bible
ra
🌐 Language
English
Español
Français
Deutsch
Português
Italiano
Nederlands
Русский
中文
日本語
한국어
العربية
Türkçe
Tiếng Việt
ไทย
Indonesia
All Languages
Home
/
Yoruba
/
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
/
Song of Solomon 2
Song of Solomon 2
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
← Chapter 1
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 3 →
1
EMI ni itanná eweko Ṣaroni, ati itanná lili awọn afonifoji.
2
Bi itanná lili lãrin ẹgún, bẹ̃li olufẹ mi ri lãrin awọn ọmọbinrin.
3
Bi igi eleso lãrin awọn igi igbẹ, bẹ̃li olufẹ mi ri lãrin awọn ọmọkunrin. Emi fi ayọ̀ nla joko labẹ ojiji rẹ̀, eso rẹ̀ si dùn mọ mi li ẹnu.
4
O mu mi wá si ile ọti-waini, Ifẹ si ni ọpagun rẹ̀ lori mi.
5
Fi akara didùn da mi duro, fi eso igi tù mi ni inu: nitori aisàn ifẹ nṣe mi.
6
Ọwọ osì rẹ̀ mbẹ labẹ ori mi, ọwọ ọtún rẹ̀ si gbá mi mọra.
7
Mo fi awọn abo egbin, ati awọn abo agbọnrin igbẹ fi nyin bú, ẹnyin ọmọbinrin Jerusalemu, ki ẹ máṣe rú olufẹ mi soke, ki ẹ má si ṣe ji i, titi yio fi wù u.
8
Ohùn olufẹ mi! sa wò o, o mbọ̀, o nfò lori awọn òke, o mbẹ lori awọn òke kékeké.
9
Olufẹ mi dabi abo egbin, tabi ọmọ agbọnrin: sa wò o, o duro lẹhin ogiri wa, o yọju loju ferese, o nfi ara rẹ̀ hàn loju ferese ọlọnà.
10
Olufẹ mi sọ̀rọ, o si wi fun mi pe, Dide, olufẹ mi, arẹwà mi kanna, ki o si jade kalọ.
11
Sa wò o, ìgba otutu ti kọja, òjo ti da, o si ti lọ.
12
Awọn itanna eweko farahàn lori ilẹ; akoko ikọrin awọn ẹiyẹ de, a si gbọ ohùn àdaba ni ilẹ wa.
13
Igi ọ̀pọtọ so eso titun, awọn àjara funni ni õrun daradara nipa itanná wọn. Dide, olufẹ mi, arẹwà mi kanna, ki o si jade kalọ.
14
Adaba mi, ti o wà ninu pàlapala okuta, ni ibi ìkọkọ okuta, jẹ ki emi ri oju rẹ, jẹ ki emi gbọ́ ohùn rẹ; nitori didùn ni ohùn rẹ, oju rẹ si li ẹwà.
15
Mu awọn kọ̀lọkọlọ fun wa, awọn kọ̀lọkọlọ kékeké ti mba àjara jẹ: nitori àjara wa ni itanná.
16
Olufẹ mi ni temi, emi si ni tirẹ̀: o njẹ lãrin awọn lili.
17
Titi ìgba itura ọjọ, titi ojiji yio fi salọ, yipada, olufẹ mi, ki iwọ ki o si dabi abo egbin, tabi ọmọ agbọnrin lori awọn oke Beteri.
← Chapter 1
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 3 →
All chapters:
1
2
3
4
5
6
7
8