bible
ra
🌐 Language
English
Español
Français
Deutsch
Português
Italiano
Nederlands
Русский
中文
日本語
한국어
العربية
Türkçe
Tiếng Việt
ไทย
Indonesia
All Languages
Home
/
Yoruba
/
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
/
1 Timothy 6
1 Timothy 6
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
← Chapter 5
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
1
KI gbogbo awọn ti iṣe ẹrú labẹ ìrú mã ka awọn oluwa ti o ni wọn yẹ si ọla gbogbo, ki a má bã sọrọ-odi si orukọ Ọlọrun ati ẹkọ́ rẹ̀.
2
Awọn ti o si ni oluwa onigbagbọ́, ki nwọn máṣe gàn wọn nitori arakunrin ni nwọn; ṣugbọn ki nwọn tubọ mã sìn wọn, nitori awọn ti iṣe alabapin iṣẹ rere wọn jẹ onigbagbọ́ ati olufẹ. Nkan wọnyi ni ki o mã kọ́ni ki o si mã fi gba-ni-niyanju.
3
Bi ẹnikẹni ba nkọ́ni li ẹkọ miran, ti kò si gba ọ̀rọ ti o ye kõro, ani ọ̀rọ Jesu Kristi Oluwa wa, ati ẹkọ́ gẹgẹ bi ìwa-bi-Ọlọrun.
4
O gberaga, kò mọ nkan kan, bikoṣe ifẹ iyan-jija ati ìja-ọ̀rọ ninu eyiti ilara, ìya, ọrọ buburu ati iro buburu ti iwá,
5
Ọ̀rọ̀ ayipo awọn enia ọlọkan ẽri ti kò si otitọ ninu wọn, ti nwọn ṣebi ọna si ere ni ìwa-bi-Ọlọrun: yẹra lọdọ irú awọn wọnni.
6
Ṣugbọn iwa-bi-Ọlọrun pẹlu itẹlọrùn ère nla ni.
7
Nitori a kò mu ohun kan wá si aiye, bẹni a kò si le mu ohunkohun jade lọ.
8
Bi a ba si li onjẹ ati aṣọ ìwọnyi yio tẹ́ wa lọrùn.
9
Ṣugbọn awọn ti nfẹ di ọlọrọ̀ a mã bọ́ sinu idanwò ati idẹkun, ati sinu wère ifẹkufẹ pipọ ti ipa-ni-lara, iru eyiti imã rì enia sinu iparun ati ègbé.
10
Nitori ifẹ owo ni gbòngbo ohun buburu gbogbo: eyiti awọn miran nlepa ti a si mu wọn ṣako kuro ninu igbagbọ́, nwọn si fi ibinujẹ pupọ̀ gún ara wọn li ọ̀kọ̀.
11
Ṣugbọn iwọ enia Ọlọrun, sá fun nkan wọnyi; ki o si mã lepa ododo, ìwa-bi-Ọlọrun, igbagbọ́, ifẹ, sũru, ìwa tutù.
12
Mã jà ìja rere ti igbagbọ́, di ìye ainipẹkun mu ninu eyiti a gbé pè ọ si, ti iwọ si ṣe ijẹwo rere niwaju ẹlẹri pupọ̀.
13
Mo paṣẹ fun ọ niwaju Ọlọrun, ti nsọ ohun gbogbo di ãye, ati niwaju Jesu Kristi, ẹni, niwaju Pontiu Pilatu, ti o jẹri ijẹwọ rere,
14
Ki iwọ ki o pa ofin mọ́ li ailabawọn, li ailẹgan, titi di ifarahàn Oluwa wa Jesu Kristi:
15
Eyiti yio fihàn ni igba tirẹ̀, Ẹniti iṣe Olubukún ati Alagbara na kanṣoṣo, Ọba awọn ọba, ati Oluwa awọn oluwa;
16
Ẹnikanṣoṣo ti o ni aikú, ti ngbe inu imọlẹ ti a kò le sunmọ, ẹniti enia kan kò ri rí ti kò si le ri: ẹniti ọla ati agbara titi lai iṣe tirẹ. Amin.
17
Kìlọ fun awọn ti o lọrọ̀ li aiye isisiyi, ki nwọn máṣe gberaga, bẹni ki nwọn máṣe gbẹkẹle ọrọ̀ aidaniloju, bikoṣe le Ọlọrun alãye, ti nfi ohun gbogbo fun wa lọpọlọpọ lati lo;
18
Ki nwọn ki o mã ṣõre, ki nwọn ki o mã pọ̀ ni iṣẹ rere, ki nwọn mura lati pin funni, ki nwọn ki o ni ẹmi ibakẹdun;
19
Ki nwọn ki o mã tò iṣura ipilẹ rere jọ fun ara wọn dè igba ti mbọ̀, ki nwọn ki o le di ìye tõtọ mu.
20
Timotiu, ṣọ ohun ni ti a fi si itọju rẹ, yà kuro ninu ọ̀rọ asan ati ijiyan ohun ti a nfi eke pè ni imọ;
21
Eyiti awọn ẹlomiran jẹwọ rẹ̀ ti nwọn si ṣina igbagbọ́. Ki ore-ọfẹ ki o wà pẹlu rẹ. Amin.
← Chapter 5
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
All chapters:
1
2
3
4
5
6