bible
ra
🌐 Language
English
Español
Français
Deutsch
Português
Italiano
Nederlands
Русский
中文
日本語
한국어
العربية
Türkçe
Tiếng Việt
ไทย
Indonesia
All Languages
Home
/
Yoruba
/
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
/
2 Samuel 16
2 Samuel 16
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
← Chapter 15
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 17 →
1
Nígbà tí Dáfídì sì fi díẹ̀ kọjá orí òkè náà, sì wò ó, Ṣíbà ìránṣẹ́ Mefíbóṣétì sì ń bọ̀ wá pàdé rẹ̀, òun àti kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ méjì tí a ti dì ní gàárì, àti igba ìṣù àkàrà lórí wọn, àti ọgọ́rùn-ún ṣírì àjàrà gbígbẹ, àti ọgọ́rùn ún èṣo ẹ̀rún, àti ìgò ọtí-wáìnì kan.
2
Ọba sì wí fún Ṣíbà pé, “Kí ni wọ̀nyí?” Ṣíbà sì wí pé, “Kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ wọ̀nyí ni fún àwọn ará ilé ọba láti máa gùn àti àkàrà yìí, àti èso ẹ̀rún yìí ni fún àwọn ọdọmọdékùnrin láti jẹ; àti ọtí-wáìnì yìí ni fún àwọn aláàárẹ̀ ní ijù láti mu.”
3
Ọba sì wí pé, “Ọmọ olúwa rẹ dà?” Ṣíbà sì wí fún ọba pé, “Wò ó, ó jókòó ní Jérúsálẹ́mù; nítorí tí ó wí pé, ‘Lónìí ni ìdílé Ísírẹ́lì yóò mú ìjọba baba mi padà wá fún mi.’ ”
4
Ọba sì wí fún Síbà pé, “Wò ó, gbogbo nǹkan tí í ṣe ti Mefíbóṣétì jẹ́ tìrẹ.” Ṣíbà sì wí pé, “Mo túúbá, jẹ́ kí n rí ore-ọ̀fẹ́ lójú rẹ, OLÚWA mi ọba.”
5
Dáfídì ọba sì dé Bahúrímù, sì wò ó, Ọkùnrin kan ti ibẹ̀ jáde wá, láti ìdílé Ṣọ́ọ̀lù wá, orúkọ rẹ̀ sì ń jẹ́ Ṣíméhì, ọmọ Gérà: ó sì ń bú èébú bí o tí ń bọ̀.
6
Ó sì sọ òkúta sí Dáfídì, àti sí gbogbo àwọn ènìyàn, gbogbo àwọn alágbára ọkùnrin sì wà lọ́wọ́ ọ̀tún rẹ̀ àti lọ́wọ́ òsì rẹ̀.
7
Báyìí ni Ṣímé sì wí nígbà tí ó ń yọ èébú, “Jáde, ìwọ ọkùnrin ẹ̀jẹ̀, ìwọ ọkùnrin Bélíálì.
8
OLÚWA mú gbogbo ẹ̀jẹ̀ ìdílé Ṣọ́ọ̀lù padà wá sí orí rẹ, ní ipò ẹni tí ìwọ jọba; OLÚWA ti fi ijọba náà lé Ábúsálómù ọmọ rẹ lọ́wọ́: sì wò ó, ìwà búburú rẹ ni ó mú èyí wá bá ọ, nítorí pé ọkùnrin ẹ̀jẹ̀ ni ìwọ.”
9
Ábíṣáì ọmọ Serúià sì wí fún ọba pé, “Èéṣe tí òkú ajá yìí fi ń bú OLÚWA mi ọba? Jẹ́ kí èmi kọjá, èmi bẹ̀ ọ́, kí èmi sì bẹ́ ẹ́ lórí.”
