bible
ra
🌐 Language
English
Español
Français
Deutsch
Português
Italiano
Nederlands
Русский
中文
日本語
한국어
العربية
Türkçe
Tiếng Việt
ไทย
Indonesia
All Languages
Home
/
Yoruba
/
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
/
Deuteronomy 10
Deuteronomy 10
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
← Chapter 9
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 32
Chapter 33
Chapter 34
Chapter 11 →
1
Nígbà náà ni OLÚWA wí fún mi pé, “Gbé síléètì òkúta méjì bí i ti àkọ́kọ́ kí o sì gòkè tọ̀ mí wá. Kí o sì tún figi kan àpótí kan.
2
Èmi yóò sì tún ọ̀rọ̀ tí ó wà lórí síléètì àkọ́kọ́ tí o fọ́ kọ sórí rẹ̀. Kí o sì fi wọ́n sínú àpótí náà.”
3
Mo sì kan àpótí náà pẹ̀lú igi kaṣíà, mo sì gbẹ́ síléètì òkúta méjì náà jáde bí i ti ìṣáájú. Mo sì gòkè lọ pẹ̀lú síléètì méjèèjì lọ́wọ́ mí.
4
OLÚWA tún ohun tí ó ti kọ tẹ́lẹ̀ kọ sórí síléétì wọ̀nyí. Àwọn òfin mẹ́wẹ̀ẹ̀wá tí ó ti sọ fún un yín lórí òkè, láàrin iná, ní ọjọ́ ìpéjọpọ̀. OLÚWA sì fi wọ́n fún mi.
5
Mo sì sọ̀kalẹ̀ láti orí òkè náà, mo sì ki àwọn síléètì òkúta náà sínú àpótí tí mo ti kàn, bí OLÚWA ti pàṣẹ fún mi, wọ́n sì wà níbẹ̀ di ìsinsin yìí.
6
(Àwọn ará Ísírẹ́lì sì gbéra láti kàǹga àwọn ará a Jákánì dé Mósérà. Níbí ni Árónì kú sí, tí a sì sin ín, Élíásárì ọmọ rẹ̀ sì rọ́pò rẹ̀ bí i àlùfáà.
7
Láti ibẹ̀ ni wọ́n ti rìn lọ sí Gúdígódà, títí dé Jótíbárà, ilẹ̀ tí o kún fún odò tí ó ń sàn.
8
Ní ìgbà yí ni OLÚWA yan àwọn ọmọ Léfì láti máa ru àpótí májẹ̀mú OLÚWA, láti máa dúró níwájú OLÚWA láti ṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́, àti láti fi orúkọ OLÚWA súre bí wọ́n ti ń ṣe títí di òní yìí.
9
Ìdí nìyí tí àwọn ẹ̀yà Léfì kò fi ní ìpín tàbí ogún kan láàrin àwọn arákùnrin wọn. OLÚWA ni ogún wọn gẹ́gẹ́ bí OLÚWA Ọlọ́run ti sọ fún un yín.)
10
Mo tún dúró ní orí òkè náà fún ogójì ọ̀sán àti ogójì òru, bí mo ti ṣe ní ìgbà àkọ́kọ́, OLÚWA sì gbọ́ tèmi ní àkókò yìí bákan náà. Kì í ṣe ìfẹ́ rẹ̀ láti run yín.
11
OLÚWA sọ fún mi pé, “Lọ darí àwọn ènìyàn wọ̀nyí ní ọ̀nà wọn, kí wọn báà lè wọ ilẹ̀ náà, kí wọn sì gba ilẹ̀ tí mo ti búra fún àwọn baba wọn láti fún wọn.”
12
Nísinsin yìí ìwọ Ísírẹ́lì, kín ni ohun tí OLÚWA Ọlọ́run rẹ béèrè lọ́wọ́ rẹ? Bí kò ṣe kí ìwọ bẹ̀rù OLÚWA Ọlọ́run rẹ àti láti máa rìn ní gbogbo ọ̀nà rẹ̀, láti fẹ́ràn rẹ̀, láti fi gbogbo ọkàn rẹ sin OLÚWA Ọlọ́run rẹ ọkan àti àyà rẹ,
13
àti láti máa kíyèsí àṣẹ àti ìlànà OLÚWA tí mo ń fún ọ lónìí, fún ire ara à rẹ.
14
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ wí pé OLÚWA Ọlọ́run yín ni ó ni ọ̀run àní àwọn ọ̀run tó ga ju ayé àti ohun gbogbo tí ó wà nínú rẹ̀.
15
Ṣíbẹ̀ OLÚWA sì tún fi ìfẹ́ rẹ̀ hàn fún àwọn baba ńlá a yín, Ó sì fẹ́ wọn Ó sì yan ẹ̀yin ọmọ wọn láti borí gbogbo orílẹ̀ èdè títí di òní.
16
Ẹ kọ ọkàn yín ní ilà, (Ẹ wẹ ọkàn ẹ̀ṣẹ̀ yín mọ́) kí ẹ má sì se jẹ́ olóríkunkun mọ́ láti òní lọ.
17
Torí pé OLÚWA Ọlọ́run yín, ni Ọlọ́run àwọn ọlọ́run àti OLÚWA àwọn olúwa. Ọlọ́run alágbára, tí ó tóbi tí ó sì lẹ́rù, tí kì í ṣe ojú ṣàájú kì í sì í gba àbẹ̀tẹ́lẹ̀.
18
Ó máa ń gbẹjọ́ aláìní baba àti opó rò, Ó fẹ́ràn àlejò, Óun fi aṣọ àti oúnjẹ fún wọn.
19
Ẹ gbọ́dọ̀ fẹ́ràn àwọn àlejò, torí pé ẹ̀yin pẹ̀lú ti jẹ́ àlejò rí ní Éjíbítì.
20
Ẹ bẹ̀rù OLÚWA Ọlọ́run yín, ẹ sì máa sìn ín. Ẹ dì í mú ṣinṣin, kí ẹ sì búra ní orúkọ rẹ̀.
21
Òun ni ìyìn in yín, Òun sì ni Ọlọ́run yín, tí ó ṣe àwọn iṣẹ́ ìyanu ńlá àti ohun ẹ̀rù, tí ẹ fojú ara yín rí.
22
Àádọ́rin (70) péré ni àwọn baba ńlá a yín tí ó sọ̀kalẹ̀ lọ sí Éjíbítì, ṣùgbọ́n OLÚWA Ọlọ́run yín ti mú un yín pọ̀ síi ní iye bí àwọn ìràwọ̀ ojú ọ̀run.
← Chapter 9
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 32
Chapter 33
Chapter 34
Chapter 11 →
All chapters:
1
2
3
4
5
6
7
8
9
10
11
12
13
14
15
16
17
18
19
20
21
22
23
24
25
26
27
28
29
30
31
32
33
34