bible
ra
🌐 Language
English
Español
Français
Deutsch
Português
Italiano
Nederlands
Русский
中文
日本語
한국어
العربية
Türkçe
Tiếng Việt
ไทย
Indonesia
All Languages
Home
/
Yoruba
/
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
/
Micah 4
Micah 4
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
← Chapter 3
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 5 →
1
Ní ọjọ́ ìkẹyìn a ó fi òkè ilé OLÚWA lélẹ̀ lórí àwọn òkè ńlá, a ó sì gbé e ga ju àwọn òkè kéékèèkéé lọ, àwọn ènìyàn yóò sì máa wọ̀ sínú rẹ̀.
2
Ọ̀pọ̀lọpọ̀ orílẹ̀-èdè yóò wá, wọn yóò sì wí pé, “Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí á gòkè ńlá OLÚWA, àti sí ilé Ọlọ́run Jákọ́bù Òun yóò sì kọ́ wa ní ọ̀nà rẹ̀, àwa ó sì máa rìn ní ipa ọ̀nà rẹ̀.” Nítorí láti Síónì ni òfin yóò ti jáde wá, àti ọ̀rọ̀ Ọlọ́run láti Jérúsálẹ́mù.
3
Òun yóò sì ṣe ìdájọ́ láàrin ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn, yóò sì parí aáwọ̀ fún orílẹ̀-èdè alágbára jínjìn réré. Wọn yóò sì fi idà wọn rọ ohun èlò ìtùlẹ̀ àti ọ̀kọ̀ wọn di dòjé orílẹ̀-èdè kì yóò gbé idà sókè sí orílẹ̀-èdè, bẹ́ẹ̀ ni wọn kì yóò kọ nípa ogun jíjà mọ́.
4
Ṣùgbọ́n olúkúlùkù yóò jókòó lábẹ́ àjàrà rẹ̀ àti lábẹ́ igi ọ̀pọ̀tọ́ rẹ̀, ẹnikan kì yóò sì dẹ́rù bà wọ́n, nítorí OLÚWA àwọn ọmọ ogun ti sọ̀rọ̀.
5
Gbogbo àwọn ènìyàn ń rìn, olúkúlùkù ni orúkọ ọlọ́run tirẹ̀, ṣùgbọ́n àwa yóò máa rìn ní orúkọ OLÚWA. Ọlọ́run wa láé àti láéláé.
6
“Ní ọjọ́ náà,” ni OLÚWA wí, “Èmi yóò kó àwọn arọ jọ; èmi yóò sì ṣà àwọn tí a lé kúrò ní ìlú jọ, àti àwọn ẹni tí èmi ti pọ́n lójú.
7
Èmi yóò dá àwọn arọ sí fún èyí tó kù, èmi yóò sì sọ àwọn tí a lé kúrò ní ìlú di orílẹ̀-èdè alágbára. OLÚWA yóò sì jọba lórí wọn ní òkè-ńlá Síónì láti ìsinsìn yìí lọ àti títí láéláé.
8
Ní ti ìwọ, ilé ìṣọ́ agbo àgùntàn, odi alágbára ọmọbìnrin Síónì, a ó mú ìjọba ìṣáájú padà bọ̀ sípò fún un yín; ìjọba yóò sì wà sí ọ̀dọ̀ ọmọbìnrin Jérúsálẹ́mù.”
9
Kí ni ìwọ ha ń kígbe sókè sí nísinsin yìí? Ǹjẹ́ ìwọ kò ní ọba bí? Àwọn ìgbìmọ̀ rẹ ṣègbé bí? Nítorí ìrora ti dì ọ́ mú bí obìnrin tí ń rọbí.
10
Má a yí síhìn-ín sọ́hùn-ún nínú ìrora, ìwọ obìnrin Síónì, bí ẹni tí ń rọbí, nítorí nísinsìn yìí ìwọ yóò jáde lọ kúrò ní ìlú, ìwọ yóò sì máa gbé inú igbó. Ìwọ yóò lọ sí Bábílónì; níbẹ̀ ni ìwọ yóò sì ti rí ìgbàlà. Níbẹ̀ ni OLÚWA yóò ti rà ọ́ padà kúrò lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá rẹ.
11
Ṣùgbọ́n nísinsin yìí ọ̀pọ̀lọpọ̀ orílẹ̀-èdè kó ara wọn jọ sí ọ. Wọ́n sì wí pé, “Ẹ jẹ́ kí a sọ ọ́ di àìmọ́, Ẹ jẹ́ kí ojú wa kí ó wo Síónì!”
12
Ṣùgbọ́n wọn kò mọ èrò inú OLÚWA; Bẹ́ẹ̀ ni òye ìmọ̀ rẹ̀ kò yé wọn, nítorí ó ti kó wọn jọ bí i ìtí sínú ìpakà.
13
“Dìde, kí ó sì máa pa ọkà ìwọ ọmọbìnrin Síónì, nítorí èmi yóò sọ ìwo rẹ̀ di irin, èmi yóò sì sọ pátakó rẹ̀ di idẹ ìwọ yóò run ọ̀pọ̀lọpọ̀ orilẹ̀-èdè pátapáta.” Èmi yóò sì ya èrè wọn sọ́tọ̀ fún OLÚWA àti ọrọ̀ wọn sí OLÚWA gbogbo aye.
← Chapter 3
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 5 →
All chapters:
1
2
3
4
5
6
7
Recommended Reading
Commentary
Micah Commentaries
→
Devotional
Micah Devotional Guide
→
Get This Bible
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní) Study Bible
→