bible
ra
🌐 Language
English
Español
Français
Deutsch
Português
Italiano
Nederlands
Русский
中文
日本語
한국어
العربية
Türkçe
Tiếng Việt
ไทย
Indonesia
All Languages
Home
/
Yoruba
/
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
/
Song of Solomon 3
Song of Solomon 3
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
← Chapter 2
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 4 →
1
LI oru lori akete mi, mo wá ẹniti ọkàn mi fẹ: emi wá a, ṣugbọn emi kò ri i.
2
Emi o dide nisisiyi, emi o si rìn lọ ni ilu, ni igboro, ati li ọ̀na gbòro ni emi o wá ẹniti ọkàn mi fẹ: emi wá a, ṣugbọn emi kò ri i.
3
Awọn oluṣọ ti nrìn ilu yika ri mi: mo bère pe, Ẹ ha ri ẹniti ọkàn mi fẹ bi?
4
Ṣugbọn bi mo ti fi wọn silẹ gẹrẹ ni mo ri ẹniti ọkàn mi fẹ: mo dì i mu, emi kò si jọ̃rẹ̀ lọwọ, titi mo fi mu u wá sinu ile iya mi, ati sinu iyẹwu ẹniti o loyun mi.
5
Mo fi awọn abo egbin ati awọn abo agbọnrin igbẹ fi nyin bú, ẹnyin ọmọbinrin Jerusalemu, ki ẹ máṣe rú olufẹ mi soke, ki ẹ má si ji i, titi yio fi wù u.
6
Tani eyi ti nti ijù jade wá bi ọwọ̀n ẽfin, ti a ti fi ojia ati turari kùn lara, pẹlu gbogbo ipara olõrun oniṣowo?
7
Wo akete rẹ̀, ti iṣe ti Solomoni; ọgọta akọni enia li o yi i ka ninu awọn akọni Israeli.
8
Gbogbo wọn li o di idà mu, nwọn gbọ́n ọgbọ́n ogun: olukulùku kọ́ idà rẹ̀ nitori ẹ̀ru li oru.
9
Solomoni, ọba, ṣe akete nla fun ara rẹ̀ lati inu igi Lebanoni.
10
O fi fadaka ṣe ọwọ̀n rẹ̀, o fi wura ṣe ibi ẹhin rẹ̀, o fi elese aluko ṣe ibujoko rẹ̀, inu rẹ̀ li o fi ifẹ tẹ́ nitori awọn ọmọbinrin Jerusalemu.
11
Ẹ jade lọ, Ẹnyin ọmọbinrin Sioni, ki ẹ si wò Solomoni, ọba, ti on ti ade ti iya rẹ̀ fi de e li ọjọ igbeyawo rẹ̀, ati li ọjọ ayọ̀ ọkàn rẹ̀.
← Chapter 2
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 4 →
All chapters:
1
2
3
4
5
6
7
8