bible
ra
🌐 Language
English
Español
Français
Deutsch
Português
Italiano
Nederlands
Русский
中文
日本語
한국어
العربية
Türkçe
Tiếng Việt
ไทย
Indonesia
All Languages
Home
/
Yoruba
/
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
/
Ecclesiastes 1
Ecclesiastes 1
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 2 →
1
Ọ̀rọ̀ Oníwàásù, ọmọ Dáfídì, ọba Jérúsálẹ́mù:
2
“Aṣán! Aṣán!” ni oníwàásù wí pé “Aṣán pátapáta! Gbogbo rẹ̀ aṣán ni”
3
Kí ni ènìyàn rí jẹ ní èrè lórí gbogbo iṣẹ́ rẹ̀ lórí èyí tí ó ń ṣe wàhálà sí lábẹ́ oòrùn?
4
Bí ìran kan ti wá ni ìran mìíràn ń kọjá lọ, síbẹ̀ ayé dúró títí láé.
5
Oòrùn ń ràn, oòrùn sì ń wọ̀, ó sì sáré padà síbi tí ó tí yọ.
6
Afẹ́fẹ́ ń fẹ́ lọ sí ihá gúṣù, Ó sì ń fẹ́ yípo sí ìhà àríwá, a sì tún padà sí ọ̀nà rẹ̀.
7
Gbogbo odò ń sàn sí inú òkun síbẹ̀síbẹ̀ òkun kò kún. níbi tí àwọn odò ti wá, níbẹ̀ ni wọ́n tún padà sí
8
Ohun gbogbo ni ó ń mú àárẹ̀ wá, ju èyí tí ẹnu le è ṣọ ojú kò tí ì rí ìrírí tí ó tẹ́ẹ lọ́rùn, bẹ́ẹ̀ ni, etí kò tí ì kún fún gbígbọ́.
9
Ohun tí ó ti wà tẹ́lẹ̀ náà ni yóò sì máa wà, ohun tí a ti ṣe sẹ́yìn òun ni a ó tún máa ṣe padà kò sí ohun tuntun lábẹ́ oòrùn.
10
Ǹjẹ́ ohun kan wà tí ẹnìkan le è ṣọ wí pé, “Wòó! Ohun tuntun ni èyí”? Ó ti wà tẹ́lẹ̀ rí ní ọjọ́ tó ti pẹ́ Ó ti wà ṣáájú tiwa.
11
Kò sí ìrántí ohun ìṣáájú bẹ́ẹ̀ ni ìrantí kì yóò sí fún ohun ìkẹyìn tí ń bọ̀ lọ́dọ̀ àwọn tí ń bọ̀ ní ìgbà ìkẹyìn.
12
Èmi, Oníwàásù ti jẹ ọba lórí Ísírẹ́lì ní Jérúsálẹ́mù rí.
13
Mo fi àsìkò mi sílẹ̀ láti kọ́ àti láti ṣe àwárí pẹ̀lú ọgbọ́n, gbogbo ohun tí ó ń ṣẹlẹ̀ lábẹ́ ọ̀run. Háà ẹrù wúwo tí Ọlọ́run ti gbé lé àwọn ènìyàn:
14
Èmi ti rí ohun gbogbo tí ó ń ṣẹlẹ̀ lábẹ́ oòrùn, gbogbo rẹ̀ kò ní ìtumọ̀ bí ẹní gbìyànjú àti mú afẹ́fẹ́ ni.
15
Ohun tí ó ti wọ́ kò le è ṣe é tọ́ mọ́, ohun tí kò sí kò le è ṣe é kà.
16
Mo rò nínú ara mi, “Wòó, mo ti dàgbà, ọgbọ́n mi sì ti pọ̀ ju ti ẹnikẹ́ni tí ó ti ṣe alákòóṣo Jérúsálẹ́mù síwájú mi lọ, mo ti ní ìrírí púpọ̀ nípa ọgbọ́n àti ìmọ̀.”
17
Nígbà náà ni mo fi ara jìn láti ní ìmọ̀ nípa ọgbọ́n, àti pàápàá àìgbọ́n àti àgọ̀, ṣùgbọ́n mo rí, wí pé èyí pẹ̀lú bí ẹni ń gbìyànjú àti mú afẹ́fẹ́ ni.
18
Nítorí pé ọgbọ́n púpọ̀ ìbànújẹ́ púpọ̀ ní ń mú wá, bí ìmọ̀ bá sì ṣe pọ̀ tó náà ni ìbànújẹ́ ń pọ̀ tó.
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 2 →
All chapters:
1
2
3
4
5
6
7
8
9
10
11
12