bible
ra
🌐 Language
English
Español
Français
Deutsch
Português
Italiano
Nederlands
Русский
中文
日本語
한국어
العربية
Türkçe
Tiếng Việt
ไทย
Indonesia
All Languages
Home
/
Yoruba
/
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
/
Ephesians 6
Ephesians 6
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
← Chapter 5
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
1
Ẹ̀yín ọmọ, ẹ máa gbọ tí àwọn òbí i yín nínú Olúwa: nítorí pé èyí ní ó tọ́.
2
“Bọ̀wọ̀ fún bábá àtí ìyá rẹ”: èyí tí í ṣe ofín kìn-ín-ní pẹ̀lú ilérí,
3
“Kí ó lé dára fún ọ, àti kí ìwọ lè wà pẹ́ ní ayé.”
4
Àti ẹyín baba, ẹ má ṣe mú àwọn ọmọ yín bínú, ṣùgbọ́n ẹ máa tọ́ wọn nínú ẹ̀kọ́ àtí ìkìlọ̀ Olúwa.
5
Ẹ̀yín ọmọ-ọ̀dọ̀, ẹ máa gbọ́ ti àwọn olúwa yín nípá ti ara, pẹ̀lú ìbẹ̀rù àtí ìwárìrì, ní òtítọ́ ọkàn yín, bí ẹni pé sí Kírísítì.
6
Gbọ́ ọ̀rọ̀ sí wọn lẹ́nu kì í ṣe láti rí ojúrere wọn nígbà tí ojú wọn bá ń bẹ lára rẹ, ṣùgbọ́n bí ẹrú Kírísítì, ní síṣe ìfẹ́ Ọlọ́run láti ọkàn rẹ.
7
Ẹ máa fí inú rere sìn bí sí Olúwa, kì í sí ṣe sí ènìyàn.
8
Bí ẹ̀yín ti mọ̀ pé ohun rere tí olúkúlùkù bá ṣe òun náà ní yóò sí gbà padá lọ́dọ̀ Olúwa, ìbá à ṣe ẹrú, tàbí òmìnira.
9
Àti ẹ̀yín ọ̀gá, ẹ máa ṣe ohun kan náà sí wọn, ẹ máa dín ìbẹ̀rù yín kù bí ẹ̀yin ti mọ̀ pé olúwa ẹ̀yin tìkárayín ń bẹ ní ọ̀run; kò sì sí ojúṣáájú ènìyàn lọ́dọ̀ rẹ̀.
10
Ní àkótan, ara mí, ẹ jẹ́ alágbára nínú Olúwa, àti nínú agbára ipá rẹ̀.
11
Ẹ gbé gbogbo ìhámọ́ra Ọlọ́run wọ̀, kí ẹ̀yín lè kọ ojú ìjà sí àrékérekè Èṣù.
12
Nítorí pé kì í ṣe ẹ̀jẹ̀ àti ẹran ara ní awá ń bá jìjàkadì, ṣùgbọ́n àwọn ìjòyé, àwọn ọlọ́lá, àwọn aláṣẹ ìbí òkùnkùn ayé yìí, àtí àwọn ẹmí búburú ní ojú ọrun.
13
Nítorí náà, ẹ gbé gbogbo ìhámọ́ra Ọlọ́run wọ̀, kí ẹ̀yín lè dúró tiiri sí ọjọ́ ibi, nígbà tí ẹ̀yin bá sì ti ṣe ohun gbogbo tan kí ẹ sì dúró.
14
Ẹ dúró nítorí náà lẹ́yìn tí ẹ fi àmùrè òtítọ́ dì ẹ̀gbẹ́ yin, tí ẹ sì ti di ìgbàyà òdodo mọ́ra.
15
Tí ẹ sì ti fí ìmúrà ìyìn rere àlàáfíà wọ ẹṣẹ̀ yín ní bàtà.
16
Ní àfikún, ẹ mú apata ìgbàgbọ́, nípa èyí tí ẹ̀yín lè máa fi paná gbogbo ọfà iná ẹni ibi náà.
17
Kí ẹ sì mú àṣíborí ìgbàlà, àti idà ẹ̀mí, tí í ṣe ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.
18
Pẹ̀lú gbogbo àdúrà àti ẹ̀bẹ̀ ni kí ẹ máa gbàdúrà nígbà gbogbo nínú Ẹ̀mí, kí ẹ sì máa ṣọ́ra sí i nínú ìdúrósinsin gbogbo àti ẹ̀bẹ̀ fún gbogbo ènìyàn mímọ́.
19
Kí ẹ sì máa gbàdúrà fún mí pẹ̀lú, kí Ọlọ́run lè fún mí ní ọ̀rọ̀ tí ó yẹ kí emí lè máa fì ìgbóyà sọ àwọn ohun ìjìnlẹ ìyìn rere náà.
20
Nítorí èyí tí èmí jẹ́ ikọ̀ nínú ẹ̀wọ̀n: kí èmi lè máa fi ìgbóyà sọ̀rọ̀ nínú rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí ó ti tọ́ fún mí láti máa sọ.
21
Ṣùgbọ́n kí ẹ̀yin pẹ̀lú lè mọ̀ bí nǹkán ti rí fún mí, bí mo tí ń ṣe sí; Tíkíkù, arákùnrin olùfẹ́ àti ìránṣẹ́ olóòótọ́ nínú Olúwa yóò sọ ohun gbogbo dí mímọ̀ fún yín.
22
Ẹni tí mo rán sí yín nítorí èyí náà, kí ẹ lè mọ̀ bí a tí wà, kì òun lè tu ọkàn yín nínú.
23
Àlàáfíà fún àwọn ará, àti ìfẹ́ pẹ̀lú ìgbàgbọ́, làti ọdọ Ọlọ́run Baba wà, àti Olúwa wà Jésù Kírísítì.
24
Kí oore ọ̀fẹ́ wà pẹ̀lú gbogbo àwọn tí ó fẹ́ Olúwa wa Jésù Kírísítì ni àìṣẹ̀tàn.
← Chapter 5
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
All chapters:
1
2
3
4
5
6