bible
ra
🌐 Language
English
Español
Français
Deutsch
Português
Italiano
Nederlands
Русский
中文
日本語
한국어
العربية
Türkçe
Tiếng Việt
ไทย
Indonesia
All Languages
Home
/
Yoruba
/
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
/
Nahum 3
Nahum 3
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
← Chapter 2
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
1
Ègbé ni fún ìlú ẹ̀jẹ̀ nì, gbogbo rẹ̀ kún fún èké, àti olè, ìja kò kúrò!
2
Ariwo pàṣán àti ariwo kíkùn kẹ̀kẹ́ ogun àti jíjó ẹṣin àti gbígbọ̀n kẹ̀kẹ́ ogun jìgìjìgì!
3
Ológun orí ẹṣin ń fi ìgbónára ju ìdà wọn mọ̀nàmọ̀nà ọ̀kọ̀ rẹ̀ ti ń dán yanran sí òkè! Ọ̀pọ̀lọpọ̀ si ní àwọn ẹni tí a pa, àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ òkú; òkú kò si ni òpin; àwọn ènìyàn sì ń kọsẹ̀ lára àwọn òkú.
4
Nítorí ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn panṣágà àgbèrè tí ó rójú rere gbà, Iyá àjẹ́ tí ó sọ́ àwọn orilẹ̀-èdè di ẹrú nipa àgbèrè rẹ̀ àti àwọn ìdílé nipa ìṣe àjẹ́ rẹ̀.
5
“Èmi dojú kọ ọ́,” ni OLÚWA awọn ọmọ ogun wí. “Èmi ó si ká aṣọ ìtẹ́lẹ̀dì rẹ ní ojú rẹ, Èmi yóò sì fi ìhòòhò rẹ̀ han àwọn orílẹ̀-èdè àti ìtìjú rẹ̀ han àwọn ilẹ̀ ọba.
6
Èmi yóò da ẹ̀gbin tí ó ni ìríra sí ọ ní ara, èmi yóò sì sọ ọ́ di aláìmọ́ èmi yóò sì sọ ọ́ di ẹlẹ́yà.
7
Kò sí ṣe pé, gbogbo àwọn tí ó ba sì wò ọ́ yóò sì káàánú fún ọ, wọn yóò sì wí pé, ‘Nínéfè ṣòfò: Ta ni yóò kẹ́dùn rẹ?’ Níbo ni èmi o ti wá olùtùnú fún ọ?”
8
Ǹjẹ́ ìwọ ha sàn ju Tébésì lọ, èyí tí ó wà ní ibi odò, Náílì tí omi sì yí káàkiri? Odò náà sì jẹ́ ààbò rẹ̀, omi si jẹ́ odi rẹ̀.
9
Etiópíà àti Éjíbítì ni agbára rẹ, kò sí ní òpin; Pútì àti Líbíà ni àwọn olùgbèjà rẹ̀.
10
Ṣíbẹ̀ ṣíbẹ̀ a kó o ní ìgbèkùn o sì lọ sí oko ẹrú. Àwọn ọmọ wẹ́wẹ́ rẹ̀ ni a ó fọ́ mọ́lẹ̀ ní orí ìta gbogbo ìgboro. Wọ́n sì di ìbò nítorí àwọn ọlọ́lá rẹ̀ ọkùnrin, gbogbo àwọn ọlọ́lá rẹ ni a sì fi ẹ̀wọ̀n dè
11
Ìwọ pẹ̀lú yóò sì mu àmupara; a ó si fi ọ́ pamọ́ ìwọ pẹ̀lú yóò máa ṣe àfẹ́rí ààbò nítorí ti ọ̀tá náà.
12
Gbogbo ilé-ìṣọ́ agbára rẹ yóò dàbí igi ọ̀pọ̀tọ́ pẹ̀lú àkọ́pọ́n èso wọn; Nígbà tí wọ́n bá ń gbọ̀n wọ́n, ọ̀pọ̀tọ́ yóò sì bọ́ sí ẹnu àwọn ọ̀jẹun.
13
Kíyè sí, Obínrin ni àwọn ènìyàn rẹ ní àárin! Ojú ibodè rẹ ní a ó sí sílẹ̀ gbagada, fún àwọn ọ̀tá rẹ̀; iná yóò jó ilẹ̀ rẹ
14
Ìwọ pọn omi de ìhámọ́, mú ile ìsọ́ rẹ lágbára sí i wọ inú amọ̀ kí o sì tẹ erùpẹ̀, kí ó sì tún ibi tí a ti ń sun bíríkì-amọ̀ ṣe kí ó le.
15
Níbẹ̀ ni iná yóò ti jó ọ́ run; Idà yóò sì ké ọ kúrò, yóò sì jẹ ọ́ bí i kòkòrò, yóò sì sọ ara rẹ̀ di púpọ̀ bí i tata, àní, di púpọ̀ bí eṣú!
16
Ìwọ ti sọ àwọn oníṣòwò rẹ di púpọ̀ títí wọn yóò ṣe pọ̀ ju ìràwọ̀ oju ọ̀run lọ Kòkòrò na ara rẹ̀ ó sì fò lọ.
17
Àwọn aládé rẹ̀ dàbí eṣú, àwọn ọ̀gágun rẹ dàbí ẹlẹ́ǹgà ńlá, èyí ti ń dó sínú ọgbà la ọjọ́ òtútù, ṣùgbọ́n nígbà tí òòrùn jáde, wọ́n sá lọ ẹnìkan kò sì mọ ibi tí wọ́n gbé wà.
18
Ìwọ ọba Ásíríà, àwọn olùṣọ àgùntàn rẹ̀ ń tòògbé; awọn ọlọ́lá rẹ yóò máa gbé inú ekuru. Rẹ àwọn ènìyàn rẹ fọ́nká lórí àwọn òkè ńlá, tí ẹnikẹni kò sì kó wọn jọ.
19
Kò sì sí ohun tí ó lè wo ọgbẹ́ ẹ rẹ sàn; ọgbẹ́ rẹ kun fún ìrora Gbogbo ẹni tí ó bá sì gbọ́ ìròyìn rẹ yóò pàtẹ́wọ́ lé ọ lórí, nítorí ni orí ta ni, ìwà buburu rẹ kò ti kọjá nígbà gbogbo?
← Chapter 2
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
All chapters:
1
2
3