bible
ra
🌐 Language
English
Español
Français
Deutsch
Português
Italiano
Nederlands
Русский
中文
日本語
한국어
العربية
Türkçe
Tiếng Việt
ไทย
Indonesia
All Languages
Home
/
Yoruba
/
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
/
Leviticus 17
Leviticus 17
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
← Chapter 16
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 18 →
1
OLÚWA sọ fún Mósè pé:
2
“Sọ fún Árónì àti àwọn ọmọ rẹ̀ pẹ̀lú gbogbo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì: ohun tí Ọlọ́run pa láṣẹ nìyí:
3
Bí ẹnikẹ́ni nínú ìdílé Ísírẹ́lì bá pa màlúù tàbí ọ̀dọ́ àgùntàn tàbí àgbò nínú ibùdó tàbí bí ó bá pa á lẹ́yìn ibùdó
4
tí kò sì mú un wá sí ibi àgọ́ ìpàdé láti fi rú ẹbọ sí OLÚWA níwájú àgọ́ ìpàdé: ẹ̀bi ìtàjẹ̀sílẹ̀ ni kí ẹ kà sí ẹni náà lọ́rùn: torí pé ó ti ta ẹ̀jẹ̀ sílẹ̀: ẹni náà ni a ó sì gé kúrò láàrin àwọn ènìyàn rẹ̀.
5
Èyí rí bẹ́ẹ̀ kí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì le è máa mú ẹbọ wọn tí wọn ti rú ní ìta gbangba wá sí iwájú OLÚWA: wọ́n gbọdọ̀ mú un wá ṣíwájú àlùfáà àní sí OLÚWA ní ẹnu ọ̀nà àgọ́ ìpàdé: kí wọ́n sì rú wọn gẹ́gẹ́ bí ẹbọ àlàáfíà sí OLÚWA.
6
Àlùfáà náà yóò sì fi ẹ̀jẹ̀ náà wọ́n ibi pẹpẹ OLÚWA ní ẹnu ọ̀nà àgọ́ ìpàdé yóò sì sun ọ̀rá rẹ̀ ní òórùn dídùn sí OLÚWA.
7
Torí náà, kí wọn má ṣe rú ẹbọ wọn sí ère ẹranko mọ́, nínú èyí tí wọ́n ti ṣe àgbérè tọ̀ lọ. Èyí yóò sì jẹ́ ìlànà títí láé láti ìran dé ìran wọn tí ń bọ̀.
8
“Kí ó sọ fún wọn pé: ‘Ọkùnrin yówù kí ó jẹ́ ní ìdílé Ísírẹ́lì tàbí ti àwọn àlejò tí ń gbé láàrin wọn tí ó bá rú ọrẹ sísun tàbí ṣe ẹbọ
9
tí kò sì mú un wá sí ẹnu ọ̀nà àgọ́ ìpàdé láti fi rúbọ sí OLÚWA irú ẹni bẹ́ẹ̀ ni a ó gé kúrò láàrin àwọn ènìyàn rẹ̀.
10
“ ‘Bí ẹnikẹ́ni bá jẹ ẹ̀jẹ̀ yálà nínú ìdílé Ísírẹ́lì tàbí àwọn àlejò tí ń gbé láàrin wọn: Èmi yóò bínú sí irú ẹni náà tí ó jẹ ẹ̀jẹ̀: èmi yóò sì gé e kúrò láàrin àwọn ènìyàn rẹ̀.
11
Nítorí pé nínú ẹ̀jẹ̀ ni ẹ̀mí ẹ̀dá wà èmi sì ti fi fún yín lórí pẹpẹ fún ètùtù ọkàn yín: nítorí pé ẹ̀jẹ̀ ni a fi ń ṣe ètùtù fún ẹ̀mí ènìyàn.
12
Ìdí nìyí tí mo fi sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé, kò sí ẹni tí ó gbọdọ̀ jẹ ẹ̀jẹ̀.
13
“ ‘Ẹnikẹ́ni yálà nínú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tàbí àlejò tí ń gbé láàrin wọn, tí ó bá pa ẹranko tàbí ẹyẹ tí ó yẹ fún jíjẹ gbọdọ̀ ro ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ sílẹ̀ kí ó sì bò ó mọ́lẹ̀.
14
Torí pé ẹ̀mí gbogbo ẹ̀dá ni ẹ̀jẹ̀ rẹ̀, torí náà ni mo fi kìlọ̀ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé wọn kò gbọdọ̀ jẹ ẹ̀jẹ̀ ohun abẹ̀mí kankan: torí pé nínú ẹ̀jẹ̀ ohun abẹ̀mí wọ̀nyí ni ẹ̀mí wọn wà: ẹnikẹ́ni tí ó bá jẹ ẹ́ ni a ó gé kúrò.
15
“ ‘Ẹnikẹ́ni tí ó bá jẹ ohun tí ó kú sílẹ̀ fúnrarẹ̀: tàbí èyí tí ẹranko búburú pa kálẹ̀ yálà onílé tàbí àlejò: ó ní láti fọ aṣọ rẹ̀. Kí ó sì fi omi wẹ ara rẹ̀: yóò sì wà ní ipò àìmọ́ títí di àṣálẹ́ lẹ́yìn èyí ni yóò tó di mímọ́.
16
Ṣùgbọ́n bí ó bá kọ̀ láti wẹ ara rẹ̀ tí kò sì fọ aṣọ rẹ̀ náà: ẹ̀bi rẹ̀ yóò wà lórí ara rẹ̀.’ ”
← Chapter 16
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 18 →
All chapters:
1
2
3
4
5
6
7
8
9
10
11
12
13
14
15
16
17
18
19
20
21
22
23
24
25
26
27