bible
ra
🌐 Language
English
Español
Français
Deutsch
Português
Italiano
Nederlands
Русский
中文
日本語
한국어
العربية
Türkçe
Tiếng Việt
ไทย
Indonesia
All Languages
Home
/
Yoruba
/
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
/
Numbers 12
Numbers 12
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
← Chapter 11
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 32
Chapter 33
Chapter 34
Chapter 35
Chapter 36
Chapter 13 →
1
A TI Miriamu ati Aaroni sọ̀rọ òdi si Mose nitori obinrin ara Etiopia ti o gbé ni iyawo: nitoripe o gbé obinrin ara Etiopia kan ni iyawo.
2
Nwọn si wipe, Nipa Mose nikan ni OLUWA ha sọ̀rọ bi? kò ha ti ipa wa sọ̀rọ pẹlu? OLUWA si gbọ́ ọ.
3
Ṣugbọn ọkunrin na Mose, o ṣe ọlọkàn tutù jù gbogbo enia lọ ti mbẹ lori ilẹ.
4
OLUWA si sọ fun Mose, ati fun Aaroni, ati fun Miriamu li ojiji pe, Ẹnyin mẹtẹta ẹ jade wá si agọ́ ajọ. Awọn mẹtẹta si jade.
5
OLUWA si sọkalẹ wá ninu ọwọ̀n awọsanma, o si duro li ẹnu-ọ̀na agọ́ na, o si pè Aaroni ati Miriamu: awọn mejeji si jade wá.
6
O si wipe, Ẹ gbọ́ ọ̀rọ mi nisisiyi: bi wolĩ OLUWA ba mbẹ ninu nyin, emi OLUWA yio farahàn fun u li ojuran, emi o si bá a sọ̀rọ li oju-alá.
7
Mose iranṣẹ mi kò ri bẹ̃, olõtọ ni ninu gbogbo ile mi.
8
On li emi mbá sọ̀rọ li ẹnu ko ẹnu, ati ni gbangba, ki si iṣe li ọ̀rọ ti o ṣe òkunkun; apẹrẹ OLUWA li on o si ri: njẹ nitori kili ẹnyin kò ṣe bẹ̀ru lati sọ̀rọ òdi si Mose iranṣẹ mi?
9
Ibinu OLUWA si rú si wọn; o si lọ.
10
Awọsanma si lọ kuro lori Agọ́ na; si kiyesi i, Miriamu di adẹ̀tẹ, o fun bi òjo didì; Aaroni si wò Miriamu, si kiyesi i, o di adẹ̀tẹ.
11
Aaroni si wi fun Mose pe, Yẽ, oluwa mi, emi bẹ̀ ọ, máṣe kà ẹ̀ṣẹ na si wa lọrùn, eyiti awa fi wère ṣe, ati eyiti awa ti dẹ̀ṣẹ.
12
Emi bẹ̀ ọ máṣe jẹ ki o dabi ẹniti o kú, ẹniti àbọ ara rẹ̀ run tán nigbati o ti inu iya rẹ̀ jade.
13
Mose si kigbe pè OLUWA, wipe, Ọlọrun, emi bẹ̀ ọ, mu u lara dá nisisiyi.
14
OLUWA si wi fun Mose pe, Bi baba rẹ̀, tilẹ tu itọ si i li oju, njẹ oju ki ba tì i ni ijọ́ meje? Ki a sé e mọ́ ẹhin ibudó ni ijọ́ meje, lẹhin eyinì ki a gbà a sinu rẹ̀.
15
A si sé Miriamu mọ́ ẹhin ibudó ni ijọ́ meje: awọn enia kò si ṣí titi a fi gbà Miriamu pada.
16
Lẹhin eyinì li awọn enia si ṣí kuro ni Haserotu, nwọn si dó si ijù Parani.
← Chapter 11
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 32
Chapter 33
Chapter 34
Chapter 35
Chapter 36
Chapter 13 →
All chapters:
1
2
3
4
5
6
7
8
9
10
11
12
13
14
15
16
17
18
19
20
21
22
23
24
25
26
27
28
29
30
31
32
33
34
35
36