bible
ra
🌐 Language
English
Español
Français
Deutsch
Português
Italiano
Nederlands
Русский
中文
日本語
한국어
العربية
Türkçe
Tiếng Việt
ไทย
Indonesia
All Languages
Home
/
Yoruba
/
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
/
Jeremiah 27
Jeremiah 27
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
← Chapter 26
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 32
Chapter 33
Chapter 34
Chapter 35
Chapter 36
Chapter 37
Chapter 38
Chapter 39
Chapter 40
Chapter 41
Chapter 42
Chapter 43
Chapter 44
Chapter 45
Chapter 46
Chapter 47
Chapter 48
Chapter 49
Chapter 50
Chapter 51
Chapter 52
Chapter 28 →
1
LI atetekọbẹrẹ ijọba Sedekiah, ọmọ Josiah, ọba Juda, li ọ̀rọ yi tọ̀ Jeremiah wá lati ọ̀dọ Oluwa wipe,
2
Bayi li Oluwa wi fun mi; Ṣe ijara ati àjaga-ọrùn fun ara rẹ, ki o si fi wọ ọrùn rẹ.
3
Ki o rán wọn lọ si ọdọ ọba Edomu, ati si ọba Moabu, ati si ọba awọn ọmọ Ammoni, ati si ọba Tire, ati si ọba Sidoni, lọwọ awọn ikọ̀ ti o wá si Jerusalemu sọdọ Sedekiah, ọba Juda.
4
Ki o si paṣẹ fun wọn lati wi fun awọn oluwa wọn pe, Bayi li Oluwa awọn ọmọ-ogun, Ọlọrun Israeli wi, Bayi li ẹnyin o wi fun awọn oluwa nyin pe;
5
Emi ti dá aiye, enia ati ẹranko ti o wà lori ilẹ aiye, nipa agbara nla mi, ati nipa ọwọ ninà mi, emi si fi i fun ẹnikẹni ti o wù mi.
6
Njẹ nisisiyi, emi fi gbogbo ilẹ yi le ọwọ Nebukadnessari, ọba Babeli, ọmọ-ọdọ mi: ati ẹranko igbẹ ni mo fi fun u pẹlu lati sin i.
7
Ati orilẹ-ède gbogbo ni yio sin on, ati ọmọ rẹ̀ ati ọmọ-ọmọ rẹ̀, titi di ìgba ti akoko ilẹ tirẹ̀ yio de; lara rẹ̀ ni orilẹ-ède pupọ ati awọn ọba nla yio jẹ.
8
Yio si ṣe, orilẹ-ède ati ijọba ti kì yio sin Nebukadnessari ọba Babeli, ti kì yio fi ọrùn wọn si abẹ àjaga ọba Babeli, orilẹ-ède na li emi o fi idà, ati ìyan, ati ajakalẹ-arun, jẹ niya, li Oluwa wi, titi emi o fi run wọn nipa ọwọ rẹ̀.
9
Nitorina ẹ máṣe fi eti si awọn woli nyin, tabi si awọn alafọṣẹ nyin, tabi si awọn alála, tabi si awọn oṣo nyin, tabi awọn ajẹ nyin ti nsọ fun nyin pe, Ẹnyin kì o sin ọba Babeli:
10
Nitori nwọn sọ-asọtẹlẹ eke fun nyin, lati mu nyin jina réré kuro ni ilẹ nyin, ki emi ki o lè lé nyin jade, ti ẹnyin o si ṣegbe.
11
Ṣugbọn orilẹ-ède na ti o mu ọrùn rẹ̀ wá si abẹ àjaga ọba Babeli, ti o si sìn i, on li emi o jẹ ki o joko ni ilẹ wọn, li Oluwa wi, yio si ro o, yio si gbe ibẹ.
