bible
ra
🌐 Language
English
Español
Français
Deutsch
Português
Italiano
Nederlands
Русский
中文
日本語
한국어
العربية
Türkçe
Tiếng Việt
ไทย
Indonesia
All Languages
Home
/
Yoruba
/
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
/
Nahum 2
Nahum 2
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
← Chapter 1
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 3 →
1
Àwọn apanirun ti dìde sí ọ, ìwọ Nínéfè pa ilé-ìsọ́ mọ́, ṣọ́ ọ̀nà náà di àmùrè, ẹ̀gbẹ́ rẹ kí ó le, múra gírí.
2
OLÚWA yóò mú ọláńlá Jákọ́bù padà sípò gẹ́gẹ́ bí ọláńlá Ísírẹ́lì bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn apanirun ti pa ibẹ̀ run, tí wọ́n sì ti run àwọn àjàrà wọn.
3
Asà àwọn ọmọ ogun rẹ̀ sì di pupa; àwọn ológun wọn sì wọ aṣọ òdòdó. Idẹ tí ó wà lórí kẹ̀kẹ́ ogun ń kọ mọ̀nàmọ̀nà ní ọjọ́ tí a bá pèsè wọn sílẹ̀ tán; igi fìrì ni a ó sì mì tìtì.
4
Àwọn kẹ̀kẹ́ ogun yóò ya bo àwọn pópónà, wọn yóò sì máa sáré síwá àti sẹ́yìn ní àárin ìgboro. Wọn sì dàbí ètúfú iná; tí ó sì kọ bí i mọ̀nàmọ́ná.
5
Òun yóò ṣe àṣàrò àwọn ọlọ́lá rẹ̀; ṣíbẹ̀ wọ́n ń kọsẹ̀ ní ojú ọ̀nà wọn; wọn sá lọ sí ibi odi rẹ̀, a ó sì pèsè ààbò rẹ̀.
6
A ó sí ìlẹ̀kùn àwọn odò wọ̀n-ọn-nì sílẹ̀, a ó sì mú ààfin náà di yíyọ́.
7
A pa á láṣẹ pé ìlú náà Èyí tí a ti fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ ni kí a kó ní ìgbèkùn lọ. A ó sì mú un gòkè wá àti awọn ìránṣẹ́bìnrin rẹ̀ yóò ti ohùn bí ti oriri, ṣe amọ̀nà rẹ̀, wọn a sì máa lu àyà wọn.
8
Nínéfè dàbí adágún omi, tí omi wọn sì ń gbẹ́ ẹ lọ. “Dúró! Dúró!” ni wọ́n ó máa kígbe, ṣùgbọ́n ẹnikankan kì yóò wo ẹ̀yìn.
9
“Ẹ kó ìkógun fàdákà! Ẹ kó ìkógun wúrà! Ìṣúra wọn ti kò lópin náà, àti ọrọ̀ kúrò nínú gbogbo ohun èlò ti a fẹ́!”
10
Òun ti ṣòfò, ó si di asán, ó sì di ahoro: ọkàn pami, éekún ń lu ara wọn, ìrora púpọ̀ sì wà nínú gbogbo ẹgbẹ́ àti ojú gbogbo wọ́n sì rẹ̀wẹ̀sì.
11
Níbo ni ihò àwọn kìnnìún wà àti ibi ìjẹun àwọn ọmọ kìnnìún, níbi tí kìnnìún, àní abo kìnnìún ti ń rìn, àti ọmọ kìnnìún, láìsí ohun ìbẹ̀rù
12
Kìnnìún pàápàá tẹ́rù fún àwọn ọmọ rẹ̀, ó sì fún-un ní ọ́rùn pa fún àwọn abo kìnnìún rẹ̀, Ó sì fi ohun pípa kún ibùgbé rẹ̀ àti ihò rẹ̀ fún ohun ọdẹ.
13
“Kíyèsíi èmi dojú kọ ọ́,” ni OLÚWA awọn ọmọ ogun wí. “Èmi yóò sì fi kẹ̀kẹ́ rẹ̀ wọ̀n-ọn-nì jóná nínú èéfín, idà yóò sì jẹ ọmọ kìnnìún rẹ̀ wọ̀n-ọn-nì run. Èmi yóò sì ké ohun ọdẹ rẹ kúrò lórí ilẹ̀ ayé Ohùn awọn òjíṣẹ́ rẹ ni a kì yóò sì tán gbọ́ mọ́.”
← Chapter 1
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 3 →
All chapters:
1
2
3