bible
ra
🌐 Language
English
Español
Français
Deutsch
Português
Italiano
Nederlands
Русский
中文
日本語
한국어
العربية
Türkçe
Tiếng Việt
ไทย
Indonesia
All Languages
Home
/
Yoruba
/
Yoruba 2010
/
Numbers 28
Numbers 28
Yoruba 2010
← Chapter 27
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 32
Chapter 33
Chapter 34
Chapter 35
Chapter 36
Chapter 29 →
1
OLUWA sọ fún Mose
2
pé kí ó pàṣẹ fún àwọn ọmọ Israẹli kí wọn máa mú ọrẹ wá fún ohun ìrúbọ sí òun OLUWA ní àkókò rẹ̀, ati àwọn nǹkan tí wọn yóo máa fi rú ẹbọ sísun olóòórùn dídùn.
3
“Ọrẹ tí wọn óo máa mú wá fún ẹbọ sísun tí ẹ óo máa rú sí OLUWA nìwọ̀nyí: ọ̀dọ́ aguntan meji ọlọ́dún kan tí kò ní àbààwọ́n fún ẹbọ sísun ojoojumọ:
4
Ọ̀dọ́ aguntan kan fún ẹbọ àárọ̀ ati ọ̀dọ́ aguntan kan fún ẹbọ àṣáálẹ́,
5
pẹlu ìdámẹ́wàá ìyẹ̀fun òṣùnwọ̀n efa tí a fi idamẹrin òṣùnwọ̀n hini òróró tí a gún pọ̀.
6
Èyí ni ẹbọ sísun ojoojumọ tí a ti fi ìlànà rẹ̀ lélẹ̀ ní òkè Sinai gẹ́gẹ́ bí ẹbọ sísun olóòórùn dídùn sí OLUWA.
7
Ẹbọ ohun mímu rẹ̀ yóo máa jẹ́ idamẹrin òṣùnwọ̀n hini fún ọ̀dọ́ aguntan kan. O óo sì ta ọtí líle náà sílẹ̀ lẹ́bàá pẹpẹ ìrúbọ bí ẹbọ sí OLUWA.
8
Ní ìrọ̀lẹ́, kí o fi ọ̀dọ́ aguntan keji rúbọ bíi ti ẹbọ ohun jíjẹ òwúrọ̀ pẹlu ẹbọ ohun mímu rẹ̀. Èyí yóo máa jẹ́ ẹbọ sísun, olóòórùn dídùn sí OLUWA.
9
“Ní ọjọ́ ìsinmi, ẹ fi ọ̀dọ́ aguntan meji ọlọ́dún kan tí kò ní àbààwọ́n rú ẹbọ pẹlu idamẹrin ìyẹ̀fun òṣùnwọ̀n efa tí a fi òróró pò fún ẹbọ ohun jíjẹ pẹlu ẹbọ ohun mímu.
10
Ẹ óo máa rú ẹbọ sísun yìí ní gbogbo ọjọ́ ìsinmi pẹlu ẹbọ ojoojumọ ati ẹbọ ohun mímu.
11
“Ẹ óo máa rú ẹbọ sísun sí OLUWA ní ìbẹ̀rẹ̀ oṣù. Àwọn nǹkan tí ẹ óo máa fi rúbọ ni: ọ̀dọ́ akọ mààlúù meji ati àgbò kan ati ọ̀dọ́ àgbò meje ọlọ́dún kọ̀ọ̀kan, tí kò ní àbààwọ́n.
12
Fún ẹbọ ohun jíjẹ, ẹ lo ìdámẹ́wàá mẹta ìyẹ̀fun òṣùnwọ̀n efa, tí a fi òróró pò fún akọ mààlúù kan ati idamẹrin ìyẹ̀fun òṣùnwọ̀n efa tí a fi òróró pò fún àgbò kan.
13
Ati ìdámẹ́wàá òṣùnwọ̀n ìyẹ̀fun tí a fi òróró pò fún ọ̀dọ́ aguntan kan. Èyí jẹ́ ẹbọ sísun olóòórùn dídùn fún OLUWA.