12
Emi si wi fun Sedekiah, ọba Juda, gẹgẹ bi ọ̀rọ wọnyi, pe, Ẹ mu ọrùn nyin si abẹ àjaga ọba Babeli, ki ẹ sin i, pẹlu awọn enia rẹ̀, bẹ̃li ẹnyin o yè.
13
Ẽṣe ti ẹnyin o kú, iwọ, ati enia rẹ, nipa idà, ati ìyan, ati ajakalẹ-arun, bi Oluwa ti sọ si orilẹ-ède ti kì yio sin ọba Babeli.
14
Ẹ máṣe gbọ́ ọ̀rọ awọn woli ti nwọn nsọ fun nyin wipe, Ẹnyin kì yio sin ọba Babeli, nitori nwọn sọ asọtẹlẹ eke fun nyin.
15
Nitori emi kò rán wọn, li Oluwa wi, ṣugbọn nwọn nsọ asọtẹlẹ eke li orukọ mi: ki emi ki o lè lé nyin jade, ki ẹ ṣegbe, ẹnyin, pẹlu awọn woli ti o sọ asọtẹlẹ fun nyin.
16
Pẹlupẹlu emi sọ fun awọn alufa ati fun gbogbo enia yi wipe, Bayi li Oluwa wi, Ẹ má gbọ́ ọ̀rọ awọn woli ti nsọ asọtẹlẹ fun nyin wipe, Sa wò o, ohun-èlo ile Oluwa li a o mu pada li aipẹ nisisiyi lati Babeli wá: nitori nwọn sọ asọtẹlẹ eke fun nyin.
17
Ẹ máṣe gbọ́ ti wọn; ẹ sin ọba Babeli, ẹ si yè: ẽṣe ti ilu yi yio fi di ahoro?
18
Ṣugbọn bi nwọn ba ṣe woli, ati bi ọ̀rọ Oluwa ba wà pẹlu wọn, jẹ ki nwọn ki o bẹbẹ lọdọ Oluwa awọn ọmọ-ogun, ki ohun-èlo iyokù ni ile Oluwa ati ni ile ọba Judah, ati ni Jerusalemu, ki nwọn ki o máṣe lọ si Babeli.
19
Nitori bayi li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi niti opó mejeji, ati niti agbada nla, ati niti ipilẹṣẹ, ati niti ohun-èlo iyokù ti o kù ni ilu yi.
20
Eyi ti Nebukadnessari, ọba Babeli, kò mu lọ nigbati o mu Jekoniah, ọmọ Jehoiakimu, ọba Juda, ni igbèkun lati Jerusalemu lọ si Babeli, pẹlu gbogbo awọn ọlọla Juda ati Jerusalemu;
21
Nitori bayi li Oluwa awọn ọmọ-ogun, Ọlọrun Israeli wi, niti ohun-èlo ti o kù ni ile Oluwa, ati ni ile ọba Juda ati Jerusalemu.
22
A o kó wọn lọ si Babeli, nibẹ ni nwọn o wà titi di ọjọ na ti emi o bẹ̀ wọn wò, li Oluwa wi, emi o si mu wọn goke wá, emi o si mu wọn pada wá si ibi yi.
← Chapter 26
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 32
Chapter 33
Chapter 34
Chapter 35
Chapter 36
Chapter 37
Chapter 38
Chapter 39
Chapter 40
Chapter 41
Chapter 42
Chapter 43
Chapter 44
Chapter 45
Chapter 46
Chapter 47
Chapter 48
Chapter 49
Chapter 50
Chapter 51
Chapter 52
Chapter 28 →
All chapters:
1
2
3
4
5
6
7
8
9
10
11
12
13
14
15
16
17
18
19
20
21
22
23
24
25
26
27
28
29
30
31
32
33
34
35
36
37
38
39
40
41
42
43
44
45
46
47
48
49
50
51
52
Recommended Reading
Commentary
Jeremiah Commentaries
→
Devotional
Jeremiah Devotional Guide
→
Get This Bible
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ) Study Bible
→