bible
ra
🌐 Language
English
Español
Français
Deutsch
Português
Italiano
Nederlands
Русский
中文
日本語
한국어
العربية
Türkçe
Tiếng Việt
ไทย
Indonesia
All Languages
Home
/
Yoruba
/
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
/
Ephesians 5
Ephesians 5
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
← Chapter 4
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 6 →
1
Nítorí náà, ẹ máa ṣe àfarawé Ọlọ́run bí àwọn olùfẹ́ ọmọ,
2
ẹ sì máa rìn ní ìfẹ́, gẹ́gẹ́ bí Kírísítì pẹ̀lú ti fẹ́ wa, tí ó sì fi ara rẹ̀ fún wa ní ọrẹ àti ẹbọ fún Ọlọ́run fún òórùn dídùn.
3
Ṣùgbọ́n àgbèrè àti gbogbo ìwà-èérì, tàbi ojúkòkòrò, kí a má tilẹ̀ dárúkọ rẹ̀ láàárin yín mọ́, bí ó ti yẹ àwọn ènìyàn mimọ;
4
Ìbáà ṣe ìwà ọ̀bùn, àti ìsọ̀rọ̀ òmùgọ̀, tàbí ìṣẹ̀fẹ̀ àwọn ohun tí kò tọ́; ṣùgbọ́n ẹ kúkú máa dúpẹ́.
5
Nítorí ẹ̀yín mọ èyí dájú pé, kò sí panṣágà, tàbí aláìmọ́ ènìyàn, tabì wọ̀bìà, (tí í ṣé abọ̀rìṣà) tí yóò ni ìní kán ni ìjọ́bà Kírísítì àti Ọlọ́run.
6
Ẹ má ṣe jẹ́ kí ẹnikẹ́ni fí ọ̀rọ̀ asán tàn yín jẹ: nítorí nípaṣẹ̀ nǹkan wọ̀nyí ní ìbínú Ọlọ́run fi ń bọ̀ wá sórí àwọn ọmọ aláìgbọ́ràn.
7
Nítorí náà ẹ má ṣe jẹ́ alájọpín pẹ̀lú wọn.
8
Nítorí ẹ̀yin tí jẹ́ òkùnkùn lẹ́ẹ̀kan ṣùgbọ́n níṣinsin yìí, ẹ̀yin dí ìmọ́lẹ̀, nípa tí Olúwa: Ẹ máa rín gẹ́gẹ́ bí àwọn ọmọ ìmọ́lẹ̀:
9
(Nítorí èso Ẹ̀mí ni ìṣoore, àti òdodo àti òtítọ́).
10
Ẹ sì máa wádìí ohun tí í ṣe ìtẹ́wọ́gbà fún Olúwa.
11
Ẹ má sì ṣe bá àwọn oníṣẹ́ òkùnkùn kẹ́gbẹ́ pọ̀, ṣùgbọ́n ẹ kúkú máa bá wọn wí.
12
Nítorí ìtìjú tilẹ̀ ni láti máa sọ̀rọ̀ nǹkán wọ̀n-ọn-nì tí àwọn aláìgbọ́ràn ń ṣe ní ìkọ̀kọ̀.
13
Ṣùgbọ́n ohun gbogbo tí a tú síta ni ìmọ́lẹ̀ ń fì hàn: nítorí ohunkóhun tí ó bá fí nǹkàn hàn, ìmọ́lẹ̀ ni.
14
Nítórí náà ni ó ṣẹ́ wí pé, “Jí, ìwọ̀ ẹní tí ó sun, Sí jíǹdè kúrò nínú òkú Kírísítì yóò sì fún ọ ní ìmọ́lẹ̀.”
15
Nítorí náà ẹ kíyésì láti máa rìn ní ìwà pípé, kì í ṣé bí àwọn òmùgọ̀, ṣùgbọ́n bí àwọn ọlọ́gbọ́n;
16
Ẹ máa ra ìgbà padá, nítorí búburú ní àwọn ọjọ́.
