bible
ra
🌐 Language
English
Español
Français
Deutsch
Português
Italiano
Nederlands
Русский
中文
日本語
한국어
العربية
Türkçe
Tiếng Việt
ไทย
Indonesia
All Languages
Home
/
Yoruba
/
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
/
Numbers 27
Numbers 27
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
← Chapter 26
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 32
Chapter 33
Chapter 34
Chapter 35
Chapter 36
Chapter 28 →
1
NIGBANA ni awọn ọmọbinrin Selofehadi, ọmọ Heferi, ọmọ Gileadi, ọmọ Makiri, ọmọ Manasse, ti idile Manasse ọmọ Josefu wá: wọnyi si li orukọ awọn ọmọbinrin rẹ̀; Mala, Noa, ati Hogla, ati Milka, ati Tirsa.
2
Nwọn si duro niwaju Mose, ati niwaju Eleasari alufa, ati niwaju awọn olori ati gbogbo ijọ, li ẹnu-ọ̀na agọ́ ajọ, wipe,
3
Baba wa kú li aginjù, on kò si sí ninu ẹgbẹ awọn ti o kó ara wọn jọ pọ̀ si OLUWA ninu ẹgbẹ Kora: ṣugbọn o kú ninu ẹ̀ṣẹ ara rẹ̀; kò si lí ọmọkunrin.
4
Ẽhaṣe ti orukọ, baba wa yio fi parẹ kuro ninu idile rẹ̀, nitoriti kò lí ọmọkunrin? Fun wa ni ilẹ-iní lãrin awọn arakunrin baba wa.
5
Mose si mú ọ̀ran wọn wá siwaju OLUWA.
6
OLUWA si sọ fun Mose pe,
7
Awọn ọmọbinrin Selofehadi sọ rere: nitõtọ, fun wọn ni ilẹ-iní kan lãrin awọn arakunrin baba wọn; ki iwọ ki o si ṣe ki ilẹ-iní baba wọn ki o kọja sọdọ wọn.
8
Ki iwọ ki o si sọ fun awọn ọmọ Israeli pe, Bi ọkunrin kan ba kú, ti kò si lí ọmọkunrin, njẹ ki ẹnyin ki o ṣe ki ilẹ-iní rẹ̀ ki o kọja sọdọ ọmọbinrin rẹ̀.
9
Bi on kò ba si lí ọmọbinrin, njẹ ki ẹnyin ki o fi ilẹ-ini rẹ̀ fun awọn arakunrin rẹ̀.
10
Bi on kò ba si lí arakunrin, njẹ ki ẹnyin ki o fi ilẹ-iní rẹ̀ fun awọn arakunrin baba rẹ̀:
11
Bi baba rẹ̀ kò ba si lí arakunrin, njẹ ki ẹnyin ki o fi ilẹ-iní rẹ̀ fun ibatan rẹ̀, ti o sunmọ ọ ni idile rẹ̀, on ni ki o jogún rẹ̀: yio si jasi ìlana idajọ fun awọn ọmọ Israeli, gẹgẹ bi OLUWA ti paṣẹ fun Mose.
12
OLUWA si sọ fun Mose pe, Gùn ori òke Abarimu yi lọ, ki o si wò ilẹ na ti mo fi fun awọn ọmọ Israeli.
13
Nigbati iwọ ba ri i tán, a o si kó iwọ jọ pẹlu awọn enia rẹ, gẹgẹ bi a ti kó Aaroni arakunrin rẹ jọ.
14
Nitoriti ẹnyin ṣọ̀tẹ si aṣẹ mi li aginjù Sini, ni ìja ijọ, lati yà mi simimọ́ ni ibi omi nì niwaju wọn. (Wọnyi li omi Meriba ni Kadeṣi li aginjù Sini.)
15
Mose si sọ fun OLUWA pe,
16
Jẹ ki OLUWA, Ọlọrun ẹmi gbogbo enia, ki o yàn ọkunrin kan sori ijọ,
17
Ti yio ma ṣaju wọn jade lọ, ti yio si ma ṣaju wọn wọle wá, ti yio si ma sìn wọn lọ, ti yio si ma mú wọn bọ̀; ki ijọ enia OLUWA ki o máṣe dabi agutan ti kò lí oluṣọ.
18
OLUWA si sọ fun Mose pe, Iwọ mú Joṣua ọmọ Nuni, ọkunrin ninu ẹniti ẹmi wà, ki o si fi ọwọ́ rẹ lé e lori;
19
Ki o si mu u duro niwaju Eleasari alufa, ati niwaju gbogbo ijọ; ki o si fi aṣẹ fun u li oju wọn.
20
Ki iwọ ki o si fi ninu ọlá rẹ si i lara, ki gbogbo ijọ awọn ọmọ Israeli ki o le gbà a gbọ́.
21
Ki on si duro niwaju Eleasari alufa, ẹniti yio bère fun u nipa idajọ Urimu niwaju OLUWA: nipa ọ̀rọ rẹ̀ ni ki nwọn ki o jade lọ, ati nipa ọ̀rọ rẹ̀ ni ki nwọn ki o wọle, ati on, ati gbogbo awọn ọmọ Israeli pẹlu rẹ̀, ani gbogbo ijọ.
22
Mose si ṣe bi OLUWA ti paṣẹ fun u: o si mú Joṣua, o si mu u duro niwaju Eleasari alufa, ati niwaju gbogbo ijọ:
23
O si fi ọwọ́ rẹ̀ lé e lori, o si fi aṣẹ fun u, bi OLUWA ti wi lati ọwọ́ Mose.
← Chapter 26
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 32
Chapter 33
Chapter 34
Chapter 35
Chapter 36
Chapter 28 →
All chapters:
1
2
3
4
5
6
7
8
9
10
11
12
13
14
15
16
17
18
19
20
21
22
23
24
25
26
27
28
29
30
31
32
33
34
35
36