bible
ra
🌐 Language
English
Español
Français
Deutsch
Português
Italiano
Nederlands
Русский
中文
日本語
한국어
العربية
Türkçe
Tiếng Việt
ไทย
Indonesia
All Languages
Home
/
Yoruba
/
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
/
Leviticus 1
Leviticus 1
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 2 →
1
OLÚWA sì pe Mósè, ó sì bá a sọ̀rọ̀ láti inú àgọ́ àjọ. Ó wí pé;
2
“Bá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sọ̀rọ̀ kí o sì wí fún wọn pé: ‘Bí ẹnikẹ́ni nínú yín bá mú ọrẹ ẹbọ wá fún OLÚWA, kí ọrẹ ẹbọ yín jẹ́ ẹran ọ̀sìn láti inú agbo ẹran tàbí láti inú ọ̀wọ́ ẹran.
3
“ ‘Bí ọrẹ ẹbọ náà bá jẹ́ sísun láti inú agbo ẹran kí òun kí ó mú akọ màlúù tí kò lábùkù. Ó sì gbọdọ̀ múu wá sí ẹnu ọ̀nà àgọ́ àjọ kí ó bá à lè jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà níwájú OLÚWA
4
kí ó gbé ọwọ́ rẹ̀ lé orí ẹbọ sísun náà yóò sì jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà dípò o rẹ̀, yóò sì jẹ́ ètùtù fún un.
5
Kí ó pa ọ̀dọ́ akọ màlúù náà níwájù OLÚWA, lẹ́yìn náà ni àwọn àlùfáà tí í se ọmọ Árónì yóò gbé ẹ̀jẹ̀ ẹran náà, wọn yóò sì wọ́n ẹ̀jẹ̀ náà yí pẹpẹ tí ó wà ní ẹnu ọ̀nà àgọ́ àjọ ká.
6
Òun yóò bó àwọ ara akọ ọ̀dọ́ màlúù náà, òun yóò sì gé e sí wẹ́wẹ́.
7
Àwọn ọmọ Árónì tí í ṣe àlùfáà yóò fi iná sí orí pẹpẹ, wọn yóò sì to igi sórí pẹpẹ náà.
8
Lẹ́yìn náà ni àwọn ọmọ Árónì tí í ṣe àlùfáà yóò tò ègé ẹran náà, pẹ̀lú orí àti ọ̀rá rẹ̀ sí ori igi tó ń jó lórí pẹpẹ.
9
Kí ó fi omi ṣàn nǹkan inú àti àwọn ẹsẹ̀ rẹ̀, kí àlùfáà sì sun gbogbo rẹ̀ lórí pẹpẹ, ó jẹ́ ọrẹ ẹbọ sísun, ọrẹ ẹbọ tí a fi iná ṣe, àní òórùn dídùn sí OLÚWA.
10
“ ‘Bí ọrẹ ẹbọ náà bá jẹ́ ọrẹ ẹbọ sísun láti inú ọ̀wọ́ ẹran, láti ara àwọn agutan tàbí ewúrẹ́ tàbí àgùntàn, kí ó mú akọ tí kò lábùkù,
11
kí ó pa á ní apá àríwá pẹpẹ níwájú OLÚWA, kí àwọn ọmọ Árónì tí í se àlùfáà sì wọ́n ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ yí gbogbo ẹ̀gbẹ́ pẹpẹ náà ká
12
Kí ó gé e sí wẹ́wẹ́, kí àlùfáà sì tò ègé ẹran náà, orí àti ọ̀rá rẹ̀ sí orí igi tó ń jó lórí pẹpẹ.
13
Kí ó fi omi san nǹkan inú àti àwọn ẹsẹ̀ rẹ̀, kí àlùfáà sì gbé gbogbo rẹ̀ wá láti sun lórí pẹpẹ. Ó jẹ́ ọrẹ ẹbọ sísun tí a fi iná se, àní òórùn dídùn sí OLÚWA
14
“ ‘Bí ọrẹ tí a fẹ́ fi fún OLÚWA bá jẹ́ ti àwọn ẹyẹ, kí ó mú àdàbà tàbí ọmọ ẹyẹlé
15
Kí àlùfáà mu wá sí ibi pẹpẹ, kí ó yín in lọ́rùn, kí ó sì sun ún lórí pẹpẹ, kí ó sì ro ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ ní ẹ̀gbẹ́ pẹpẹ.
16
Kí ó yọ àjẹsí (àpò oúnjẹ) ẹyẹ náà pẹ̀lú gbogbo ohun tí ó wà nínú rẹ̀, kí ó gbe lọ ṣí apá ìlà oòrùn pẹpẹ níbi tí eérú wà
17
Kí ó gbá apá rẹ̀ méjèèjì mú, kí ó fà á ya, ṣùgbọ́n kí ó má yaá tan pátapáta. Lẹ́yìn náà ni àlùfáà yóò sun ún lórí igi tí ó ń jó lórí pẹpẹ, ọrẹ ẹbọ sísun ni ọrẹ tí a fi iná se, àní òórùn dídùn sí OLÚWA.
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 2 →
All chapters:
1
2
3
4
5
6
7
8
9
10
11
12
13
14
15
16
17
18
19
20
21
22
23
24
25
26
27