bible
ra
🌐 Language
English
Español
Français
Deutsch
Português
Italiano
Nederlands
Русский
中文
日本語
한국어
العربية
Türkçe
Tiếng Việt
ไทย
Indonesia
All Languages
Home
/
Yoruba
/
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
/
Micah 3
Micah 3
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
← Chapter 2
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 4 →
1
Nígbà náà, ni mo wí pé, “Ẹ gbọ́, ẹ̀yin olórí Jákọ́bù, ẹ̀yin alákòóso ilé Ísírẹ́lì. Ǹjẹ́ ẹ̀yin kì í ha ṣe láti mọ òdodo bí.
2
Ẹ̀yin tí ó kórìíra ire, tí ẹ sì fẹ́ràn ibi; Ẹ̀yin tí ẹ fa awọ-ẹran ara àwọn ènìyàn mi ya kúrò lára wọn àti ẹran-ara wọn kúrò ní egungun wọn;
3
Àwọn tí ó jẹ ẹran-ara àwọn ènìyàn mi, wọn sì bọ́ awọ-ara wọn kúrò lára wọn. Wọ́n sì fọ́ egungun wọn sí wẹ́wẹ́; Wọn sì gée sí wẹ́wẹ́ bí ẹran inú ìkòkò, bí ẹran inú òdù?”
4
Nígbà náà ni wọn yóò kígbe sí OLÚWA, Ṣùgbọ́n òun kì yóò dá wọn lóhùn. Ní àkókò náà ni òun yóò fi ojú rẹ̀ pamọ́ kúrò lọ́dọ̀ wọn, nítorí ibi tí wọ́n ti ṣe.
5
Báyìí ni OLÚWA wí: “Ní ti àwọn Wòlíì tí ń sí àwọn ènìyàn mi lọ́nà, tí ẹnìkan bá fún wọn ní oúnjẹ, wọn yóò kéde àlàáfíà; Ṣùgbọ́n tí kò bá fi nǹkan sí wọn ní ẹnu, wọn yóò múra ogun sí i.
6
Nítorí náà òru yóò wá sórí yín, tí ẹ̀yin kì yóò sì rí ìran kankan, òkùnkùn yóò sì kùn fún yín, tí ẹ̀yin kì yóò sì lè ṣọ tẹ́lẹ̀ Oòrùn yóò sì yọ lórí àwọn wòlíì ọjọ́ yóò sì ṣókùnkùn lórí wọn.
7
Ojú yóò sì ti àwọn Wòlíì àwọn alásọtẹ́lẹ̀ pẹ̀lú yóò sì gba ìtìjú. Gbogbo wọn ni yóò bo ojú wọn, nítorí kò sí ìdáhùn láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run.”
8
Ṣùgbọ́n ní tèmi, èmi kún fún agbára pẹ̀lú ẹ̀mi OLÚWA, láti sọ ìré-òfin-kọjá Jákọ́bù fún-un, àti láti sọ ẹ̀ṣẹ̀ Ísírẹ́lì fún-un.
9
Gbọ́ ẹ̀yin olórí ilé Jákọ́bù, àti ẹ̀yin alákòóso ilé Ísírẹ́lì, tí ó kórìíra òdodo tí ó sì yí òtítọ́ padà;
10
Tí ó kọ́ Síónì pẹ̀lú ìtàjẹ̀sílẹ̀, àti Jérúsálẹ́mù pẹ̀lú ìwà búrurú.
11
Àwọn olórí rẹ̀ ń ṣe ìdájọ́ nítorí àbẹ̀tẹ́lẹ̀, àwọn àlùfáà rẹ̀ sì ń kọ́ni nítorí owó-ọ̀yà àwọn wòlíì rẹ̀ pẹ̀lú sì ń sọ tẹ́lẹ̀ nítorí owó. Ṣíbẹ̀, wọn gbẹ́kẹ̀lé OLÚWA, wọ́n sì wí pé, “Ní tòótọ́, OLÚWA wà pẹ̀lú wa! Ibi kan kì yóò bá wa.”
12
Nítorí náà, nitorí tiyín, ni a ó ṣe ro Síónì bí oko, Jérúsálẹ́mù yóò sì di ebè àti òkè tẹ́ḿpìlì bí i ibi gíga igbo.
← Chapter 2
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 4 →
All chapters:
1
2
3
4
5
6
7
Recommended Reading
Commentary
Micah Commentaries
→
Devotional
Micah Devotional Guide
→
Get This Bible
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní) Study Bible
→