bible
ra
🌐 Language
English
Español
Français
Deutsch
Português
Italiano
Nederlands
Русский
中文
日本語
한국어
العربية
Türkçe
Tiếng Việt
ไทย
Indonesia
All Languages
Home
/
Yoruba
/
Yoruba 2010
/
Numbers 34
Numbers 34
Yoruba 2010
← Chapter 33
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 32
Chapter 33
Chapter 34
Chapter 35
Chapter 36
Chapter 35 →
1
OLUWA sọ fún Mose pé,
2
“Pàṣẹ fún àwọn ọmọ Israẹli pé, ‘Nígbà tí ẹ bá dé ilẹ̀ Kenaani tí mo fun yín, gbogbo ilẹ̀ náà ni yóo jẹ́ tiyín. Àwọn ààlà ilẹ̀ yín nìwọ̀nyí.’
3
Ilẹ̀ yín ní ìhà gúsù yóo bẹ̀rẹ̀ láti aṣálẹ̀ Sini lẹ́bàá ààlà Edomu. Ààlà yín ní ìhà gúsù yóo jẹ́ láti òpin Òkun-Iyọ̀ ní ìlà oòrùn.
4
Yóo sì yí láti ìhà gúsù lọ sí gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ òkè Akirabimu, yóo sì la aṣálẹ̀ Sini kọjá lọ títí dé ìhà gúsù Kadeṣi Banea ati títí dé Hasari Adari ati títí dé Asimoni.
5
Yóo sì yí láti Asimoni lọ dé odò Ijipti, òkun ni yóo sì jẹ́ òpin rẹ̀.
6
“Ní ìhà ìwọ̀ oòrùn Òkun ni yóo jẹ́ ààlà yín.
7
“Ní ìhà àríwá, ààlà yín yóo gba ẹ̀gbẹ́ òkun ńlá lọ títí dé Òkè Hori.
8
Láti ibẹ̀ lọ dé ẹnu ibodè Hamati, títí dé Sedadi,
9
Sifironi ati Hasari Enani.
10
“Ààlà ìhà ìlà oòrùn yín yóo gba ẹ̀gbẹ́ Hasari Enani lọ sí Ṣefamu.
11
Yóo lọ sí ìhà gúsù sí Ribila ní ìhà ìlà oòrùn Aini títí lọ sí àwọn òkè tí wọ́n wà létí ìhà ìlà oòrùn Òkun-Kinereti.
12
Láti ibẹ̀ lọ sí ìhà gúsù lẹ́bàá odò Jọdani, yóo parí sí Òkun-Iyọ̀. Àwọn ni yóo jẹ́ ààlà ilẹ̀ yín.”
13
Mose sọ fún àwọn ọmọ Israẹli pé, “Èyí ni ilẹ̀ tí ẹ óo fi gègé pín. Ilẹ̀ tí OLUWA yóo fún àwọn ẹ̀yà mẹsan-an ààbọ̀ yòókù.
14
Àwọn ẹ̀yà Reubẹni ati ẹ̀yà Gadi ati ìdajì ẹ̀yà Manase ti gba ilẹ̀ tiwọn, tí a pín gẹ́gẹ́ bí ilé baba wọn.
15
ní ìhà ìlà oòrùn Jọdani ní òdìkejì Jẹriko. Wọ́n sì ti pín in ní ìdílé-ìdílé.”
16
OLUWA sọ fún Mose pé,
17
“Eleasari alufaa ati Joṣua ọmọ Nuni ni yóo pín ilẹ̀ náà fun yín.
18
Mú olórí kọ̀ọ̀kan ninu ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan láti ràn wọ́n lọ́wọ́.”
19
Àwọn olórí náà nìwọ̀nyí: láti inú ẹ̀yà Juda, a yan Kalebu ọmọ Jefune.
20
Láti inú ẹ̀yà Simeoni, a yan Ṣemueli ọmọ Amihudu.
21
Láti inú ẹ̀yà Bẹnjamini, a yan Elidadi ọmọ Kisiloni.
22
Láti inú ẹ̀yà Dani, a yan Buki ọmọ Jogili.
23
Láti inú ẹ̀yà Manase, a yan Hanieli ọmọ Efodu.
24
Láti inú ẹ̀yà Efuraimu, a yan Kemueli ọmọ Ṣifitani.
25
Láti inú ẹ̀yà Sebuluni, a yan Elisafani ọmọ Parinaki.
26
Láti inú ẹ̀yà Isakari, a yan Palitieli ọmọ Asani.
27
Láti inú ẹ̀yà Aṣeri, a yan Ahihudu ọmọ Ṣelomi.
28
Láti inú ẹ̀yà Nafutali, a yan Pedaheli ọmọ Amihudu.
29
Àwọn ni OLUWA pàṣẹ fún láti pín ilẹ̀ ìní náà fún àwọn ọmọ Israẹli ní ilẹ̀ Kenaani.
← Chapter 33
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 32
Chapter 33
Chapter 34
Chapter 35
Chapter 36
Chapter 35 →
All chapters:
1
2
3
4
5
6
7
8
9
10
11
12
13
14
15
16
17
18
19
20
21
22
23
24
25
26
27
28
29
30
31
32
33
34
35
36