bible
ra
🌐 Language
English
Español
Français
Deutsch
Português
Italiano
Nederlands
Русский
中文
日本語
한국어
العربية
Türkçe
Tiếng Việt
ไทย
Indonesia
All Languages
Home
/
Yoruba
/
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
/
Micah 5
Micah 5
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
← Chapter 4
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 6 →
1
Nísinsin yìí, kó àwọn ọ̀wọ́ ogun rẹ jọ, ìwọ ọmọbìnrin ọ̀wọ́ ogun, nítorí ó ti fi gbógun dó tì wá. Wọn yóò fi ọ̀pá lu àwọn alákòóso Ísírẹ́lì ní ẹ̀rẹ̀kẹ́.
2
“Ṣùgbọ́n ìwọ, Bẹ́tílẹ́hẹ́mù Éfúrátà, bí ó ti lẹ̀ jẹ́ pé ìwọ kékeré láàrin àwọn ẹ̀yà Júdà, nínú rẹ ni ẹni tí yóò jẹ́ olórí Ísírẹ́lì yóò ti jáde tọ̀ mí wá, ìjáde lọ rẹ̀ sì jẹ́ láti ìgbà àtijọ́, láti ìgbà láéláé.”
3
Nítorí náà Ísírẹ́lì yóò di kíkọ̀sílẹ̀ pátápátá títí di àkókò tí ẹni tí ń rọbí yóò fi bí, àti àwọn ìyókù arákùnrin rẹ̀ yóò fi padà láti dara pọ̀ mọ́ àwọn Ísírẹ́lì.
4
Òun yóò sì dúró, yóò sì máa ṣe Olùsọ́-àgùntàn àwọn agbo-ẹran rẹ̀ ní agbára OLÚWA, ní ọláńlá orúkọ OLÚWA Ọlọ́run rẹ̀. Wọn yóò sì wà láìléwu, nítorí nísinsin yìí ni títóbi rẹ yóò sì dé òpin ayé.
5
Òun yóò sì jẹ́ àlàáfíà wọn. Nígbà tí àwọn Ásíríà bá gbógun sí ilẹ̀ wa tí wọ́n sì ń yan lórí odi alágbára wa, nígbà náà ni a ó gbé olúsọ́-àgùntàn méje dìde sí i, àti olórí ènìyàn mẹ́jọ.
6
Wọn yóò sì fi idà pa ilẹ̀ Ásíríà run, àti ilẹ̀ Nímíródù pẹ̀lú idà tí a fà. Òun yóò sì gbà wá sílẹ̀ lọ́wọ́ àwọn ará Ásíríà nígbà tí wọn bá gbógun ti ilẹ̀ wa tí wọ́n sì tún yan wọ inú ìpínlẹ̀ wa.
7
Ìyòókù Jákọ́bù yóò sì wà láàrin ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn bí ìrì látí ọ̀dọ̀ OLÚWA wa, bí ọ̀wàrà òjò lórí koríko, tí kò gbẹ́kẹ̀lé ènìyàn tàbí kò dúró de àwọn ọmọ ènìyàn.
8
Ìyòókù Jákọ́bù yóò sì wà láàrin àwọn aláìkọlà ní àárin àwọn ọ̀pọ̀ ènìyàn, bí i kìnnìún láàrin àwọn ẹranko inú igbó, bí i ọmọ kìnnìún láàrin agbo àgùntàn, èyí tí ó máa ń fàá ya pẹ́rẹpẹ̀rẹ, tí ó sì máa ń tẹ̀ ẹ́ mọ́lẹ̀, tí kò sì sí ẹnìkan tí ó lè gbà á là.
9
A ó gbé ọwọ́ rẹ̀ sókè ní ìṣẹ́gun lórí àwọn ọ̀tá rẹ̀, gbogbo àwọn ọ̀ta rẹ̀ sì ni a ó parun.
10
“Ní ọjọ́ náà,” ni OLÚWA wí, “Èmi yóò pa àwọn esin rẹ̀ run kúrò láàrin rẹ èmi yóò sì pa àwọn kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀ run.
11
Èmi yóò sì pa ilẹ̀ ìlú-ńlá rẹ̀ run, èmi ó sì fa gbogbo ibi gíga rẹ̀ ya.
12
Èmi yóò gé ìwà-àjẹ́ kúrò lọ́wọ́ rẹ̀, ìwọ kì yóò sì ní aláfọ̀ṣẹ mọ́.
13
Èmi yóò pa àwọn ère fífín rẹ̀ run, àti ọwọ́n rẹ̀ kúrò láàrin rẹ̀; ìwọ kì yóò sì le è foríbalẹ̀ fún iṣẹ́ ọwọ́ rẹ mọ́.
14
Èmi yóò fa òpó òrìṣà rẹ tu kúrò láàrin rẹ̀, èmi yóò sì pa ìlú ńlá rẹ̀ run.
15
Èmi yóò gbẹ̀san ní ìbínú àti ìrunú lórí àwọn orílẹ̀-èdè tí kò ti tẹríba fún mi.”
← Chapter 4
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 6 →
All chapters:
1
2
3
4
5
6
7
Recommended Reading
Commentary
Micah Commentaries
→
Devotional
Micah Devotional Guide
→
Get This Bible
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní) Study Bible
→