bible
ra
🌐 Language
English
Español
Français
Deutsch
Português
Italiano
Nederlands
Русский
中文
日本語
한국어
العربية
Türkçe
Tiếng Việt
ไทย
Indonesia
All Languages
Home
/
Yoruba
/
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
/
2 Samuel 9
2 Samuel 9
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
← Chapter 8
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 10 →
1
Dáfídì sì béèrè pé, ọ̀kan nínú àwọn ẹni tí ń ṣe ìdílé Ṣọ́ọ̀lù kù síbẹ̀ bí? Kí èmi lè ṣe oore fún un nítorí Jónátanì.
2
Ìránṣẹ́ kan sì ti wà ní ìdílé Ṣọ́ọ̀lù, orúkọ rẹ̀ sí ń jẹ́ Síbà, Wọ́n sì pèé wá sọ́dọ̀ Dáfídì, ọba sì béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé, “Ìwọ ni Síbà bí?” Ó sì dáhùn wí pé, “Ìránṣẹ́ rẹ ni.”
3
Ọba sì wí pé, “Kò ha sí ọ̀kan nínú ìdílé Ṣọ́ọ̀lù ṣíbẹ̀, kí èmi ṣe ooré Ọlọ́run fún un?” Ṣíbà sì wí fún ọba pé, “Jónátanì ní ọmọ kan ṣíbẹ̀ tó ya arọ.”
4
Ọba sì wí fún un pé, “Níbo ni ó gbé wà?” Síbà sì wí fún ọba pé, “Wò ó, òun wà ní ilé Mákírì, ọmọ Ámíélì, ní Lódébárì.”
5
Dáfídì ọba sì ránṣẹ́, ó sì mú un láti ilé Mákírì ọmọ Ámíélì láti Lódébárì wá.
6
Méfibóṣétì ọmọ Jónátaanì ọmọ Ṣọ́ọ̀lù sì tọ Dáfídì wá, ó sì wólẹ̀ níwájú rẹ̀, ó sì bú ọlá fún un. Dáfídì sì wí pé, “Méfibóṣétì!” Òun sì dáhún wí pé, “Wò ó, ìránṣẹ́ rẹ!”
7
Dáfídì sì wí fún un pé, “Má ṣe bẹ̀rù: nítorí pé nítòótọ́ èmi ó ṣe oore fún ọ nítorí Jónátanì baba rẹ, èmi ó sì tún fi gbogbo ilé Ṣọ́ọ̀lù baba rẹ fún ọ: ìwọ ó sì máa bá mi jẹun nígbà gbogbo ní ibi oúnjẹ mi.”
8
Òun sì tẹríba, ó sì wí pé, “Kí ni ìránṣẹ́ rẹ jásí, tí ìwọ ó fi máa wo òkú ajá bí èmi.”
9
Ọba sì pe Síbà ìránṣẹ́ Ṣọ́ọ̀lù, ó sì wí fún un pé, “Gbogbo nǹkan tí í ṣe ti Ṣọ́ọ̀lù, àti gbogbo èyí tí í ṣe ti ìdílé rẹ̀ ni èmi fi fún ọmọ olúwa rẹ.
10
Ìwọ, àti àwọn ọmọ rẹ, àti àwọn ìránṣẹ́ rẹ ni yóò sì máa ró ilé náà fún un, ìwọ ni yóò sì máa mú ìkóre wá, ọmọ olúwa rẹ yóò sì máa rí òunjẹ jẹ: ṣùgbọ́n Méfibóṣétì ọmọ olúwa rẹ yóò sì máa bá mi jẹun nígbà gbogbo ní ibi oúnjẹ mi.” (Ṣíbà sì ní ọmọ mẹ́ẹ̀dógún àti ogún ìránṣẹ́kùnrin.)
11
Ṣíbà sì wí fún ọba pé, “Gẹ́gẹ́ bí gbogbo èyí tí OLÚWA mi ọba ti pa láṣẹ fún ìránṣẹ́ rẹ, bẹ́ẹ̀ náà ni ìránṣẹ́ rẹ ó ṣe.” Ọba sì wí pé, “Ní ti Méfibóṣétì, yóò máa jẹun ní ibi oúnjẹ mi, Gẹ́gẹ́ bí ọ̀kan nínú àwọn ọmọ ọba.”
12
Méfibóṣétì sì ní ọmọ kékeré kan, orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Míkà. Gbogbo àwọn tí ń gbé ní ilé Síbà ni ó sì ń ṣe ìránṣẹ́ fún Méfibóṣétì.
13
Méfibóṣétì sì ń gbé ní Jérúsálẹ́mù: òun a sì máa jẹun nígbà gbogbo ní ibi oúnjẹ́ ọba; òun sì yarọ ní ẹṣẹ̀ rẹ̀ méjèèjì.
← Chapter 8
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 10 →
All chapters:
1
2
3
4
5
6
7
8
9
10
11
12
13
14
15
16
17
18
19
20
21
22
23
24