bible
ra
🌐 Language
English
Español
Français
Deutsch
Português
Italiano
Nederlands
Русский
中文
日本語
한국어
العربية
Türkçe
Tiếng Việt
ไทย
Indonesia
All Languages
Home
/
Yoruba
/
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
/
1 Timothy 2
1 Timothy 2
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
← Chapter 1
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 3 →
1
NITORINA mo gbà nyin niyanju ṣaju ohun gbogbo, pe ki a mã bẹ̀bẹ, ki a mã gbadura, ki a mã ṣìpẹ, ati ki a mã dupẹ nitori gbogbo enia;
2
Fun awọn ọba, ati gbogbo awọn ti o wà ni ipo giga; ki a le mã lo aiye wa ni idakẹjẹ ati pẹlẹ ninu gbogbo ìwa-bi-Ọlọrun ati ìwa agbà.
3
Nitori eyi dara o si ṣe itẹwọgbà niwaju Ọlọrun Olugbala wa;
4
Ẹniti o nfẹ ki gbogbo enia ni igbala ki nwọn si wá sinu ìmọ otitọ.
5
Nitori Ọlọrun kan ni mbẹ, Onilaja kan pẹlu larin Ọlọrun ati enia, on papa enia, ani Kristi Jesu;
6
Ẹniti o fi ara rẹ̀ ṣe irapada fun gbogbo enia, ẹrí li akokò rẹ̀;
7
Nitori eyiti a yàn mi ṣe oniwasu, ati aposteli, (otitọ li emi nsọ, emi kò ṣeke;) olukọ awọn Keferi ni igbagbọ́ ati otitọ.
8
Nitorina mo fẹ ki awọn ọkunrin mã gbadura nibi gbogbo, ki nwọn mã gbé ọwọ́ mimọ́ soke, li aibinu ati li aijiyan.
9
Bẹ̃ gẹgẹ ki awọn obinrin ki o fi aṣọ iwọntunwọnsin ṣe ara wọn li ọṣọ́, pẹlu itiju ati ìwa airekọja; kì iṣe pẹlu irun didì ati wura, tabi pearli, tabi aṣọ olowo iyebiye,
10
Bikoṣe pẹlu iṣẹ́ rere (eyi ti o yẹ fun awọn obinrin ti o jẹwọ ìwa-bi-Ọlọrun).
11
Jẹ ki obinrin ki o mã fi idakẹjẹ ati itẹriba gbogbo kọ́ ẹkọ́.
12
Ṣugbọn emi kò fi aṣẹ fun obinrin lati mã kọ́ni, tabi lati paṣẹ lori ọkunrin, bikoṣepe ki o dakẹjẹ.
13
Nitori Adamu li a kọ́ dá, lẹhin na, Efa.
14
A kò si tàn Adamu jẹ, ṣugbọn obinrin na, nigbati a tàn a, o ṣubu sinu ẹ̀ṣẹ.
15
Ṣugbọn a o gbà a là nipa ìbimọ rẹ̀, bi nwọn ba duro ninu igbagbọ́ ati ifẹ, ati ìwa mimọ́ pẹlu ìwa airekọja.
← Chapter 1
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 3 →
All chapters:
1
2
3
4
5
6