bible
ra
🌐 Language
English
Español
Français
Deutsch
Português
Italiano
Nederlands
Русский
中文
日本語
한국어
العربية
Türkçe
Tiếng Việt
ไทย
Indonesia
All Languages
Home
/
Yoruba
/
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
/
Numbers 7
Numbers 7
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
← Chapter 6
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 32
Chapter 33
Chapter 34
Chapter 35
Chapter 36
Chapter 8 →
1
OSI ṣe li ọjọ́ na ti Mose gbé agọ́ na ró tán, ti o si ta oróro si i ti o si yà a simimọ́, ati gbogbo ohun-èlo rẹ̀, ati pẹpẹ na ati gbogbo ohun-èlo rẹ̀, ti o si ta oróro si wọn, ti o si yà wọn simimọ́;
2
Ni awọn ijoye Israeli, awọn olori ile baba wọn, awọn olori ẹ̀ya wọnni, ti iṣe olori awọn ti a kà, mú ọrẹ wá:
3
Nwọn si mú ọrẹ-ẹbọ wọn wá siwaju OLUWA, kẹkẹ́-ẹrù mẹfa ti a bò, ati akọmalu mejila; kẹkẹ́-ẹrù kan fun ijoye meji, ati akọmalu kan fun ọkọkan: nwọn si mú wọn wá siwaju agọ́ ajọ.
4
OLUWA si sọ fun Mose pe,
5
Gbà a lọwọ wọn, ki nwọn ki o le jẹ́ ati fi ṣe iṣẹ-ìsin agọ́ ajọ; ki iwọ ki o si fi wọn fun awọn ọmọ Lefi, fun olukuluku gẹgẹ bi iṣẹ-ìsin rẹ̀.
6
Mose si gbà kẹkẹ́-ẹrù wọnni, ati akọmalu, o si fi wọn fun awọn ọmọ Lefi.
7
Kẹkẹ́-ẹrù meji ati akọmalu mẹrin, li o fi fun awọn ọmọ Gerṣoni, gẹgẹ bi iṣẹ-ìsin wọn:
8
Ati kẹkẹ́-ẹrù mẹrin ati akọmalu mẹjọ li o fi fun awọn ọmọ Merari, gẹgẹ bi iṣẹ-ìsin wọn, li ọwọ́ Itamari ọmọ Aaroni alufa.
9
Ṣugbọn kò fi fun awọn ọmọ Kohati: nitoripe iṣẹ-ìsin ibi-mimọ́ ni ti wọn; li ohun ti nwọn o ma fi ejika rù.
10
Awọn olori si mú ọrẹ wá fun ìyasimimọ́ pẹpẹ li ọjọ́ ti a ta oróro si i, ani awọn olori mú ọrẹ-ẹbọ wọn wá siwaju pẹpẹ na.
11
OLUWA si wi fun Mose pe, Ki nwọn ki o ma mú ọrẹ-ẹbọ wọn wá, olukuluku olori li ọjọ́ tirẹ̀ fun ìyasimimọ̀ pẹpẹ.
12
Ẹniti o si mú ọrẹ-ẹbọ tirẹ̀ wá li ọjọ́ kini ni Naṣoni ọmọ Amminadabu, ti ẹ̀ya Juda.
13
Ọrẹ-ẹbọ tirẹ̀ si jẹ́ awopọkọ kan ti fadakà, ìwọn rẹ̀ ãdoje ṣekeli, awokòto kan ti fadakà ãdọrin ṣekeli, gẹgẹ bi ṣekeli ibi-mimọ́; mejeji wọn kún fun iyẹfun daradara ti a fi oróro pò, fun ẹbọ ohunjijẹ;
14
Ṣibi kan ìwọn ṣekeli mẹwa wurà, o kún fun turari;
15
Ẹgbọrọ akọmalu kan, àgbo kan, akọ ọdọ-agutan kan ọlọdún kan, fun ẹbọ sisun;
16
Akọ ewurẹ kan fun ẹbọ ẹ̀ṣẹ;
17
Ati fun ẹbọ ti ẹbọ alafia, akọmalu meji, àgbo marun, obukọ marun, akọ ọdọ-agutan marun ọlọdún kan: eyi li ọrẹ-ẹbọ ti Naṣoni ọmọ Amminadabu.
