bible
ra
🌐 Language
English
Español
Français
Deutsch
Português
Italiano
Nederlands
Русский
中文
日本語
한국어
العربية
Türkçe
Tiếng Việt
ไทย
Indonesia
All Languages
Home
/
Yoruba
/
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
/
1 Timothy 4
1 Timothy 4
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
← Chapter 3
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 5 →
1
ṢUGBỌN Ẹmí ntẹnumọ ọ pe, ni igba ikẹhin awọn miran yio kuro ninu igbagbọ́, nwọn o mã fiyesi awọn ẹmí ti ntan-ni-jẹ, ati ẹkọ́ awọn ẹmí èṣu;
2
Nipa agabagebe awọn ti nṣeke, awọn ti ọkàn awọn tikarawọn dabi eyiti a fi irin gbigbona jó.
3
Awọn ti nda-ni-lẹkun ati gbeyawo, ti nwọn si npaṣẹ lati ka ẽwọ onjẹ ti Ọlọrun ti da fun itẹwọgba pẹlu ọpẹ awọn onigbagbọ ati awọn ti o mọ otitọ.
4
Nitori gbogbo ohun ti Ọlọrun dá li o dara, kò si ọkan ti o yẹ ki a kọ̀, bi a ba fi ọpẹ́ gbà a.
5
Nitori a fi ọ̀rọ Ọlọrun ati adura yà a si mimọ́.
6
Bi iwọ ba nrán awọn ará leti nkan wọnyi, iwọ o jẹ iranṣẹ rere ti Kristi Jesu, ti a nfi ọrọ igbagbọ́ ati ẹ̀kọ rere bọ́, eyiti iwọ ti ntẹle.
7
Ṣugbọn kọ̀ ọrọ asan ati itan awọn agba obinrin, si mã tọ́ ara rẹ si ìwa-bi-Ọlọrun.
8
Nitori ṣíṣe eré ìdaraya ní èrè diẹ, ṣugbọn ìwa-bi-Ọlọrun li ère fun ohun gbogbo, o ni ileri ti aiye isisiyi ati ti eyi ti mbọ̀.
9
Otitọ ni ọrọ na, o si yẹ fun itẹwọgbà gbogbo.
10
Nitori fun eyi li awa nṣe lãlã ti a si njijakadi, nitori awa ni ireti ninu Ọlọrun alãye, ẹniti iṣe Olugbala gbogbo enia, pẹlupẹlu ti awọn ti o gbagbọ́.
11
Nkan wọnyi ni ki o mã palaṣẹ ki o si mã kọ́ni.
12
Máṣe jẹ ki ẹnikẹni ki o gàn ewe rẹ; ṣugbọn ki iwọ ki o jẹ apẹrẹ fun awọn ti o gbagbọ́, ninu ọ̀rọ, ninu ìwa hihu, ninu ifẹ, ninu ẹmí, ninu igbagbọ́, ninu ìwa mimọ́.
13
Titi emi o fi de, mã tọju iwe kikà ati igbaniyanju ati ikọ́ni.
14
Máṣe ainani ẹ̀bun ti mbẹ lara rẹ, eyiti a fi fun ọ nipa isọtẹlẹ pẹlu ifọwọle awọn àgba.
15
Mã fiyesi nkan wọnyi; fi ara rẹ fun wọn patapata; ki ilọsiwaju rẹ ki o le hàn gbangba fun gbogbo enia.
16
Mã ṣe itọju ara rẹ ati ẹkọ́ rẹ; mã duro laiyẹsẹ ninu nkan wọnyi: nitori ni ṣiṣe eyi, iwọ ó gbà ara rẹ ati awọn ti ngbọ́ ọ̀rọ rẹ là.
← Chapter 3
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 5 →
All chapters:
1
2
3
4
5
6