bible
ra
🌐 Language
English
Español
Français
Deutsch
Português
Italiano
Nederlands
Русский
中文
日本語
한국어
العربية
Türkçe
Tiếng Việt
ไทย
Indonesia
All Languages
Home
/
Yoruba
/
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
/
Deuteronomy 17
Deuteronomy 17
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
← Chapter 16
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 32
Chapter 33
Chapter 34
Chapter 18 →
1
Ẹ má ṣe fi màlúù tàbí àgùntàn tí ó ní àbùkù, tàbí àbàwọ́n rúbọ sí OLÚWA Ọlọ́run yín, nítorí ìríra ni èyí yóò jẹ́ fún un.
2
Bí ọkùnrin tàbí obìnrin kan tó ń gbé láàrin yín ní èyíkéyìí ìlú wọ̀n-ọn-nì, tí OLÚWA fún un yín bá ń ṣe ibi ní ojú OLÚWA Ọlọ́run yín, ní ríré májẹ̀mú rẹ̀ kọjá,
3
èyí tí ó lòdì sí òfin mi, ó ń sin ọlọ́run mìíràn, ó ń foríbalẹ̀ fún wọn: àní sí òòrùn, òṣùpá àti àwọn ìràwọ̀ ojú ọ̀run,
4
tí èyí sì dé etíìgbọ́ ọ yín, kí ẹ wádìí ọ̀rọ̀ náà dájúdájú. Bí ó bá jẹ́ òtítọ́ tí ó sì hàn gbangba pé ó ti ṣe ohun ìríra yìí, ní Ísírẹ́lì.
5
Ẹ mú ọkùnrin tàbí obìnrin tí ó ti ṣe ibi yìí wá sí ẹnu ọ̀nà ibodè ìlú u yín, kí ẹ sọ ọ́ ní òkúta pa.
6
Lẹnu ẹlẹ́rìí méjì tàbí mẹ́ta ni a ó pa ọkùnrin náà tí ó yẹ láti kú, ṣùgbọ́n ẹ má ṣe pànìyàn nípaṣẹ̀ ẹlẹ́rìí kan ṣoṣo.
7
Àwọn ẹlẹ́rìí ni kí ó kọ́kọ́ gbọ́wọ́ lé e láti pa á. Lẹ́yìn èyí ni kí gbogbo ènìyàn dáwọ́jọ láti pa á. Nípa báyìí, ẹ̀yin yóò sì fọ ohun búburú náà mọ́ kúrò ní àárin yín.
8
Bí ẹjọ́ bá wá sí ilé ẹjọ́ ọ yín tí ó nira jù láti dá: yálà ìtàjẹ̀sílẹ̀ ni, ọ̀ràn dídá tàbí ìkanni-lábùkù: Ẹ mú wọn lọ sí ibi tí OLÚWA Ọlọ́run yín yóò yàn.
9
Ẹ lọ sí ọ̀dọ̀ àwọn àlùfáà tí í ṣe Léfì, àní sí ọ̀dọ̀ adájọ́ tí ó wà fún ìgbẹ́jọ́ ní ìgbà náà. Ẹ béèrè lọ́wọ́ wọn, wọn yóò sì ṣe ìdájọ́.
10
Ẹ gbọdọ̀ ṣe gẹ́gẹ́ bí ìpinnu tí wọ́n fún un yín pé kí ẹ ṣe.
11
Ẹ ṣe bí òfin tí wọ́n kọ́ ọ yín, àti ìpinnu tí wọ́n fún un yín. Ẹ má ṣe yípadà sọ́tùn ún tàbí sósì, kúrò nínú ohun tí wọ́n sọ fún un yín.
12
Ọkùnrin náà tí ó bá ṣe àìbọ̀wọ̀ fún adájọ́ tàbí àlùfáà tí ó ń se iṣẹ́ ìránṣẹ́ sí OLÚWA Ọlọ́run yín, níbẹ̀ ni kí ẹ pa á. Nípa báyìí ẹ̀yin yóò sì fọ ohun búburú náà mọ́ kúrò ní àárin yín.
13
Gbogbo ènìyàn ni yóò sì gbọ́, ẹ̀rù yóò sì bà wọ́n, wọn kò sì ní ṣe àìgbọ́ràn mọ́.
14
Nígbà tí ẹ bá dé ilẹ̀ náà tí OLÚWA Ọlọ́run yín yóò fún un yín, tí ẹ sì ti gba ilẹ̀ náà, tí ẹ sì ń gbé inú un rẹ̀, tí ẹ sì wá sọ pé, “Ẹ jẹ́ kí a yan ọba tí yóò jẹ lé wa lórí bí i ti àwọn orílẹ̀ èdè tí ó yí wa ká.”
15
Ẹ ríi dájú pé ọba tí OLÚWA Ọlọ́run yín yàn fún un yín ní ẹ yàn. Ó gbọdọ̀ jẹ́ láàrin àwọn arákùnrin yín. Ẹ má ṣe fi àjòjì jọba lórí i yín: àní ẹni tí kì í ṣe arákùnrin ní Ísírẹ́lì.
16
Ṣíwájú sí i, ọba náà kò gbọdọ̀ kó ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹsin jọ fún ara rẹ̀, tàbí kí ó rán àwọn ènìyàn náà padà sí Éjíbítì láti wá àwọn ẹsin sí i, nítorí pé OLÚWA ti sọ fún un yín pé, “Ẹ kò gbọdọ̀ tún padà lọ ní ọ̀nà náà mọ́.”
17
Kò gbọdọ̀ kó aya jọ, kí ọkàn rẹ̀ má bàá yapa kúrò. Kò gbọdọ̀ kó fàdákà àti wúrà jọ fún ara rẹ̀ lọ́pọ̀lọpọ̀.
18
Nígbà tí ó bá dé orí oyè ilé ọba rẹ̀ kí ó ṣe àdàkọ àwọn òfin wọ̀nyí sí inú ìwé fún ara rẹ̀, láti inú un ti àlùfáà tí wọ́n jẹ́ ọmọ Léfì.
19
Èyí gbọdọ̀ wà pẹ̀lú rẹ̀, ó sì gbọdọ̀ máa kà wọ́n ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀, àti láti máa tẹ̀lé gbogbo ọ̀rọ̀ inú òfin yìí àti àwọn ìlànà an rẹ̀ tọkàntọkàn.
20
Kí ó má baà lérò pé òun sàn ju àwọn arákùnrin rẹ̀ yóòkù lọ, kí ó sì ti ipa bẹ́ẹ̀ yípadà kúrò nínú òfin wọ̀nyí sí ọ̀tún tàbí sósì. Bẹ́ẹ̀ ni òun àti àwọn ọmọ rẹ̀ yóò jọba pẹ́ títí ní Ísírẹ́lì.
← Chapter 16
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 32
Chapter 33
Chapter 34
Chapter 18 →
All chapters:
1
2
3
4
5
6
7
8
9
10
11
12
13
14
15
16
17
18
19
20
21
22
23
24
25
26
27
28
29
30
31
32
33
34