18
Li ọjọ́ keji ni Netaneeli ọmọ Suari, olori ti Issakari mú ọrẹ wá:
19
On múwa fun ọrẹ-ẹbọ tirẹ̀ awopọkọ kan ti fadakà, ìwọn rẹ̀ jẹ́ ãdoje ṣekeli, awokòto kan ti fadakà ãdọrin ṣekeli, gẹgẹ bi ṣekeli ibi-mimọ́; mejeji wọn kún fun iyẹfun daradara ti a fi oróro pò, fun ẹbọ ohunjijẹ:
20
Ṣibi kan ìwọn ṣekeli mẹwa wurà, o kún fun turari;
21
Ẹgbọrọ akọmalu kan, àgbo kan, akọ ọdọ-agutan kan ọlọdún kan, fun ẹbọ sisun;
22
Akọ ewurẹ kan fun ẹbọ ẹ̀ṣẹ;
23
Ati fun ẹbọ ti ẹbọ alafia, akọmalu meji, àgbo marun, obukọ marun, akọ ọdọ-agutan marun ọlọdún kan: eyi li ọrẹ-ẹbọ ti Netaneeli ọmọ Suari.
24
Li ọjọ́ kẹta Eliabu ọmọ Heloni, olori awọn ọmọ Sebuluni:
25
Ọrẹ-ẹbọ tirẹ̀ jẹ́ awopọkọ kan ti fadakà, ìwọn rẹ̀ jẹ́ ãdoje ṣekeli, awokòto kan ti fadakà ãdọrin ṣekeli, gẹgẹ bi ṣekeli ibi-mimọ́; mejeji wọn kún fun iyẹfun daradara ti a fi oróro pò, fun ẹbọ ohunjijẹ;
26
Ṣibi kan ìwọn ṣekeli mẹwa wurà, o kún fun turari;
27
Ẹgbọrọ akọmalu kan, àgbo kan, akọ ọdọ-agutan kan ọlọdún kan, fun ẹbọ sisun;
28
Akọ ewurẹ kan fun ẹbọ ẹ̀ṣẹ;
29
Ati fun ẹbọ ti ẹbọ alafia, akọmalu meji, àgbo marun, obukọ marun, akọ ọdọ-agutan marun ọlọdún kan: eyi li ọrẹ-ẹbọ ti Eliabu ọmọ Heloni.
30
Li ọjọ́ kẹrin Elisuri ọmọ Ṣedeuri, olori awọn ọmọ Reubeni;
31
Ọrẹ-ẹbọ tirẹ̀ jẹ̀ awopọkọ kan ti fadakà, ìwọn rẹ̀ jẹ́ ãdoje ṣekeli, awokòto kan ti fadakà ãdọrin ṣekeli, gẹgẹ bi ṣekeli ibi-mimọ́; mejeji wọn kún fun iyẹfun daradara ti a fi oróro pò fun ẹbọ ohunjijẹ;
32
Ṣibi kan ìwọn ṣekeli mẹwa wurà, o kún fun turari;
33
Ẹgbọrọ akọmalu kan, àgbo kan, akọ ọdọ-agutan kan ọlọdún kan, fun ẹbọ sisun;
34
Akọ ewurẹ kan fun ẹbọ ẹ̀ṣẹ;
35
Ati fun ẹbọ ti ẹbọ alafia, akọmalu meji, àgbo marun, obukọ marun, akọ ọdọ-agutan marun ọlọdún kan: eyi li ọrẹ-ẹbọ ti Elisuri ọmọ Ṣedeuri.
