bible
ra
🌐 Language
English
Español
Français
Deutsch
Português
Italiano
Nederlands
Русский
中文
日本語
한국어
العربية
Türkçe
Tiếng Việt
ไทย
Indonesia
All Languages
Home
/
Yoruba
/
Yoruba 2010
/
Numbers 25
Numbers 25
Yoruba 2010
← Chapter 24
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 32
Chapter 33
Chapter 34
Chapter 35
Chapter 36
Chapter 26 →
1
Nígbà tí àwọn ọmọ Israẹli pàgọ́ sí àfonífojì Ṣitimu, àwọn ọkunrin wọn ń bá àwọn ọmọbinrin Moabu tí wọ́n wà níbẹ̀ ṣe àgbèrè.
2
Àwọn obinrin wọnyi a sì máa pè wọ́n lọ síbi àsè ìbọ̀rìṣà. Wọn a máa jẹ oúnjẹ wọn, wọn a sì ma bá wọn bọ oriṣa wọn.
3
Báyìí ni àwọn ọmọ Israẹli ṣe da ara wọn pọ̀ mọ́ oriṣa Baali tí ó wà ní Peori, ibinu OLUWA sì ru sí wọn.
4
OLUWA bá sọ fún Mose pé, “Mú gbogbo àwọn olórí Israẹli, kí o so wọ́n kọ́ sórí igi ninu oòrùn títí tí wọn óo fi kú níwájú OLUWA. Nígbà náà ni n kò tó ni bínú sí àwọn eniyan náà mọ́.”
5
Mose sì wí fún àwọn onídàájọ́ Israẹli pé, “Olukuluku yín gbọdọ̀ pa àwọn eniyan rẹ̀ tí ó lọ sin oriṣa Baali tí ó wà ní Peori.”
6
Ọ̀kan ninu àwọn ọmọ Israẹli mú ọmọbinrin Midiani wọlé lójú Mose ati gbogbo àwọn eniyan, níbi tí wọ́n ti ń sọkún lẹ́nu ọ̀nà Àgọ́ Àjọ níwájú OLUWA.
7
Nígbà tí Finehasi, ọmọ Eleasari, ọmọ Aaroni, alufaa, rí i, ó dìde láàrin àwọn eniyan, ó sì mú ọ̀kọ̀ kan,
8
ó tọ ọkunrin náà lọ ninu àgọ́ rẹ̀, ó sì fi ọ̀kọ̀ náà gún òun ati obinrin náà ní àgúnyọ. Àjàkálẹ̀ àrùn sì dúró láàrin àwọn ọmọ Israẹli.
9
Àwọn tí wọ́n kú ninu àjàkálẹ̀ àrùn náà jẹ́ ẹgbaa mejila (24,000).
10
OLUWA sọ fún Mose pé,
11
“N kò ní bínú sí Israẹli mọ nítorí ohun tí Finehasi ọmọ Eleasari, ọmọ Aaroni, alufaa, ṣe. Ó kọ̀ láti gba ìbọ̀rìṣà láàyè, nítorí náà ni n kò ṣe ní fi ibinu pa àwọn ọmọ Israẹli run.
12
Nítorí náà, sọ fún un pé mo bá a dá majẹmu alaafia.
13
Majẹmu náà ni pé mo ti yan òun ati arọmọdọmọ rẹ̀ láti máa ṣe alufaa ní Israẹli títí lae nítorí pé ó ní ìtara fún Ọlọrun rẹ̀, ó sì ṣe ètùtù fún ẹ̀ṣẹ̀ àwọn eniyan Israẹli.”
14
Orúkọ ọmọ Israẹli tí ó pa pẹlu ọmọbinrin Midiani ni Simiri, ọmọ Salu, olórí ilé kan ninu ẹ̀yà Simeoni.
15
Orúkọ ọmọbinrin Midiani náà ni Kosibi, ọmọ Suri, baálé ilé kan ní ilẹ̀ Midiani.
16
OLUWA sọ fún Mose pé,
17
“Kọlu àwọn ará Midiani, kí o sì pa wọ́n run
18
nítorí ibi tí wọ́n ṣe, ati títàn tí wọ́n tàn yín ní Peori, ati nítorí ọ̀rọ̀ Kosibi, ọmọ baálé kan ní ilẹ̀ Midiani, arabinrin wọn, tí a pa nígbà àjàkálẹ̀ àrùn ti Peori.”
← Chapter 24
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 32
Chapter 33
Chapter 34
Chapter 35
Chapter 36
Chapter 26 →
All chapters:
1
2
3
4
5
6
7
8
9
10
11
12
13
14
15
16
17
18
19
20
21
22
23
24
25
26
27
28
29
30
31
32
33
34
35
36