bible
ra
🌐 Language
English
Español
Français
Deutsch
Português
Italiano
Nederlands
Русский
中文
日本語
한국어
العربية
Türkçe
Tiếng Việt
ไทย
Indonesia
All Languages
Home
/
Yoruba
/
Yoruba 2010
/
Numbers 27
Numbers 27
Yoruba 2010
← Chapter 26
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 32
Chapter 33
Chapter 34
Chapter 35
Chapter 36
Chapter 28 →
1
Nígbà náà ni Mahila, Noa, Hogila, Milika ati Tirisa, àwọn ọmọbinrin Selofehadi, ọmọ Heferi, ọmọ Gileadi, ọmọ Makiri, ọmọ Manase, ti ìdílé Manase, ọmọ Josẹfu,
2
lọ fi ẹjọ́ sun Mose ati Eleasari alufaa ati àwọn olórí àwọn ọmọ Israẹli níwájú Àgọ́ Àjọ pé,
3
“Baba wa kú sinu aṣálẹ̀ láìní ọmọkunrin kankan. Kò sí lára àwọn ẹgbẹ́ Kora tí ó ṣọ̀tẹ̀ sí OLÚWA, ṣugbọn ó kú nítorí ẹ̀ṣẹ̀ tirẹ̀ ni.
4
Kí ló dé tí orúkọ baba wa yóo fi parẹ́ kúrò ninu ìdílé rẹ̀ nítorí pé kò ní ọmọkunrin? Nítorí náà, ẹ fún wa ní ilẹ̀ ìní láàrin àwọn eniyan baba wa.”
5
Mose bá bá OLUWA sọ̀rọ̀ nípa wọn,
6
OLUWA sì sọ fún un pé,
7
“Ohun tí àwọn ọmọbinrin Selofehadi bèèrè tọ́, fún wọn ní ilẹ̀ ìní baba wọn láàrin àwọn eniyan baba wọn.
8
Sì sọ fún àwọn ọmọ Israẹli pé nígbà tí ẹnìkan bá kú láìní ọmọkunrin, àwọn ọmọbinrin rẹ̀ yóo jogún ilẹ̀ ìní rẹ̀.
9
Bí kò bá sì ní ọmọbinrin, ilẹ̀ ìní rẹ̀ yóo jẹ́ ti àwọn arakunrin rẹ̀.
10
Bí kò bá ní arakunrin, kí ẹ fi ilẹ̀ ìní rẹ̀ fún àwọn arakunrin baba rẹ̀.
11
Bí baba rẹ̀ kò bá ní arakunrin, ẹ fi ilẹ̀ ìní rẹ̀ fún ìbátan rẹ̀ tí ó bá súnmọ́ ọn jùlọ ninu ìdílé rẹ̀. Ìbátan rẹ̀ yìí ni yóo jogún rẹ̀. Èyí yóo máa jẹ́ ìlànà fún àwọn ọmọ Israẹli gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti pàṣẹ fún Mose.”
12
OLUWA sọ fún Mose pé, “Gun orí òkè Abarimu yìí lọ, kí o sì wo ilẹ̀ tí n óo fún àwọn ọmọ Israẹli.
13
Lẹ́yìn náà tí o bá ti wò ó tán, ìwọ náà yóo kú gẹ́gẹ́ bíi Aaroni arakunrin rẹ,
14
nítorí o ṣàìgbọràn sí àṣẹ mi ninu aṣálẹ̀ Sini. Nígbà tí gbogbo àwọn ọmọ Israẹli ń kùn sí mi ní Meriba, ẹ kọ̀ láti fi títóbi agbára mi hàn níwájú àwọn eniyan náà.” (Meriba ni wọ́n ń pe àwọn omi tí ó wà ní Kadeṣi ní aṣálẹ̀ Sini).
15
Mose bá gbadura báyìí pé,
16
“OLUWA Ọlọrun, ìwọ ni orísun ìyè gbogbo nǹkan alààyè. Èmi bẹ̀ ọ́, yan ẹnìkan tí yóo máa ṣáájú àwọn eniyan wọnyi:
17
ẹni tí ó lè máa ṣáájú wọn lójú ogun, kí àwọn eniyan rẹ má baà wà bí aguntan tí kò ní olùṣọ́.”
18
OLUWA bá sọ fún Mose pé, “Mú Joṣua ọmọ Nuni, ẹni tí Ẹ̀mí èmi OLUWA wà ninu rẹ̀, gbé ọwọ́ rẹ lé e lórí,
19
kí o mú un wá siwaju Eleasari alufaa ati gbogbo àwọn eniyan, kí o sì fún un ní àṣẹ lójú wọn.
20
Fún un ninu iṣẹ́ rẹ, kí àwọn ọmọ Israẹli lè tẹríba fún un.
21
Yóo máa gba ìmọ̀ràn lọ́wọ́ Eleasari alufaa. Eleasari yóo sì máa lo Urimu ati Tumimu láti mọ ohun tí mo fẹ́. Ìtọ́ni Urimu ati Tumimu ni Eleasari yóo fi máa darí Joṣua ninu ohun gbogbo tí àwọn ọmọ Israẹli bá fẹ́ ṣe.”
22
Mose ṣe gbogbo ohun tí OLUWA pa láṣẹ fún un. Ó mú Joṣua wá siwaju Eleasari alufaa ati gbogbo àwọn eniyan,
23
ó gbé ọwọ́ rẹ̀ lé e lórí, ó sì fún un ní àṣẹ.
← Chapter 26
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 32
Chapter 33
Chapter 34
Chapter 35
Chapter 36
Chapter 28 →
All chapters:
1
2
3
4
5
6
7
8
9
10
11
12
13
14
15
16
17
18
19
20
21
22
23
24
25
26
27
28
29
30
31
32
33
34
35
36