36
Li ọjọ́ karun Ṣelumieli ọmọ Suriṣuddai, olori awọn ọmọ Simeoni:
37
Ọrẹ-ẹbọ tirẹ̀ jẹ́ awopọkọ kan ti fadakà, ìwọn rẹ̀ jẹ́ ãdoje ṣekeli, awokòto kan ti fadakà ãdọrin ṣekeli, gẹgẹ bi ṣekeli ibi-mimọ́; mejeji wọn kún fun iyẹfun daradara ti a fi oróro pò fun ẹbọ ohunjijẹ;
38
Ṣibi kan ìwọn ṣekeli mẹwa wurà, o kún fun turari;
39
Ẹgbọrọ akọmalu kan, àgbo kan, akọ ọdọ-agutan kan ọlọdún kan, fun ẹbọ sisun;
40
Akọ ewurẹ kan fun ẹbọ ẹ̀ṣẹ;
41
Ati fun ẹbọ ti ẹbọ alafia, akọmalu meji, àgbo marun, obukọ marun, akọ ọdọ-agutan marun ọlọdún kan: eyi li ọrẹ-ẹbọ Ṣelumieli ọmọ Ṣuriṣaddai.
42
Li ọjọ́ kẹfa Eliasafu ọmọ Deueli, olori awọn ọmọ Gadi:
43
Ọrẹ-ẹbọ tirẹ̀ jẹ́ awopọkọ kan ti fadakà, ìwọn rẹ̀ jẹ́ ãdoje ṣekeli, awokòto kan ti fadakà ãdọrin ṣekeli, gẹgẹ bi ṣekeli ibi-mimọ́; mejeji wọn kún fun iyẹfun daradara ti a fi oróro pò fun ẹbọ ohunjijẹ;
44
Ṣibi kan ìwọn ṣekeli mẹwa wurà, o kún fun turari;
45
Ẹgbọrọ akọmalu kan, àgbo kan, akọ ọdọ-agutan kan ọlọdún kan, fun ẹbọ sisun;
46
Akọ ewure kan fun ẹbọ ẹ̀ṣẹ;
47
Ati fun ẹbọ ti ẹbọ alafia, akọmalu meji, àgbo marun, obukọ marun, akọ ọdọ-agutan marun ọlọdún kan: eyi li ọrẹ-ẹbọ Eliasafu ọmọ Deueli.
48
Li ọjọ́ keje Eliṣama ọmọ Ammihudu, olori awọn ọmọ Efraimu:
49
Ọrẹ-ẹbọ tirẹ̀ jẹ́ awopọkọ kan ti fadakà, ìwọn rẹ̀ jẹ́ ãdoje ṣekeli, awokòto kan ti fadakà ãdọrin ṣekeli, gẹgẹ bi ṣekeli ibi-mimọ́; mejeji wọn kún fun iyẹfun daradara ti a fi oróro pò, fun ẹbọ ohunjijẹ;
50
Ṣibi kan ìwọn ṣekeli mẹwa wurà, o kún fun turari;
51
Ẹgbọrọ akọmalu kan, àgbo kan, akọ ọdọ-agutan kan ọlọdún kan, fun ẹbọ sisun;
52
Akọ ewurẹ kan fun ẹbọ ẹ̀ṣẹ;
53
Ati fun ẹbọ ti ẹbọ alafia, akọmalu meji, àgbo marun, obukọ marun, akọ ọdọ-agutan marun ọlọdún kan: eyi li ọrẹ-ẹbọ Eliṣama ọmọ Ammihudu.
