bible
ra
🌐 Language
English
Español
Français
Deutsch
Português
Italiano
Nederlands
Русский
中文
日本語
한국어
العربية
Türkçe
Tiếng Việt
ไทย
Indonesia
All Languages
Home
/
Yoruba
/
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
/
Leviticus 5
Leviticus 5
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
← Chapter 4
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 6 →
1
“ ‘Bí ẹnìkan bá dẹ́ṣẹ̀ nítorí pé kò sọ̀rọ̀ nígbà tí a bi í ní gbangba pé kó jẹ̀ẹ́rí nípa nǹkan tó rí tàbí nǹkan tó mọ̀ nípa ìṣẹ̀lẹ̀ kan, a ó di ẹ̀bi rẹ̀ rù ú.
2
“ ‘Tàbí bí ẹnìkan bá fọwọ́ kan ohun tí a kà sí àìmọ́ yálà òkú ẹranko aláìmọ́ tàbí òkú ẹran ọ̀sìn aláìmọ́ tàbí òkú ẹ̀dá yòówù tó ń rìn lórí ilẹ̀ bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹni náà kò mọ̀, ó ti di aláìmọ́, ó sì ti jẹ̀bi.
3
“ ‘Tàbí bí ó bá fọwọ́ kan ohun àìmọ́ ti ènìyàn-ohunkóhun tó lè mú ni di aláìmọ́-bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹni náà kò mọ̀, nígbà tí ó bá mọ̀ nípa rẹ̀ yóò jẹ̀bi.
4
“ ‘Tàbí bí ẹni kan bá búra láti ṣe ohun kan láì ronú lé e lórí, yálà ohun tó dára tàbí ohun búburú, nínú ọ̀rọ̀ yòówù tó ti búra láì kíyèsí ara, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé, kò mọ̀ nípa rẹ̀ tẹ́lẹ̀, bí ó ti wù kó rí, nígbà tó bá mọ̀ yóò jẹ̀bi.
5
“ ‘Bí ẹnikẹ́ni bá jẹ̀bi ọ̀kan nínú àwọn nǹkan wọ̀nyí, ó gbọdọ̀ jẹ́wọ́ irú ọ̀nà tó ti dẹ́ṣẹ̀
6
àti pé gẹ́gẹ́ bí ìtanràn fún ẹ̀ṣẹ̀ tí ó ṣẹ̀, ó gbọdọ̀ mú abo àgùntàn tàbí abo ewúrẹ́ láti inú agbo ẹran wá gẹ́gẹ́ bí ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀, àlùfáà yóò sì ṣe ètùtù fún ẹ̀ṣẹ̀ tí ó ṣẹ̀.
7
“ ‘Bí kò bá lágbára àti mú ọ̀dọ́-àgùntàn wá, kí ó mú àdàbà méjì tàbí ọmọ ẹyẹlé méjì fún OLÚWA gẹ́gẹ́ bí ìtanràn fún ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀-ọ̀kan fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀, èkejì fún ẹbọ sísun.
8
Kí ó kó wọn wá fún àlùfáà tí yóò kọ́kọ́ rúbọ ẹ̀ṣẹ̀ kí ó yín in lọ́rùn, ṣùgbọ́n kí ó má já orí rẹ̀ tan,
9
kí ó sì wọ́n díẹ̀ lára ẹ̀jẹ̀ ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ náà sí ẹ̀gbẹ́ pẹpẹ, ìyókù ẹ̀jẹ̀ náà ni kí ó ro sí ìṣàlẹ̀ pẹpẹ. Ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ ni.
10
Lẹ́yìn èyí àlùfáà yóò wá rú ẹbọ sísun gẹ́gẹ́ bí ìlànà, yóò sì ṣe ètùtù fún un nítorí ẹ̀ṣẹ̀ tí ó ṣẹ̀, a ó sì dárí jìn-ní.
11
“ ‘Bí ó bá sì jẹ́ pé kò ní agbára àti mú àdàbà méjì tàbi ọmọ ẹyẹlẹ́ méjì wá, kí ó mú ìdá mẹ́wàá òsùwọ̀n ìyẹ̀fun kíkúná dáradára wá fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ rẹ, kò gbọdọ̀ fi òróró tàbí tùràrí sí i nítorí pé ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ ni.
12
Kí ó gbé e wá sí ọ̀dọ̀ àlùfáà, àlùfáà yóò sì bu ẹ̀kúnwọ́ ìyẹ̀fun gẹ́gẹ́ bí ẹbọ ìrántí, kí ó sì sun ún lórí pẹpẹ, gẹ́gẹ́ bí ẹbọ tí a fi iná sun sí OLÚWA. Ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ ni
13
Báyìí ni àlùfáà yóò ṣe ètùtù fún ẹni náà fún èyíkéyìí nínú àwọn ẹ̀ṣẹ̀ tí ó dá, a ó sì dárí jìn-ní.’ ”
14
OLÚWA sọ fún Mósè pé
15
“Nígbà tí ẹnìkan bá dẹ́ṣẹ̀ ìrékọjá tí ó sì ṣe láìmọ̀ ní ti àwọn ohun mímọ́ OLÚWA, kí ó mú àgbò láti inú agbo ẹran wá fún OLÚWA gẹ́gẹ́ bí ìtanràn, àgbò tí kò lábùkù tí ó sì níye lórí gẹ́gẹ́ bí iye owó ibi mímọ́. Ẹbọ ẹ̀bi ni.
16
Kí ó ṣe àtúnṣe nítorí ohun tí ó ti kùnà láti ṣe ní ti àwọn ohun mímọ́ OLÚWA, kí ó sì fi ìdá márùn-ún kún iye ohun tí ó kùnà láti ṣe nípa ohun mímọ́ OLÚWA kí ó sì kó gbogbo rẹ̀ fún àlùfáà, ẹni tí yóò ṣe ètùtù fún un pẹ̀lú àgbò fún ẹbọ ẹ̀bi, a ó sì dárí jìn-ní.
17
“Bí ẹnìkan bá dẹ́ṣẹ̀ tí ó sì ṣe ohun tí kó yẹ ko ṣe sí ọ̀kan nínú òfin OLÚWA, bí kò tilẹ̀ mọ̀, ó jẹ̀bi, yóò sì ru ẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀
18
kí ó mú àgbò kan láti inú agbo ẹran wá sọ́dọ̀ àlùfáà, fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ àgbò tí kò lábùkù tí ó sì níye lórí bí iye owó ibi mímọ́. Báyìí ni àlùfáà yóò ṣe ètùtù fún ẹni náà, fún àṣìṣe tí ó ṣe láìmọ̀, a ó sì dári jìn-ní.
19
Ẹbọ ẹ̀bi ni ó ti jẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀ tí ó ṣẹ̀ sí OLÚWA.”
← Chapter 4
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 6 →
All chapters:
1
2
3
4
5
6
7
8
9
10
11
12
13
14
15
16
17
18
19
20
21
22
23
24
25
26
27