bible
ra
🌐 Language
English
Español
Français
Deutsch
Português
Italiano
Nederlands
Русский
中文
日本語
한국어
العربية
Türkçe
Tiếng Việt
ไทย
Indonesia
All Languages
Home
/
Yoruba
/
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
/
Deuteronomy 14
Deuteronomy 14
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
← Chapter 13
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 32
Chapter 33
Chapter 34
Chapter 15 →
1
Ọmọ OLÚWA Ọlọ́run yín ni ẹ̀yin jẹ́: nítorí náà, ẹ má ṣe ya ara yín ní abẹ. Ẹ má ṣe gé irun iwájú orí i yín nítorí òkú.
2
Nítorí pé ènìyàn mímọ́ ní ẹ jẹ́ fún OLÚWA Ọlọ́run yín, nínú gbogbo ènìyàn tí ó wà lórí ilẹ̀ ayé, Ọlọ́run ti yàn yín láti jẹ́ ìṣúra iyebíye rẹ̀.
3
Ẹ má ṣe jẹ ohun ìríra kankan.
4
Àwọn wọ̀nyí ni ẹranko tí ẹ lè máa jẹ: màlúù, àgùntàn àti ewúrẹ́,
5
àgbọ̀nrín, èsúó, ẹtu, àgóró, ẹfọ̀n, ìgalà àti àgùntàn igbó
6
Ẹ lè jẹ gbogbo ẹranko tí pátakò ẹṣẹ̀ rẹ̀ kì í se méjì tí ó sì tún jẹ àpọ̀jẹ.
7
Ṣíbẹ̀ṣíbẹ̀ nínú gbogbo ẹran tí ń jẹ àpọ̀jẹ tí ó sì tún ya pátakò ẹṣẹ̀ tí ẹ kò gbọdọ̀ jẹ ni: ràkunmí, ehoro, àti ẹranko tí ó dàbí ehoro tí ń gbé inú àpáta. Bí ó tílẹ̀ jẹ́ pé wọ́n jẹ àpọ̀jẹ, ṣùgbọ́n wọn kò la pátakò, ẹṣẹ̀ a kà wọ́n sí àìmọ́ fún un yín.
8
Ẹlẹ́dẹ̀ jẹ́ àìmọ́; bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ya pátakò ẹṣẹ̀, kì í jẹ àpọ̀jẹ, ẹ kò gbọdọ̀ jẹ ẹran rẹ̀, ẹ kò sì gbọdọ̀ fọwọ́ kan òkú rẹ̀.
9
Nínú gbogbo ẹ̀dá alààyè tí ń gbé inú omi, ẹ lè jẹ èyíkéyí tí ó ní lẹbẹ àti ìpẹ́.
10
Ṣùgbọ́n èyíkéyí tí kò bá ní lẹbẹ àti ìpẹ́, ẹ má ṣe jẹ ẹ́, nítorí pé àìmọ́ ni wọ́n jẹ́ fún un yín.
11
Ẹ lè jẹ ẹyẹ tí ó bá mọ́.
12
Ṣùgbọ́n ìwọ̀nyí ní ẹ kò gbọdọ̀ jẹ: idì, igún, àkàlà,
13
onírúurú àṣá àti àṣá alátagbà,
14
onírúurú ẹyẹ ìwò,
15
ògòǹgò, òyo, pẹ́pẹ́yẹdò àti onírúurú àwòdì,
16
onírúurú òwìwí,
17
òwìwí-ọ̀dàn, idì-okùn, ẹyẹ-àkọ̀,
18
òòdẹ̀, onírúurú ẹyẹ odò mìíràn, atọ́ka àti àdán.
19
Àti gbogbo kòkòrò tí ń fò tí wọ́n ń kọ́wọ̀ọ́ rín jẹ́ aláìmọ́ fun un yín, ẹ má ṣe jẹ wọ́n.
20
Ṣùgbọ́n ẹ lè jẹ èyíkéyí ẹ̀dá abìyẹ́ tí ó bá mọ́.
21
Ẹ má ṣe jẹ ohun tí ó ti kú sílẹ̀. Ẹ lè fún àwọn àjèjì tí ń gbé ní èyíkéyí nínú ìlú yín. Òun lè jẹ ẹ́ tàbí kí ẹ tà á fún àwọn àjèjì. Ṣùgbọ́n ènìyàn mímọ́ fún OLÚWA Ọlọ́run yín ni ẹ̀yin jẹ́. Má ṣe ṣe ewúrẹ́ nínú wàrà ìyá rẹ̀.
22
Ẹ rí i dájú pé ẹ̀ ń fi ìdá kan nínú mẹ́wàá nínú irè oko yín lọ́dọọdún pamọ́ sí apákan
23
Ẹ jẹ ìdámẹ́wàá, oúnjẹ yín, wáìnì tuntun, òróró, àti àkọ́bí àwọn màlúù yín àti ewúrẹ́ ẹ yín, níwájú OLÚWA Ọlọ́run yín, ní ibi tí yóò yàn bí ibùgbé orúkọ rẹ̀. Kí ẹ lè kọ́ bí a ṣé ń bọlá fún OLÚWA Ọlọ́run yín nígbà gbogbo.
24
Bí ibẹ̀ bá jìn tí OLÚWA Ọlọ́run rẹ sì ti bùkún fún ọ, tí o kò sì le ru àwọn ìdámẹ́wàá rẹ (nítorí pé ibi tí OLÚWA yóò yàn láti fi orúkọ rẹ̀ sí jìnnà jù).
25
Ẹ pààrọ̀ àwọn ìdámẹ́wàá yín sówó, ẹ mú owó náà lọ sí ibi tí OLÚWA yóò yàn.
26
Fi owó náà ra ohunkóhun tí o bá fẹ́, màlúù, àgùntàn, wáìnì, tàbí ọtí líle, tàbí ohunkóhun tí o bá fẹ́. Kí ìwọ àti ìdílé rẹ sì jẹ ẹ́ níwájú OLÚWA níbẹ̀ kí ẹ sì máa yọ̀.
27
Ẹ má ṣe gbàgbé àwọn Léfì tí ó ń gbé nì ilú yín, nítorí pé wọn kò ní ìpín kan tàbí ogún kan tí í se tiwọn.
28
Ní òpin ọdún mẹ́tamẹ́ta, ẹ mú gbogbo ìdámẹ́wàá irè oko àwọn ọdún náà, kí ẹ kó wọn jọ ní ìlú yín.
29
Kí àwọn Léfì (tí kò ní ìpín tàbí ogún ti wọn) àti àwọn àlejò, àwọn aláìní baba, àti àwọn opó tí ń gbé ìlú yín lè wá, kí wọn sì jẹ kí wọn sì yó, kí OLÚWA Ọlọ́run rẹ leè bùkún fún ọ, nínú gbogbo iṣẹ́ ọwọ́ rẹ.
← Chapter 13
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 32
Chapter 33
Chapter 34
Chapter 15 →
All chapters:
1
2
3
4
5
6
7
8
9
10
11
12
13
14
15
16
17
18
19
20
21
22
23
24
25
26
27
28
29
30
31
32
33
34