54
Li ọjọ́ kẹjọ Gamalieli ọmọ Pedasuri, olori awọn ọmọ Manasse:
55
Ọrẹ-ẹbọ tirẹ̀ jẹ́ awopọkọ kan ti fadakà, ìwọn rẹ̀ jẹ́ ãdoje ṣekeli, awokòto kan ti fadakà ãdọrin ṣekeli, gẹgẹ bi ṣekeli ibi-mimọ́; mejeji wọn kún fun iyẹfun daradara ti a fi oróro pò, fun ẹbọ ohunjijẹ;
56
Ṣibi kan ìwọn ṣekeli mẹwa wurà, o kún fun turari;
57
Ẹgbọrọ akọmalu kan, àgbo kan, akọ ọdọ-agutan kan ọlọdún kan, fun ẹbọ sisun;
58
Akọ ewurẹ kan fun ẹbọ ẹ̀ṣẹ;
59
Ati fun ẹbọ ti ẹbọ alafia, akọmalu meji, àgbo marun, obukọ marun, akọ ọdọ-agutan marun ọlọdún kan: eyi li ọrẹ-ẹbọ ti Gamalieli ọmọ Pedasuri.
60
Li ọjọ́ kẹsan Abidani ọmọ Gideoni, olori awọn ọmọ Benjamini:
61
Ọrẹ-ẹbọ tirẹ̀ jẹ́ awopọkọ kan ti fadakà, ìwọn rẹ̀ jẹ́ ãdoje ṣekeli, awokòto kan ti fadakà ãdọrin ṣekeli, gẹgẹ bi ṣekeli ibi-mimọ́; mejeji wọn kún fun iyẹfun daradara ti a fi oróro pò, fun ẹbọ ohunjijẹ;
62
Ṣibi kan ìwọn ṣekeli mẹwa wurà, o kún fun turari;
63
Ẹgbọrọ akọmalu kan, àgbo kan, akọ ọdọ-agutan kan ọlọdún kan, fun ẹbọ sisun;
64
Akọ ewurẹ kan fun ẹbọ ẹ̀ṣẹ;
65
Ati fun ẹbọ ti ẹbọ alafia, akọmalu meji, àgbo marun, obukọ marun, akọ ọdọ-agutan marun ọlọdún kan: eyi li ọrẹ-ẹbọ ti Abidani ọmọ Gideoni.
66
Li ọjọ́ kẹwá ni Ahieseri ọmọ Ammiṣaddai, olori awọn ọmọ Dani:
67
Ọrẹ-ẹbọ tirẹ̀ jẹ́ awopọkọ kan ti fadakà, ìwọn rẹ̀ jẹ́ ãdoje ṣekeli, awokòto kan ti fadakà ìwọn ãdọrin ṣekeli, gẹgẹ bi ṣekeli ibi-mimọ́; mejeji wọn kún fun iyẹfun daradara ti a fi oróro pò, fun ẹbọ ohunjijẹ:
68
Ṣibi kan ìwọn ṣekeli mẹwa wurà, o kún fun turari;
69
Ẹgbọrọ akọmalu kan, àgbo kan, akọ ọdọ-agutan kan ọlọdún kan, fun ẹbọ sisun;
70
Akọ ewurẹ kan fun ẹbọ ẹ̀ṣẹ;
71
Ati fun ẹbọ ti ẹbọ alafia, akọmalu meji, àgbo marun, obukọ marun, akọ ọdọ-agutan marun ọlọdún kan: eyi li ọrẹ-ẹbọ ti Ahieseri ọmọ Ammiṣaddai.
72
Li ọjọ́kọkanla Pagieli ọmọ Okrani, olori awọn ọmọ Aṣeri:
73
Ọrẹ-ẹbọ tirẹ̀ jẹ́ awopọkọ kan ti fadakà, ìwọn rẹ̀ jẹ́ ãdoje ṣekeli, awokòto kan ti fadakà ìwọn ãdọrin ṣekeli, gẹgẹ bi ṣekeli ibi-mimọ́; mejeji wọn kún fun iyẹfun daradara ti a fi oróro pò, fun ẹbọ ohunjijẹ;
74
Ṣibi kan ìwọn ṣekeli mẹwa wurà, o kún fun turari;
75
Ẹgbọrọ akọmalu kan, àgbo kan, akọ ọdọ-agutan kan ọlọdún kan, fun ẹbọ sisun;
76
Akọ ewurẹ kan fun ẹbọ ẹ̀ṣẹ;
77
Ati fun ẹbọ ti ẹbọ alafia, akọmalu meji, àgbo marun, obukọ marun, akọ ọdọ-agutan marun ọlọdún kan: eyi li ọrẹ-ẹbọ ti Pagieli ọmọ Okrani.
