bible
ra
🌐 Language
English
Español
Français
Deutsch
Português
Italiano
Nederlands
Русский
中文
日本語
한국어
العربية
Türkçe
Tiếng Việt
ไทย
Indonesia
All Languages
Home
/
Yoruba
/
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
/
Ecclesiastes 5
Ecclesiastes 5
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
← Chapter 4
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 6 →
1
Ṣọ́ ìrìn rẹ nígbà tí o bá lọ sí ilé Ọlọ́run. Kí ìwọ kí ó sì múra láti gbọ́ ju àti se ìrúbọ aṣiwèrè, tí kò mọ̀ wí pé òun ń ṣe búburú.
2
Má ṣe yára pẹ̀lú ẹnu un rẹ má sọ ohunkóhun níwájú Ọlọ́run Ọlọ́run ń bẹ ní ọ̀run Ìwọ sì wà ní ayé, nítorí náà jẹ́ kí ọ̀rọ̀ rẹ mọ ní ìwọ̀n
3
Gẹ́gẹ́ bí àlá tí ń wá, nígbà tí ìtọ́jú púpọ̀ wà bẹ́ẹ̀ ni ọ̀rọ̀ òmùgọ̀ nígbà tí ọ̀rọ̀ bá pọ̀jù.
4
Nígbà tí ó bá ṣe ìlérí sí Ọlọ́run, má ṣe pé ní mímú ṣẹ kò ní inú dídùn sí òmùgọ̀, mú ìlérí rẹ sẹ.
5
Ó sàn láti má jẹ́ ẹ̀jẹ́, ju wí pé kí a jẹ́ ẹ̀jẹ́ kí a má mu ṣẹ lọ.
6
Má ṣe jẹ́ kí ẹnu rẹ tì ọ́ sínú ẹ̀ṣẹ̀. Má sì ṣe sọ fún òjíṣẹ́ ilé-ìsìn pé “Àṣìṣe ni ẹ̀jẹ́ mi.” Kí ló dé tí Ọlọ́run fi le è bínú sí ọ kí ó sì ba iṣẹ́ ọwọ́ rẹ jẹ́?
7
Aṣán ni ọ̀pọ̀ àlá àti ọ̀rọ̀ púpọ̀. Nítorí náà dúró nínú ìbẹ̀rù Ọlọ́run.
8
Bí o bá rí talákà tí wọ́n ń ni lára ní ojú títì, tí a sì ń fi òtítọ́ àti ẹ̀tọ́ rẹ̀ dùú, má ṣe jẹ́ kí ó yà ọ́ lẹ́nu láti rí irú nǹkan bẹ́ẹ̀, nítorí pé ẹni tí ó wà ní ipò gíga máa ń mọ́ òṣìṣẹ́ tí ó wà lá bẹ́ rẹ̀ lójú ni, ṣìbẹ́ àwọn kan sì wà tí wọ́n jẹ́ olórí àwọn méjèèjì.
9
Gbogbo wọn ni ó ń pín èrè tí wọ́n bá rí lórí ilẹ̀, àní ọba pàápàá ń jẹ èrè lórí oko.
10
Ẹni tí ó bá ní ìfẹ́ owó kì í ní owó ànító, ẹni tí ó bá ní ìfẹ́ sí ọrọ̀ kì í ní ìtẹ́lọ́rùn pẹ̀lú èrè tí ó ń wọlé fún-un.
11
Bí ẹrù bá ti ń pọ̀ síi náà ni àwọn tí ó ń jẹ ẹ́ yóò máa pọ̀ síi Èrè e kí ni wọ́n sì jẹ́ sí oní nǹkan bí kò se pé, kí ó máa mú inú ara rẹ dùn nípa rírí wọn?
12
Oorun alágbàṣe a máa dùn, yálà ó jẹun kékeré ni tàbí ó jẹun púpọ̀, ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀ ọ̀rọ̀ ọlọ́rọ̀ kì í jẹ́ kí ó ṣùn rárá.
13
Mo ti rí ohun tí ó burú gidigidi lábẹ́ oòrùn ọrọ̀ tí a kó pamọ́ fún ìparun oní nǹkan.
14
Tàbí ọrọ̀ tí ó ṣọnù nípa àìrí ojúrere, nítorí wí pé bí ó bá ní ọmọkùnrin kò sí ohun tí yóò fi sílẹ̀ fún-un.
15
Ìhòòhò ni ènìyàn wá láti inú ìyá rẹ̀, bí ó sì ṣe wá, bẹ́ẹ̀ ni yóò kúrò kò sí ohunkóhun nínú iṣẹ́ rẹ̀ tí ó le mú ní ọwọ́ rẹ̀.
16
Ohun búburú gbáà ni eléyìí pàápàá: Bí ènìyàn ṣe wá, ni yóò lọ kí wá ni èrè tí ó jẹ nígbà tí ó ṣe wàhálà fún afẹ́fẹ́?
17
Ó ń jẹ nínú òkùnkùn ní gbogbo ọjọ́ọ rẹ̀, pẹ̀lú iyè ríra tí ó ga, ìnira àti ìbínú.
18
Nígbà náà ni mo wá rí i dájú pé, ó dára, ó sì tọ̀ nà fún ènìyàn láti jẹ, kí ó mu, kí ó sì ní ìtẹ́lọ́rùn nínú iṣẹ́ wàhálà rẹ̀ lábẹ́ oòrùn, ní àkókò ọjọ́ ayé díẹ̀ tí Ọlọ́run ti fi fún-un, nítorí ìpín rẹ̀ ni èyí.
19
Síwájú sí, nígbà tí Ọlọ́run fún ẹnikẹ́ni ní ọrọ̀ àti ohun ìní, tí ó sì fún-un lágbára láti gbádùn wọn, láti gba ìpín rẹ̀ kí inú rẹ̀ sì dùn sí iṣẹ́ rẹ̀—ẹ̀bùn Ọlọ́run ni èyí.
20
Ó máa ń ronú lẹ́ẹ̀kọ̀ọ́kan nípa ọjọ́ ayé rẹ lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan nítorí pé Ọlọ́run ń pa á mọ́ pẹ̀lú inú dídùn ní ọkàn rẹ̀.
← Chapter 4
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 6 →
All chapters:
1
2
3
4
5
6
7
8
9
10
11
12