bible
ra
🌐 Language
English
Español
Français
Deutsch
Português
Italiano
Nederlands
Русский
中文
日本語
한국어
العربية
Türkçe
Tiếng Việt
ไทย
Indonesia
All Languages
Home
/
Yoruba
/
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
/
Song of Solomon 6
Song of Solomon 6
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
← Chapter 5
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 7 →
1
NIBO ni olufẹ rẹ lọ, iwọ arẹwà julọ ninu awọn obinrin? nibo li olufẹ rẹ yà si? ki a le ba ọ wá a.
2
Olufẹ mi sọkalẹ lọ sinu ọgba rẹ̀, si ebè turari, lati ma jẹ̀ ninu ọgbà, ati lati ká itanna lili.
3
Emi ni ti olufẹ mi, olufẹ mi si ni ti emi: o njẹ̀ lãrin itanna lili.
4
Iwọ yanju, olufẹ mi, bi Tirsa, o li ẹwà bi Jerusalemu, ṣugbọn o li ẹ̀ru bi ogun pẹlu ọpagun.
5
Mu oju rẹ kuro lara mi nitori nwọn bori mi: irun rẹ si dabi ọwọ́ ewurẹ ti o dubulẹ ni Gileadi.
6
Ehin rẹ dabi ọwọ́ agutan ti ngòke lati ibi iwẹ̀ wá, ti olukuluku wọn bi ìbejì, kò si si ọkan ti o yàgan ninu wọn.
7
Bi ẹ̀la eso-pomegranate kan ni ẹrẹkẹ rẹ ri lãrin iboju rẹ.
8
Ọgọta ayaba ni mbẹ, ati ọgọrin àle, ati awọn wundia lainiye.
9
Ọkan ni adaba mi, alailabawọn mi; on nikanṣoṣo ni ti iya rẹ̀, on ni ãyo ẹniti o bi i. Awọn ọmọbinrin ri i, nwọn si sure fun u; ani awọn ayaba ati awọn àle, nwọn si yìn i.
10
Tali ẹniti ntàn jàde bi owurọ, ti o li ẹwà bi oṣupa, ti o mọ́ bi õrun, ti o si li ẹ̀ru bi ogun pẹlu ọpagun?
11
Emi sọkalẹ lọ sinu ọgba eso igi, lati ri awọn ẹka igi tutu afonifoji, ati lati ri bi ajara ba ruwe, ati bi igi-granate ba rudi.
12
Ki emi to mọ̀, ọkàn mi gbe mi ka ori kẹkẹ́ Amminadibu.
13
Pada, pada, Ṣulamite; pada, pada, ki awa ki o le wò ọ. Ẽṣe ti ẹnyin fẹ wò Ṣulamite bi ẹnipe orin ijó Mahanaimu.
← Chapter 5
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 7 →
All chapters:
1
2
3
4
5
6
7
8