78
Li ọjọ́ kejila Ahira ọmọ Enani, olori awọn ọmọ Naftali:
79
Ọrẹ-ẹbọ tirẹ̀ jẹ̀ awopọkọ kan ti fadakà, ìwọn rẹ̀ jẹ́ ãdoje ṣekeli, awokòto kan ti fadakà ãdọrin ṣekeli, gẹgẹ bi ṣekeli ibi-mimọ́; mejeji wọn kún fun iyẹfun daradara ti a fi oróro pò, fun ẹbọ ohunjijẹ;
80
Ṣibi kan ìwọn ṣekeli mẹwa wurà, o kún fun turari;
81
Ẹgbọrọ akọmalu kan, àgbo kan, akọ ọdọ-agutan kan ọlọdún kan, fun ẹbọ sisun;
82
Akọ ewurẹ kan fun ẹbọ ẹ̀ṣẹ;
83
Ati fun ẹbọ ti ẹbọ alafia, akọmalu meji, àgbo marun, obukọ marun, akọ ọdọ-agutan marun ọlọdún kan: eyi li ọrẹ-ẹbọ ti Ahira ọmọ Enani.
84
Eyi ni ìyasimimọ́ pẹpẹ, li ọjọ́ ti a ta oróro si i, lati ọwọ́ awọn olori Israeli wá: awopọkọ fadakà mejila, awokòto fadakà mejila, ṣibi wurà mejila:
85
Awopọkọ fadakà kọkan jẹ́ ãdoje ṣekeli: awokòto kọkan jẹ́ ãdọrin: gbogbo ohun-èlo fadakà jẹ́ egbejila ṣekeli, gẹgẹ bi ṣekeli ibi-mimọ́;
86
Ṣibi wurà jẹ́ mejila, nwọn kún fun turari, ṣibi kọkan jẹ́ ṣekeli mẹwa, gẹgẹ bi ṣekeli ibi-mimọ́; gbogbo wurà agọ́ na jẹ́ ọgọfa ṣekeli.
87
Gbogbo akọmalu fun ẹbọ sisun jẹ́ ẹgbọrọ akọmalu mejila, àgbo mejila, akọ ọdọ-agutan ọlọdún kan mejila, pẹlu ẹbọ ohunjijẹ wọn: ati akọ ewurẹ fun ẹbọ ẹ̀ṣẹ, mejila.
88
Ati gbogbo akọmalu fun ẹbọ ti ẹbọ alafia jẹ́ akọmalu mẹrinlelogun, àgbo ọgọta, obukọ ọgọta, akọ ọdọ-agutan ọlọdún kan ọgọta. Eyi ni ìyasimimọ́ pẹpẹ, lẹhin igbati a ta oróro si i.
89
Nigbati Mose si wọ̀ inu agọ́ ajọ lọ lati bá a (Ọlọrun) sọ̀rọ, nigbana li o gbọ́ ohùn ti nfọ̀ si i lati ori itẹ́-ãnu nì wá ti mbẹ lori apoti ẹrí, lati agbedemeji awọn kerubu meji nì wá: o si bá a sọ̀rọ.
← Chapter 6
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 32
Chapter 33
Chapter 34
Chapter 35
Chapter 36
Chapter 8 →
All chapters:
1
2
3
4
5
6
7
8
9
10
11
12
13
14
15
16
17
18
19
20
21
22
23
24
25
26
27
28
29
30
31
32
33
34
35
36