bible
ra
🌐 Language
English
Español
Français
Deutsch
Português
Italiano
Nederlands
Русский
中文
日本語
한국어
العربية
Türkçe
Tiếng Việt
ไทย
Indonesia
All Languages
Home
/
Yoruba
/
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
/
Ecclesiastes 4
Ecclesiastes 4
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
← Chapter 3
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 5 →
1
Mo sì tún wò ó, mo sì ri gbogbo ìnilára tí ó ń ṣẹlẹ̀ lábẹ́ oòrùn: mo rí ẹkún àwọn tí ara ń ni, wọn kò sì ní Olùtùnú kankan, agbára wà ní ìkápá àwọn tí ó ń ni wọ́n lára wọn kò sì ní olùtùnú kankan.
2
Mo jowú àwọn tí wọ́n ti kú tí wọ́n sì ti lọ, ó ṣàn fún wọn ju àwọn tí wọ́n sì wà láàyè lọ.
3
Nítòótọ́, ẹni tí kò tí ì sí sàn ju àwọn méjèèjì lọ: ẹni tí kò tí ì rí iṣẹ́ búburú tí ó ń lọ ní abẹ́ oòrun.
4
Mo sì tún mọ̀ pẹ̀lú, ìdí tí ènìyàn fi ń ṣiṣẹ́ tagbáratagbára láti ṣe àṣeyọrí, nítorí pé wọn ń jowú àwọn aládùgbò wọn ni. Ṣùgbọ́n, aṣán ni, ó dàbí ẹni ń gbìyànjú àti mú afẹ́fẹ́.
5
Aṣiwèrè ká ọwọ́ rẹ̀ kò ó sì ba tara rẹ̀ jẹ́.
6
Oúnjẹ ẹ̀kúnwọ́ kan pẹ̀lú ìdákẹ́jẹ́jẹ́ pèlú wàhálà, àti gbígba ìyànjú àti lé afẹ́fẹ́ lọ.
7
Lẹ́ẹ̀kan síi mo tún rí ohun asán kan lábẹ́ oòrùn:
8
Ọkùnrin kan dá wà, kò ní ọmọkùnrin kankan tàbí ẹbí wàhálà rẹ̀ kò lópin, ṣíbẹ̀, ọ̀rọ̀ ohun ìní rẹ̀ kò tẹ́ ẹ lọ́rùn, ó bèèrè pé, “Nítorí ta ni mo ṣe ń ṣe wàhálà” “àti wí pé kí ni ìdí tí mo fi ń fi ìgbádùn du ara mi?” Eléyìí náà aṣán ni iṣẹ́ ìbànújẹ́ ni.
9
Ẹni méjì ṣàn ju ẹnìkan, nítorí wọ́n ní ààbò rere fún iṣẹ́ wọn:
10
Tí ọ̀kan bá ṣubú lulẹ̀, ọ̀rẹ́ rẹ̀ le è ràn án lọ́wọ́ kí ó fàá sókè, ṣùgbọ́n ìyọnu ni fún ọkùnrin náà tí ó ṣubú tí kò sì ní ẹni tí ó le è ràn-án lọ́wọ́!
11
Àti pẹ̀lú pé, bí ẹni méjì bá ṣùn pọ̀, wọn yóò móoru. Ṣùgbọ́n báwo ni ẹnìkan ṣe le è dá nìkan móoru?
12
Bí ó ti lẹ̀ jẹ́ pé, a le è kojú ogun ẹnìkan, àwọn méjì le è gbìjà ara wọn, ìkọ́ okùn mẹ́ta kì í dùn-ún yàra fà já
13
Òtòsì ìpẹ́ẹ̀rẹ̀ tí ó ṣe ọlọ́gbọ́n, ó ṣàn ju arúgbó àti aṣiwèrè ọba lọ tí kò mọ bí yóò ti ṣe gba ìmọ̀ràn,
14
Nítorí pé láti inú túbú ni ó ti jáde ìjọba, bí a tilẹ̀ bí i ní talákà ní ìjọba rẹ̀.
15
Mo rí gbogbo alààyè tí ń rìn lábẹ́ oòrùn, pẹ̀lú ìpẹ́ẹ̀rẹ̀ kejì tí yóò gba ipò ọba yìí.
16
Gbogbo àwọn tí ó wà ní wájú wọn kò sì lópin, ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ àwọn ènìyàn ní ó jọba lé lórí, ẹni tí ó wà ní ipò yìí kò dùn mọ́ àwọn tí ó tẹ̀lé wọn nínú. Aṣán ni eléyìí pẹ̀lú jẹ́, ó dàbí ẹni ń gbìyànjú àti mú afẹ́fẹ́ ni.
← Chapter 3
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 5 →
All chapters:
1
2
3
4
5
6
7
8
9
10
11
12