bible
ra
🌐 Language
English
Español
Français
Deutsch
Português
Italiano
Nederlands
Русский
中文
日本語
한국어
العربية
Türkçe
Tiếng Việt
ไทย
Indonesia
All Languages
Home
/
Yoruba
/
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
/
Jeremiah 17
Jeremiah 17
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
← Chapter 16
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 32
Chapter 33
Chapter 34
Chapter 35
Chapter 36
Chapter 37
Chapter 38
Chapter 39
Chapter 40
Chapter 41
Chapter 42
Chapter 43
Chapter 44
Chapter 45
Chapter 46
Chapter 47
Chapter 48
Chapter 49
Chapter 50
Chapter 51
Chapter 52
Chapter 18 →
1
Ẹ̀ṢẸ Juda ni a fi kalamu irin kọ, a fi ṣonṣo okuta adamante gbẹ ẹ sori walã aiya wọn, ati sori iwo pẹpẹ nyin.
2
Bi awọn ọmọ wọn ba ranti pẹpẹ wọn, ati ere òriṣa wọn, lẹba igi tutu, ati ibi giga wọnni.
3
Oke mi ti o wà ni papa! emi o fi ohun-ini rẹ pẹlu ọrọ̀ rẹ gbogbo fun ijẹ, ati ibi giga rẹ, nitori ẹ̀ṣẹ yi gbogbo àgbegbe rẹ ka.
4
Iwọ fun ara rẹ ni yio jọ̃ ogún rẹ lọwọ, ti mo ti fi fun ọ, emi o mu ọ sìn awọn ọta rẹ ni ilẹ ti iwọ kò mọ̀ ri: nitoriti ẹnyin ti tinabọ ibinu mi, ti yio jo lailai.
5
Bayi li Oluwa wi: Egbe ni fun ẹniti o gbẹkẹle enia, ti o fi ẹlẹran ara ṣe apá rẹ̀, ẹniti ọkàn rẹ̀ si ṣi kuro lọdọ Oluwa!
6
Nitoripe yio dabi alaini ni aginju, ti kò si ri pe rere mbọ̀: ṣugbọn yio gbe ibi iyangbẹ ilẹ wọnni ni aginju, ilẹ iyọ̀ ti a kì igbe inu rẹ̀.
7
Ibukun ni fun ẹniti o gbẹkẹle Oluwa, ti o si fi Oluwa ṣe igbẹkẹle rẹ̀!
8
Yio si dabi igi ti a gbìn lẹba omi, ti o nà gbòngbo rẹ̀ lẹba odò, ti kì yio bẹ̀ru bi õru ba de, ṣugbọn ewe rẹ̀ yio tutu, kì yio si ni ijaya ni ọdun ọ̀dá, bẹ̃ni kì yio dẹkun lati ma so eso.
9
Ọkàn enia kún fun ẹ̀tan jù ohun gbogbo lọ, o si buru jayi! tani o le mọ̀ ọ?
10
Emi, Oluwa, ni iwá awari ọkàn enia, emi ni ndan inu wò, ani lati fi fun olukuluku gẹgẹ bi ọ̀na rẹ̀, ati gẹgẹ bi eso iṣe rẹ̀.
11
Bi aparo ti isaba lori ẹyin ti kò yin, bẹ̃ gẹgẹ ni ẹniti o kó ọrọ̀ jọ, ṣugbọn kì iṣe ni ododo; yio fi i silẹ lagbedemeji ọjọ rẹ̀, ati ni opin rẹ̀ yio jẹ aṣiwere.
12
Itẹ́ ogo! ibi giga lati ipilẹsẹ ni ibi ile mimọ́ wa!
13
Oluwa ni ireti Israeli! gbogbo awọn ti o kọ̀ ọ silẹ yio dãmu, awọn ti o yẹ̀ kuro lọdọ mi, ni a o kọ orukọ wọn sinu ẽkuru, si ori ilẹ, nitori nwọn ti kọ̀ Oluwa silẹ, orisun omi ìye.
14
Wò mi sàn, Oluwa, emi o si sàn! gbà mi là, emi o si là, nitori iwọ ni iyìn mi!
15
Sa wò o, nwọn wi fun mi pe, Nibo ni ọ̀rọ Oluwa wà? jẹ ki o wá wayi.
16
Bi o ṣe ti emi ni, emi kò yara kuro ki emi má ṣe oluṣọ-agutan, lẹhin rẹ, bẹ̃ni emi kò bere ọjọ ipọnju, iwọ mọ̀: eyiti o jade li ète mi, o ti hàn niwaju rẹ.