10
Ọba sì wí pé, “Kín ni èmi ní ṣe pẹ̀lú yín, ẹ̀yín ọmọ́ Séríià? Bí ó bá ń bú èébú, nítorí tí OLÚWA ti wí fún un pé: ‘Bú Dáfídì!’ Ta ni yóò sì wí pé, ‘kín ni ìdí tí o fi ṣe bẹ́ẹ̀.’ ”
11
Dáfídì sì wí fún Ábíṣáì, àti fún gbogbo àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ pé, “Wò ó, ọmọ mi tí ó ti inú mi wá, ń wá mi kiri: ǹjẹ́ mélòó mélòó ni ará Bẹ́ńjámínì yìí yóò sì ṣe? Fi í sílẹ̀, sì jẹ́ kí o máa yan èébú; nítorí pé OLÚWA ni ó sọ fún un.
12
Bóyá Ọlọ́run yóò wo ìpọ̀njú mi, OLÚWA yóò sì fi ire san án fún mi ní ipò èébú rẹ̀ lónìí.”
13
Dáfídì àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ sì ń lọ ní ọ̀nà, Ṣíméhì sì ń rìn lẹ́bá òkè tí ó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀, ó sì ń yan èébú bí ó ti ń lọ, ó sì ń sọ ọ́ lókúta, ó sì ń fọ́n erùpẹ̀.
14
Ọba, àti gbogbo àwọn ènìyàn tí ó ń bẹ lọ́dọ̀ rẹ̀ sì dé Jódánì, ó sì rẹ̀ wọ́n, wọ́n sì sinmi níbẹ̀.
15
Ábúsálómù àti gbogbo àwọn ènìyàn, àwọn ọkùnrin Ísírẹ́lì sì wá sí Jérúsálẹ́mù, Áhítófélì sì wà pẹ̀lú rẹ̀.
16
Ó sì ṣe, nígbà tí Húṣáì ará Áríkì, ọ̀rẹ́ Dáfídì tọ Ábúsálómù wá, Húṣáì sì wí fún Ábúsálómù pé, “Kí ọba ó pẹ́! Kí ọba ó pẹ́.”
17
Ábúsálómù sì wí fún Húṣáì pé, “Oore rẹ sí ọ̀rẹ́ rẹ ni èyí? Èéṣe tí ìwọ kò bá ọ̀rẹ́ rẹ lọ?”
18
Húṣáì sì wí fún Ábúsálómù pé, “Bẹ́ẹ̀ kọ́ nítorí ẹni tí OLÚWA, àti gbogbo àwọn ènìyàn yìí, àti gbogbo àwọn ọkùnrin Ísírẹ́lì bá yàn, tirẹ̀ lèmi ó jẹ́, òun lèmi ó sì bá jókòó.
19
Àti pé, ta ni èmi ó sì sìn? Kò ha yẹ kí èmi ó máa sìn níwájú ọmọ rẹ̀? Gẹ́gẹ́ bí èmi ti ń sìn rí níwájú baba rẹ, bẹ́ẹ̀ ni èmi ó sìn níwájú rẹ.”
20
Ábúsálómù sì wí fún Áhítófélì pé, “Ẹ bá ará yín gbímọ ohun tí àwa ó ṣe.”
21
Áhítófélì sì wí fún Ábúsálómù pé, “Wọlé tọ àwọn obìnrin baba rẹ lọ, tí ó fi sílẹ̀ láti máa ṣọ́ ilé, gbogbo Ísírẹ́lì yóò sì gbọ́ pé, ìwọ di ẹni-ìríra sí baba rẹ, ọwọ́ gbogbo àwọn tí ó wà lọdọ rẹ yóò sì le.”
22
Wọ́n sì tẹ́ àgọ́ kan fún Ábúsálómù ní òrùlé; Ábúsálómù sì wọlé tọ àwọn obìnrin baba rẹ̀ lójú gbogbo Ísírẹ́lì.
23
Ìmọ̀ Áhítófélì tí ó máa ń gbà ni ìgbà náà, ó dàbí ẹni pé ènìyàn béèrè nǹkan lọ́wọ́ Ọlọ́run: bẹ́ẹ̀ ni gbogbo ìmọ̀ Áhítófélì fún Dáfídì àti fún Ábúsálómù sì rí.
← Chapter 15
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 17 →
All chapters:
1
2
3
4
5
6
7
8
9
10
11
12
13
14
15
16
17
18
19
20
21
22
23
24