14
Kí ẹbọ ohun mímu jẹ́ ààbọ̀ òṣùnwọ̀n hini ọtí waini fún akọ mààlúù kan, ìdámẹ́ta òṣùnwọ̀n hini ọtí waini fún àgbò kan ati idamẹrin òṣùnwọ̀n hini ọtí waini fún ọ̀dọ́ aguntan kan. Èyí ni ìlànà ẹbọ sísun ti ìbẹ̀rẹ̀ oṣù.
15
Yàtọ̀ sí ẹbọ sísun ati ẹbọ ohun mímu ojoojumọ yìí, ẹ óo tún fi òbúkọ kan rú ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ sí OLUWA.
16
“Ọjọ́ kẹrinla oṣù kinni ni Àjọ̀dún Ìrékọjá OLUWA.
17
Ọjọ́ kẹẹdogun oṣù náà ni ọjọ́ àjọ̀dún, ẹ óo máa jẹ burẹdi tí kò ní ìwúkàrà fún ọjọ́ meje.
18
Ní ọjọ́ kinni àjọ̀dún náà ẹ óo máa ní àpèjọ mímọ́, ẹ kò gbọdọ̀ ṣe iṣẹ́ líle kankan.
19
Kí ẹ máa fi ọ̀dọ́ akọ mààlúù meji, ati àgbò kan ati ọ̀dọ́ àgbò meje ọlọ́dún kọ̀ọ̀kan, tí wọn kò ní àbààwọ́n rú ẹbọ sísun sí OLUWA.
20
Ẹbọ ohun jíjẹ tí ẹ óo rú pẹlu wọn ni ìyẹ̀fun tí a fi òróró pò, ìdámẹ́wàá lọ́nà mẹta òṣùnwọ̀n efa fún akọ mààlúù kan, ati ìdámárùn-ún òṣùnwọ̀n efa fún àgbò kan,
21
ìdámẹ́wàá òṣùnwọ̀n efa fún ọ̀dọ́ aguntan kọ̀ọ̀kan;
22
ati òbúkọ kan fún ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀ láti ṣe ètùtù fun yín.
23
Ẹ óo máa rú àwọn ẹbọ wọnyi yàtọ̀ sí ẹbọ sísun ojoojumọ.
24
Báyìí ni ẹ óo ṣe rú ẹbọ sísun olóòórùn dídùn sí OLUWA ní ojoojumọ fún ọjọ́ meje náà yàtọ̀ sí ẹbọ sísun ati ẹbọ ohun mímu ojoojumọ.
25
Ní ọjọ́ keje ẹ óo máa ní àpèjọ mímọ́, ẹ kò sì gbọdọ̀ ṣe iṣẹ́ líle kankan.
26
“Ní ọjọ́ kinni àjọ̀dún ìkórè, nígbà tí ẹ óo bá mú ẹbọ ohun jíjẹ ti ọkà titun wá fún OLUWA, ẹ óo máa ní àpèjọ mímọ́, ẹ kò sì gbọdọ̀ ṣe iṣẹ́ líle kankan.
27
Kí ẹ fi ọ̀dọ́ akọ mààlúù meji, ati àgbò kan, ati ọ̀dọ́ àgbò meje ọlọ́dún kọ̀ọ̀kan rú ẹbọ sísun olóòórùn dídùn sí OLUWA.
28
Ẹbọ ohun jíjẹ tí ẹ óo máa rú pẹlu wọn ni ìyẹ̀fun tí a fi òróró pò: ìdámẹ́wàá lọ́nà mẹta òṣùnwọ̀n efa fún akọ mààlúù kan, ati ìdámárùn-ún òṣùnwọ̀n efa fún àgbò kan,
29
ati ìdámẹ́wàá òṣùnwọ̀n efa fún ọ̀dọ́ aguntan kọ̀ọ̀kan;
30
ati òbúkọ kan fún ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀ láti ṣe ètùtù fun yín.
31
Ẹ óo máa rú àwọn ẹbọ wọnyi pẹlu ẹbọ ohun mímu wọn, yàtọ̀ sí ẹbọ sísun ati ẹbọ ohun jíjẹ ojoojumọ.
← Chapter 27
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 32
Chapter 33
Chapter 34
Chapter 35
Chapter 36
Chapter 29 →
All chapters:
1
2
3
4
5
6
7
8
9
10
11
12
13
14
15
16
17
18
19
20
21
22
23
24
25
26
27
28
29
30
31
32
33
34
35
36