17
Máṣe di ibẹ̀ru fun mi! iwọ ni ireti mi li ọjọ ibi!
18
Jẹ ki oju ki o tì awọn ti o nṣe inunibini si mi, ṣugbọn má jẹ ki oju ki o tì mi: jẹ ki nwọn ki o dãmu, ṣugbọn máṣe jẹ ki emi ki o dãmu: mu ọjọ ibi wá sori wọn, ki o si fi iparun iṣẹpo meji pa wọn run.
19
Bayi li Oluwa wi fun mi; Lọ, ki o si duro ni ẹnu-ọ̀na awọn enia nibi ti awọn ọba Juda nwọle, ti nwọn si njade, ati ni gbogbo ẹnu-bode Jerusalemu.
20
Ki o si wi fun wọn pe, Ẹ gbọ́ ọ̀rọ Oluwa, ẹnyin ọba Juda ati gbogbo Juda, ati gbogbo ẹnyin olugbe Jerusalemu, ti o nkọja ninu ẹnu-bode wọnyi.
21
Bayi li Oluwa wi, Ẹ kiyesi li ọkàn nyin, ki ẹ máṣe ru ẹrù li ọjọ isimi, bẹ̃ni ki ẹ má si ṣe mu u wá ninu ẹnu-bode Jerusalemu:
22
Bẹ̃ni ki ẹ má si ṣe gbe ẹrù jade kuro ninu ile nyin li ọjọ isimi, bẹ̃ni ki ẹ má ṣe iṣẹkiṣẹ, ṣugbọn ki ẹ yà ọjọ isimi si mimọ́, gẹgẹ bi mo ti paṣẹ fun awọn baba nyin.
23
Ṣugbọn nwọn kò gbọ́, nwọn kò si tẹti silẹ, nwọn mu ọrun wọn le, ki nwọn ki o má ba gbọ́, ati ki nwọn o má bà gba ẹ̀kọ́.
24
Yio si ṣe bi ẹnyin ba tẹtisilẹ gidigidi si mi, li Oluwa wi, ti ẹ kò ba ru ẹrù kọja ni ẹnu-bode ilu yi li ọjọ isimi, ti ẹ ba si yà ọjọ isimi si mimọ, ti ẹ kò si ṣe iṣẹkiṣẹ ninu rẹ̀,
25
Nigbana ni nwọn o wọ ẹnu-bode ilu yi, ani ọba, ati ijoye ti o joko lori itẹ Dafidi, awọn ti ngun kẹ̀kẹ ati ẹṣin, awọn wọnyi pẹlu ijoye wọn, awọn ọkunrin Juda, ati olugbe Jerusalemu: nwọn o si ma gbe ilu yi lailai.
26
Nwọn o si wá lati ilu Juda wọnni, ati lati àgbegbe Jerusalemu yikakiri, ati lati ilẹ Benjamini, lati pẹtẹlẹ, ati lati oke, ati lati gusu wá, nwọn o si mu ọrẹ-ẹbọ sisun, ati ọrẹ ẹran ati turari, ati awọn wọnyi ti o mu iyìn wá si ile Oluwa.
27
Ṣugbọn bi ẹnyin kò ba gbọ́ ti emi, lati ya ọjọ isimi si mimọ́, ti ẹ kò si ru ẹrù, ti ẹ kò tilẹ wọ ẹnu-bode Jerusalemu li ọjọ isimi; nigbana ni emi o da iná ni ẹnu-bode wọnni, yio si jo ãfin Jerusalemu run, a kì o si pa a.
← Chapter 16
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 32
Chapter 33
Chapter 34
Chapter 35
Chapter 36
Chapter 37
Chapter 38
Chapter 39
Chapter 40
Chapter 41
Chapter 42
Chapter 43
Chapter 44
Chapter 45
Chapter 46
Chapter 47
Chapter 48
Chapter 49
Chapter 50
Chapter 51
Chapter 52
Chapter 18 →
All chapters:
1
2
3
4
5
6
7
8
9
10
11
12
13
14
15
16
17
18
19
20
21
22
23
24
25
26
27
28
29
30
31
32
33
34
35
36
37
38
39
40
41
42
43
44
45
46
47
48
49
50
51
52
Recommended Reading
Commentary
Jeremiah Commentaries
→
Devotional
Jeremiah Devotional Guide
→
Get This Bible
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ) Study Bible
→