bible
ra
🌐 Language
English
Español
Français
Deutsch
Português
Italiano
Nederlands
Русский
中文
日本語
한국어
العربية
Türkçe
Tiếng Việt
ไทย
Indonesia
All Languages
Home
/
Yoruba
/
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
/
Ephesians 2
Ephesians 2
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
← Chapter 1
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 3 →
1
Ní ti ẹ̀yin, ẹ̀yin ni ó sì ti sọ di ààyè, nígbà ti ẹ̀yin ti kú nítorí ìrékọjá àti àwọn ẹ̀ṣẹ̀ yín,
2
nínú èyí tí ẹ̀yin ti gbé rí àní bí ipá ti ayé yìí, gẹ́gẹ́ bí aláṣẹ agbára ojú ọ̀run, ẹ̀mí tí n ṣiṣẹ́ ni isinsìn yìí nínú àwọn ọmọ aláìgbọ́ràn.
3
Nínú àwọn ẹni tí gbogbo wa pẹ̀lú ti wà rí nínú ìfẹ́kúfẹ ara wa, a ń mú ìfẹ́ ara àti ti inú ṣẹ, àti nípa ẹ̀dá àwa sì ti jẹ́ ọmọ ìbínú, gẹ́gẹ́ bí àwọn ìyókù pẹ̀lú.
4
Ṣùgbọ́n Ọlọ́run, ẹni tí í ṣe ọlọ́rọ̀ ni àánú, nítorí ìfẹ́ ńlá rẹ̀ tí ó fi fẹ́ wa,
5
nígbà tí àwa tilẹ̀ ti kú nítorí ìrékọjá wa, ó sọ wá di ààyè pẹ̀lú Kírísítì oore ọ̀fẹ́ ni a ti fi gbà yín là.
6
Ọlọ́run sì ti jí wa dìde pẹ̀lú Kírísítì, ó sì ti mú wa jókòó pẹ̀lú rẹ̀ nínú àwọn ọ̀run nínú Kírísítì Jésù.
7
Pé ni gbogbo ìgbà tí ń bọ̀ kí ó bà á lè fi ọ̀rọ̀ oore-ọ̀fẹ́ rẹ̀ tí o pọ̀ rékọjá hàn fún wa nínú ìṣehun rẹ̀ sì wà nínú Kírísítì Jésù.
8
Nítorí oore ọ̀fẹ́ ní a fi gbà yín là nípa ìgbàgbọ́: àti èyí yìí kì í ṣe ti láti ọ́dọ̀ ẹ̀yin fúnra yín: ẹ̀bùn Ọlọ́run ni:
9
Kì í ṣe nípa àwọn iṣẹ́, kí ẹnikẹ́ni má ba à ṣògo.
10
Nítorí àwa ni iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀ tí a ti dá nínú Kírísítì Jésù fún àwọn iṣẹ́ rere, èyí tí Ọlọ́run ti pèṣè tẹ́lẹ̀, fún wa láti ṣe.
11
Nítorí náà ẹ rántí pé, nígbà àtijọ́ rí, ẹ̀yin tí ẹ ti jẹ́ aláìkọlà nípa ti ìbí, tí àwọn tí a ń pè ní Akọlà ti a fi ọwọ́ ṣe ni ara ń pè ní Aláìkọlà.
12
ẹ rántí pé ni àkókò náà ẹ̀yin wà láìní Kírísítì, ẹ jẹ́ àjèjì sí àǹfàní àwọn ọlọ̀tọ̀ Ísírẹ́lì, àti àlejò sí àwọn májẹ̀mú ìlérí náà, láìní ìrètí, àti láìní Ọlọ́run ni ayé:
13
Ṣùgbọ́n nísinsin yìí nínú Kírísítì Jésù ẹ̀yin tí ó ti jìnà réré nígbà àtijọ́ rí ni a mú súnmọ́ tòsí, nípa ẹ̀jẹ̀ Kírísítì.
14
Nítorí oun ni àlàáfíà wa, ẹni tí o ti ṣe méjèèjì ni ọ̀kan, tí ó sì ti wó ògiri ìkélé ti ìkórira èyí tí ń bẹ láàrin yín.
15
Nípa pípa àṣẹ, àwọn òfin àti ìlànà gbogbo rẹ̀ nínú ara rẹ̀. Àfojúsùn rẹ̀ i kí ó le dá ọkùnrin tuntun kan nínú ara rẹ̀ nínú àwọn méjèèjì, kí àlááfíà kí ó lè wà nípa èyí.
16
àti kí ó lè mú àwọn méjèèjì bá Ọlọ́run làjà nínú ara kan nípa àgbélébùú; nípa èyí tí yóò fi pa ìsòtá náà run.
17
Ó sì ti wá ó sì ti wàásù àlàáfíà fún ẹ̀yin tí o jìnnà réré, àti àlááfíà fún àwọn tí o súnmọ́ tòòsí.
18
Nítorí nípa rẹ̀ ni àwa méjèèjì ti ni àǹfààní sọ́dọ̀ baba nípa Ẹ̀mí kan.
19
Ǹjẹ́ nítorí náà ẹ̀yin kì í ṣe àlejò àti àtìpó mọ́, ṣùgbọ́n àjùmọ̀jẹ́ ọmọ ìbílẹ̀ pẹ̀lú àwọn ènìyàn mímọ́, àti àwọn ara ilé Ọlọ́run;
20
a sì ń gbé yín ró lórí ìpilẹ̀ àwọn àpostélì, àti àwọn wòlíì, pẹ̀lú Jésù Kírísítì fúnra rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí pàtàkì òkúta igun ilé;
21
Nínú rẹ ni gbogbo ilé náà, tí a ń kọ wà papọ̀ sọ̀kan tí ó sì ń dàgbà sókè láti di tẹ́ḿpìlì mímọ́ kan nínú Olúwa:
22
Nínú rẹ̀ ni a ń gbé ẹ̀yin pẹ̀lú ró pọ̀ pẹ̀lú fún ibùjókòó Ọlọ́run nínú Ẹ̀mí rẹ̀.
← Chapter 1
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 3 →
All chapters:
1
2
3
4
5
6