bible
ra
🌐 Language
English
Español
Français
Deutsch
Português
Italiano
Nederlands
Русский
中文
日本語
한국어
العربية
Türkçe
Tiếng Việt
ไทย
Indonesia
All Languages
Home
/
Yoruba
/
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
/
Nahum 1
Nahum 1
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 2 →
1
Ọ̀rọ̀ ìmọ̀ nípa Nínéfè. Ìwé ìran Náhúmù ará Elikósì.
2
OLÚWA ń jowu, ó sì ń gbẹ̀san. OLÚWA ń gbẹ̀san, ó sì kún fún ìbínú OLÚWA ń gbẹ̀san lára àwọn ọ̀tá rẹ̀, Ìbínú rẹ̀ kò sì yí padà lórí àwọn ọ̀tá rẹ̀
3
OLÚWA lọ́ra láti bínú, ó sì tóbi ní agbára; OLÚWA kì yóò fi àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ sílẹ̀ láì jìyà. Ọ̀nà rẹ̀ wà nínú ààjà àti nínú ìjì, Ìkùùku sánmọ̀ sì ni eruku ẹsẹ̀ rẹ̀.
4
Ó bá òkun wí, ó sì mú kí ó gbẹ; Ó sí sọ gbogbo odò di gbígbẹ. Báṣánì àti Kámẹ́lì sì rọ, Ìtànná Lébánónì sì rẹ̀ sílẹ̀.
5
Àwọn òkè ńlá wárìrì níwájú rẹ̀, àwọn òkè kéékèèkéé sì di yíyọ́, ilẹ̀ ayé sì jóná níwájú rẹ̀, àní ayé àti gbogbo àwọn tí ń gbé inú rẹ̀.
6
Ta ni ó lé dúró níwájú ìbínú rẹ̀? Ta ni ó lé faradà gbígbóná ìbínú rẹ̀? Ìbínú rẹ̀ tú jáde bí iná; àwọn àpáta sì fọ́ túútúú níwájú rẹ̀.
7
Rere ni OLÚWA, ààbò ní ọjọ ìpọ́njú. Òun sì tọ́jú àwọn tí ó gbẹ́kẹ̀ lé e,
8
Ṣùgbọn pẹ̀lú ìkún omi ńlá ní òun yóò fi ṣe ìparun ibẹ̀ dé òpin; òkùnkùn yóò sì máa lépa àwọn ọ̀tá rẹ̀.
9
Kí ni ẹ̀yìn ń gbìmọ lòdì sí OLÚWA? Òun yóò fi òpin sí i, Ìpọ́njú kì yóò wáyé ní ìgbà kejì
10
Wọn yóò sì lọ́lù papọ̀ bí ẹ̀gún òṣùṣù wọn yóò sì mu àmupara nínú ọtí wáìnì wọn a ó sì run wọn gẹ́gẹ́ bi àkékù koríko gbígbẹ
11
Láti ọ̀dọ̀ rẹ, ìwọ Nínéfè, ni ẹnìkan ti jáde wá tí ó ń gbérò ibi sí OLÚWA ti ó sì ń gbìmọ̀ búburú.
12
Báyìí ni OLÚWA wí: “Bí wọ́n tilẹ̀ pé, tí wọ́n sì pọ̀ níye, Ṣùgbọ́n, báyìí ní a ó ké wọn lulẹ̀, nígbà tí òun ó bá kọ́já. Bí mo tilẹ̀ ti pọ́n ọ lójú ìwọ Júdà, èmi kì yóò pọ́n ọ lójú mọ́.
13
Nísinsin yìí ni èmi yóò já àjàgà wọn kúrò ní ọrùn rẹ èmi yóò já sẹkẹ́sẹkẹ̀ rẹ dànù.”
14
OLÚWA ti fi àṣẹ kan lélẹ̀ nítorí tìrẹ Nínéfè: “Ìwọ kì yóò ni irú ọmọ láti máa jẹ́ orúkọ rẹ mọ́, Èmi yóò pa ère fínfín àti ère dídà run tí ó wà nínú tẹ́ḿpílì àwọn ọlọ́run rẹ. Èmi yóò wa ibojì rẹ, nítorí ẹ̀gbin ni ìwọ.”
15
Wò ó, lórí àwọn okè, awọn ẹsẹ̀ ẹni tí ó mú ìròyin ayọ wá, ẹni tí ó ń kéde àlàáfíà, Ìwọ Júdà, pa àṣẹ rẹ tí ó ní ìrònú mọ́, kí ó sì san àwọn ẹ̀jẹ́ rẹ. Àwọn ènìyàn búburú kì yóò sì gbógun tì ọ́ mọ́; Wọn yóò sì parun pátapáta.
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 2 →
All chapters:
1
2
3