17
Nítorí náà, ẹ má ṣé jẹ aláìlóye, ṣùgbọ́n ẹ máa mòyé ohun tí ìfẹ́ Olúwa jásí.
18
Ẹ má sí ṣe mú wáìnì ní àmupara, nínú èyí tí rúdurúdu wà; ṣùgbọ́n ẹ kún fún Ẹ̀mí Mímọ́.
19
Ẹ sì máa bá ara yín sọ̀rọ̀ nínú Sáàmù, àti orin ìyìn, atí orin ẹ̀mí, ẹ máa kọrin, kí ẹ sì máa kọrìn dídùn ní ọkàn yín sí Olúwa.
20
Ẹ máa dúpẹ́ nígbà gbogbo fún ohun gbogbo lọ́wọ́ Ọlọ́run, àní Baba, ní orúkọ Jésù Kírísítì Olúwa wá.
21
Ẹ máa tẹríba fún ara yín ní ìbẹ̀rù Ọlọ́run.
22
Ẹ̀yín aya, ẹ máa tẹríba fún àwọn ọkọ yín, gẹ́gẹ́ bí fún Olúwa.
23
Nítorí pé ọkọ ni ó ń ṣe orí aya, gẹ́gẹ́ bí Kírísítì tí i ṣe orí ìjọ, tí ó ń ṣe ara rẹ̀, oún si ni Olugbálá rẹ̀.
24
Nítorí náà gẹ́gẹ́ bí ijọ tí i tẹríba fún Kírísítì, bẹ́ẹ̀ sì ní kì àwọn aya máa ṣe sí ọkọ wọn ní ohun gbogbo.
25
Ẹ̀yín ọkọ, ẹ fẹ́ràn àwọn aya yín, gẹ́gẹ́ bí Kírísítì tí fẹ́ràn ìjọ, tí ó sì fí ara rẹ̀ fún-un.
26
Kí òun lè sọ ọ́ dí mímọ́ lẹ́yìn tí ó tí fí ọ̀rọ̀ wẹ̀ ẹ́ nínú agbada omí.
27
Kí òun lé mú ún wá sọ́dọ̀ ara rẹ̀ bí ìjọ tí ó lógó láìní àbàwọ́n, tàbí àlébù kan, tàbí irú nǹkán bá-wọ̀n-ọn-nì: ṣùgbọ́n kí ó lè jẹ mímọ́ àti aláìní àbùkù.
28
Bẹ́ẹ̀ ní ó tọ́ kí àwọn ọkùnrin máa fẹ́ràn aya wọn gẹ́gẹ́ bí ara àwọn fúnra wọn.
29
Nítorí kò sì ẹnìkan tí ó ti kóríra ara rẹ̀; bí kò ṣe pé kí ó máa bọ́ ọ kí ó sì máa sìkẹ́ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí Kírísítì sì ti ń ṣe sí ìjọ.
30
Nítorí pé àwa ni ẹ̀yà ara rẹ̀, àti tí ẹran ara rẹ̀, atí egúngún ara rẹ̀.
31
Nítorí èyí ní ọkùnrin yóò ṣe fí Baba àti ìyá rẹ̀ sílẹ̀, òun yóò sì dàpọ̀ mọ́ aya rẹ̀, àwọn méjèèjì á sí dí ara kán.
32
Àṣírí ńlá ní èyí: ṣùgbọ́n èmí ń sọ nípá ti Kírísítì àti tí ìjọ.
33
Ṣùgbọ́n kí olúkúlùkù yín fẹ́ràn aya rẹ̀, bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ bí òun fúnra rẹ̀; kí aya kí ó sì bọ̀wọ̀ fún ọkọ rẹ̀.
← Chapter 4
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 6 →
All chapters:
1
2
3
4
5
6