bible
ra
🌐 Language
English
Español
Français
Deutsch
Português
Italiano
Nederlands
Русский
中文
日本語
한국어
العربية
Türkçe
Tiếng Việt
ไทย
Indonesia
All Languages
Home
/
Yoruba
/
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
/
Deuteronomy 24
Deuteronomy 24
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
← Chapter 23
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 32
Chapter 33
Chapter 34
Chapter 25 →
1
Bí ọkùnrin kan bá fẹ́ obìnrin kan ní ìyàwó tí ó wá padà bà á nínú jẹ́ nítorí ó rí ohun àìtọ́ kan nípa rẹ̀, tí ó sì kọ ìwé ìkọ̀sílẹ̀ si i, fi fún un kí ó sì lọ jáde kúrò ní ilé è rẹ,
2
tí ó bá di ìyàwó ọkùnrin mìíràn lẹ́yìn ìgbà tí ó kúrò nílé rẹ,
3
àti tí ọkọ rẹ̀ kejì kò bá fẹ́ràn rẹ̀ tí ó sì kọ ìwé ẹ̀rí ìkọ̀sílẹ̀ sí i, kí ó fi fún un kí ó sì lé e kúrò nílé e rẹ̀, tàbí tí ọkọ rẹ̀ kejì bá kú,
4
nígbà náà ni ọkọ, tí ó ti kọ̀ ọ́ sílẹ̀, kò gbọdọ̀ fẹ ẹ mọ́ lẹ́yìn tí ó ti di àìmọ́. Nítorí èyí ni ìríra níwájú OLÚWA. Má ṣe mú ẹ̀ṣẹ̀ wá sórí ilẹ̀ tí OLÚWA Ọlọ́run rẹ yóò fi fún ọ bí ogún.
5
Bí ọkùnrin kan bá ṣẹ̀ṣẹ̀ gbéyàwó, o kò gbọdọ̀ ran lọ sí ogun tàbí kí ó ní iṣẹ́ kan láti ṣe. Ó ní láti ní òmìnira fún ọdún kan kí ó dúró sílé kí ó sì mú inú dídùn bá ìyàwó rẹ̀ tí ó fẹ́.
6
Ẹnikẹ́ni kò gbọdọ̀ gba ìyá ọlọ tàbí ọmọ ọlọ ní ògo, nítorí pé ẹ̀mí ènìyàn ni ó gbà ní ògo n nì.
7
Bí a bá mú ọkùnrin kan tí ó jí ọ̀kan nínú arákùnrin rẹ̀ ní Ísírẹ́lì gbé àti tí ó jí ọ̀kan nínú ẹrú tàbí kí ó tàá, ẹni tí ó jí ènìyàn gbé ní láti kú. Ẹní láti wẹ búburú kúrò láàrin yín.
8
Ní ti àrùn ẹ̀tẹ̀ kíyèsára láti máa ṣe gẹ́gẹ́ bí àwọn àlùfáà tí wọ́n jẹ́ ọmọ Léfì ti pàṣẹ fún ọ. O ní láti máa fi ìṣọ́ra tẹ̀lé ohun tí mo ti pa láṣẹ fún wọn.
9
Rántí ohun tí OLÚWA Ọlọ́run rẹ ṣe sí Míríámù lójú ọ̀nà lẹ́yìn ìgbà tí o jáde kúrò ní Éjíbítì.
10
Nígbà tí o bá wín arákùnrin rẹ ní ohunkóhun, má ṣe lọ sí ilé rẹ̀ láti gba ohun tí ó bá mú wá bí ẹ̀rí.
11
Dúró síta gbangba kí o sì jẹ́ kí ọkùnrin tí o wín mú ògò rẹ jáde wá fún ọ.
12
Bí ọkùnrin náà bá jẹ́ talákà má ṣe lọ sùn ti ìwọ ti ògo rẹ.
13
Dá aṣọ ìlékè rẹ padà ní àṣálẹ́ kí ó báà le sùn lórí i rẹ̀. Nígbà náà ni yóò dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ, ó sì má a jásí ìwà òdodo níwájú OLÚWA Ọlọ́run rẹ.
14
Má ṣe ni alágbàṣe kan lára tí ó jẹ́ talákà àti aláìní, bóyá ó jẹ́ arákùnrin Isírẹ́lì tàbí àlejò tí ó ń gbé ní ọ̀kan nínú àwọn ìlú rẹ.
15
San owó iṣẹ́ rẹ̀ ní ọjọ́ kan náà kí ó tó di àṣàálẹ́, nítorí ó jẹ́ talákà, ó sì gbẹ́kẹ̀lé e bí kò ṣe bẹ́ẹ̀ ó lè képe OLÚWA sí ọ, o sì máa gba ìdálẹ́bi ẹ̀ṣẹ̀.
16
Baba kò gbọdọ̀ kú fún àwọn ọmọ wọn tàbí kí àwọn ọmọ kú fún bàbá wọ́n; olúkúlùkù ní láti kú fún ẹ̀ṣẹ̀ òun tìkára rẹ̀.
17
Má ṣe yí ìdájọ́ po fún àlejò tàbí aláìní baba, tàbí gba aṣọ ìlékè opó bí ẹ̀rí.
18
Rántí pé o jẹ́ ẹrú ní Éjíbítì tí OLÚWA Ọlọ́run rẹ sì gbà ọ́ níbẹ̀. Ìdí nìyí tí mo fi pa á láṣẹ fún ọ láti ṣe èyí.
19
Nígbà tí o bá ń kórè oko rẹ tí o sì fojú fo ìtí kan, má ṣe padà lọ mú u. Fi í kalẹ̀ fún àwọn àlejò, aláìní baba àti opó, kí OLÚWA Ọlọ́run rẹ lè bùkún fún gbogbo iṣẹ́ ọwọ́ ọ̀ rẹ.
20
Nígbà tí o bá ń gun igi ólífì lára àwọn igi i rẹ, má ṣe padà lọ sí ẹ̀ka náà ní ìgbà kejì. Fi èyí tí ó kù fún àlejò, aláìní baba àti opó.
21
Nígbà tí o bá kórè èṣo àjàrà nínú ọgbà àjàrà rẹ, má ṣe lọ sí ọgbà náà mọ́. Fi èyí tí ó kù fún àlejò, aláìní baba àti opó.
22
Rántí pé o ti jẹ́ àlejò ní Éjíbítì. Ìdí nìyí tí mo fi pa á láṣẹ fún ọ láti ṣe èyí.
← Chapter 23
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 32
Chapter 33
Chapter 34
Chapter 25 →
All chapters:
1
2
3
4
5
6
7
8
9
10
11
12
13
14
15
16
17
18
19
20
21
22
23
24
25
26
27
28
29
30
31
32
33
34