bible
ra
🌐 Language
English
Español
Français
Deutsch
Português
Italiano
Nederlands
Русский
中文
日本語
한국어
العربية
Türkçe
Tiếng Việt
ไทย
Indonesia
All Languages
Home
/
Yoruba
/
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
/
Jeremiah 14
Jeremiah 14
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
← Chapter 13
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 32
Chapter 33
Chapter 34
Chapter 35
Chapter 36
Chapter 37
Chapter 38
Chapter 39
Chapter 40
Chapter 41
Chapter 42
Chapter 43
Chapter 44
Chapter 45
Chapter 46
Chapter 47
Chapter 48
Chapter 49
Chapter 50
Chapter 51
Chapter 52
Chapter 15 →
1
EYI li ọ̀rọ Oluwa ti o tọ̀ Jeremiah wá nipa ti ọdá.
2
Juda kãnu ati ẹnu-bode rẹ̀ wọnnì si jõro, nwọn dudu de ilẹ; igbe Jerusalemu si ti goke.
3
Awọn ọlọla wọn si ti rán awọn ọmọ wẹrẹ lọ si odò: nwọn wá si kanga, nwọn kò ri omi; nwọn pada pẹlu agbè wọn lofo, oju tì wọn, idãmu mu wọn, nwọn si bo ori wọn.
4
Nitori ilẹ, ti ndãmu gidigidi, nitoriti òjo kò si ni ilẹ, oju tì awọn àgbẹ, nwọn bo ori wọn.
5
Lõtọ abo-àgbọnrin pẹlu ni papa bimọ, o fi i silẹ nitori ti kò si koriko.
6
Ati awọn kẹtẹkẹtẹ-igbẹ duro lori oke wọnni, nwọn fọn imu si ẹfũfu bi ikõko, oju wọn rẹ̀ nitoriti kò si koriko.
7
Oluwa, bi ẹ̀ṣẹ wa ti jẹri si wa to nì, ṣe atunṣe nitori orukọ rẹ: nitoriti ipẹhinda wa pọ̀; si ọ li awa ti ṣẹ̀.
8
Iwọ, ireti Israeli, olugbala rẹ̀ ni wakati ipọnju! ẽṣe ti iwọ o dabi alejo ni ilẹ, ati bi èro ti o pa agọ lati sùn?
9
Ẽṣe ti iwọ o dabi ẹniti o dãmu, bi ọkunrin akọni ti kò le ràn ni lọwọ? sibẹ iwọ, Oluwa, mbẹ li ãrin wa, a si npè orukọ rẹ mọ wa, má fi wa silẹ.
10
Bayi li Oluwa wi fun awọn enia yi, bayi ni nwọn ti fẹ lati rò kiri, nwọn kò dá ẹsẹ wọn duro; Oluwa kò si ni inu-didun ninu wọn: yio ranti aiṣedẽde wọn nisisiyi, yio si bẹ ẹ̀ṣẹ wọn wò.
11
Nigbana li Oluwa wi fun mi pe, Máṣe gbadura fun awọn enia yi fun rere.
12
Nigbati nwọn ba gbãwẹ, emi kì yio gbọ́ ẹ̀bẹ wọn; nigbati nwọn ba ru ẹbọ-ọrẹ sisun ati ẹbọ-ọrẹ, inu mi kì o dùn si wọn: ṣugbọn emi o fi idà, ati ìyan, ati ajakalẹ-àrun pa wọn run.
13
Emi si wipe, Oluwa Ọlọrun, sa wò o, awọn woli wi fun wọn pe; Ẹnyin kì yio ri idà, bẹ̃li ìyan kì yio de si nyin; ṣugbọn emi o fun nyin ni alafia otitọ ni ibi yi.
14
Nigbana ni Oluwa wi fun mi pe, awọn woli nsọ asọtẹlẹ eke li orukọ mi; emi kò rán wọn, bẹ̃ni emi kò paṣẹ fun wọn, emi kò si sọ̀rọ kan fun wọn, iran eke, afọṣẹ, ati ohun asan, ati ẹ̀tan inu wọn, ni awọn wọnyi sọtẹlẹ fun nyin.
15
Nitorina bayi li Oluwa wi niti awọn woli ti nsọ asọtẹlẹ li orukọ mi, ti emi kò rán; sibẹ nwọn wipe, Idà ati ìyan kì yio wá sori ilẹ yi; nipa idà, pẹlu ìyan, ni awọn woli wọnyi yio ṣegbe.
16
Ati awọn enia ti nwọn nsọ asọtẹlẹ fun ni a o lù bolẹ ni ita Jerusalemu, nitori ìyan ati idà, nwọn kì yio ri ẹniti o sin wọn, awọn aya wọn, ati ọmọkunrin wọn, ati ọmọbinrin wọn: nitoriti emi o tu ìwa-buburu wọn jade sori wọn.
17
Ki iwọ ki o si sọ ọ̀rọ yi fun wọn pe: oju mi sun omije li oru ati li ọsan, kì yio si dá, nitoriti a ti ṣa wundia ọmọbinrin enia mi li ọgbẹ nla kikoro gidigidi ni lilù na.
18
Bi emi ba jade lọ si papa, sa wò o, a ri awọn ti a fi idà pa! bi emi ba si wọ inu ilu lọ, sa wò o, awọn ti npa ọ̀kakà ikú nitori iyan! nitori awọn, ati awọn woli, ati awọn alufa nwọ́ lọ si ilẹ ti nwọn kò mọ̀.
19
Iwọ ha ti kọ̀ Juda silẹ patapata? ọkàn rẹ ti korira Sioni? ẽṣe ti iwọ ti lù wa, ti imularada kò si fun wa? awa nreti alafia, kò si si rere, ati fun igba imularada, ṣugbọn wò o, idãmu!
20
Awa jẹwọ iwa buburu wa, Oluwa, ati aiṣedede awọn baba wa: nitori awa ti ṣẹ̀ si ọ.
21
Máṣe korira wa, nitori orukọ rẹ, máṣe gan itẹ́ ogo rẹ, ranti, ki o máṣe dà majẹmu ti o ba wa dá.
22
Ẹniti o le mu ojo rọ̀ ha wà lọdọ awọn oriṣa awọn keferi? tabi ọrun le rọ̀ òjo? iwọ ha kọ́, Oluwa Ọlọrun wa? awa si nreti rẹ: nitori iwọ li o da gbogbo nkan wọnyi.
← Chapter 13
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 32
Chapter 33
Chapter 34
Chapter 35
Chapter 36
Chapter 37
Chapter 38
Chapter 39
Chapter 40
Chapter 41
Chapter 42
Chapter 43
Chapter 44
Chapter 45
Chapter 46
Chapter 47
Chapter 48
Chapter 49
Chapter 50
Chapter 51
Chapter 52
Chapter 15 →
All chapters:
1
2
3
4
5
6
7
8
9
10
11
12
13
14
15
16
17
18
19
20
21
22
23
24
25
26
27
28
29
30
31
32
33
34
35
36
37
38
39
40
41
42
43
44
45
46
47
48
49
50
51
52
Recommended Reading
Commentary
Jeremiah Commentaries
→
Devotional
Jeremiah Devotional Guide
→
Get This Bible
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ) Study Bible
→