bible
ra
🌐 Language
English
Español
Français
Deutsch
Português
Italiano
Nederlands
Русский
中文
日本語
한국어
العربية
Türkçe
Tiếng Việt
ไทย
Indonesia
All Languages
Home
/
Yoruba
/
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
/
Ecclesiastes 6
Ecclesiastes 6
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
← Chapter 5
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 7 →
1
Mo ti rí ibi mìíràn lábẹ́ oòrùn.
2
Ọlọ́run fún ọkùnrin kan ní ọrọ̀, ohun ìní àti ọlà kí ó má ba à ṣe aláìní ohun kóhun tí ọkàn rẹ̀ ń fẹ́ ṣùgbọ́n, Ọlọ́run kò fún un ní àǹfàní láti gbádùn wọn, dípò èyí, àlejò ni ó ń gbádùn wọn. Aṣán ni èyí, àrùn búburú gbáà ni.
3
Ọkùnrin kan le è ní ọgọ́rún ọmọ kí ó sì wà láàyè ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún, ṣíbẹ̀ kò sí bí ó ti le wà láàyè pẹ́ tó, bí kò bá le è gbádùn ohun-ìní rẹ̀ kí ó sì gba ìsìnkú tí ó tọ́, mo ṣọ wí pé àbíkú ọmọ ṣàn jù ú lọ.
4
Ó wà láìní ìtumọ̀, ó lọ nínú òkùnkùn, nínú òkùnkùn sì ni orúkọ rẹ̀ farapamọ́ sí.
5
Bí ó ti jẹ́ wí pé kò rí oòrùn tàbí mọ ohunkóhun, ó ní ọ̀pọ̀ ìṣinmi ju ti okùnrin náà lọ.
6
Kó dà, bí ó wà láàyè fún ẹgbẹ̀rún ọdún méjì yípo ṣùgbọ́n tí ó kùnà láti gbádùn ohun-ìní rẹ̀. Kìí ṣe ibìkan ni gbogbo wọn ń lọ?
7
Gbogbo wàhálà tí ènìyàn ń ṣe nítorí àtijẹ ni ṣíbẹ̀ ikùn rẹ̀ kò yó rí
8
Kí ni àǹfàní tí ọlọgbọ́n ènìyàn ní lórí aṣiwèrè? Kí ni èrè talákà ènìyàn nípa mímọ bí yóò ṣe hùwà níwájú àwọn tó kù?
9
Ohun tí ojú rí sàn ju ìfẹnúwákiri lọ Aṣán ni eléyìí pẹ̀lú ó dàbí ẹni ń gbìyànjú àti mú afẹ́fẹ́.
10
Ohunkóhun tí ó bá ti wà ti ní orúkọ, ohun tí ènìyàn jẹ́ sì ti di mímọ̀; kò sí ènìyàn tí ó le è ja ìjàkadì pẹ̀lú ẹni tí ó lágbára jùú lọ
11
Ọ̀rọ̀ púpọ̀, kì í ní ìtumọ̀ èrè wo ni ènìyàn ń rí nínú rẹ̀?
12
Àbí, ta ni ó mọ ohun tí ó dára fún ènìyàn ní ayé fún ọjọ́ ayé kúkúrú àti aṣán tí ó ń là kọjá gẹ́gẹ́ bí òjìji? Ta ni ó le è sọ fún mi, ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ lábẹ́ oòrùn lẹ́yìn tí ó bá lọ tán? kò sí!
← Chapter 5
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 7 →
All chapters:
1
2
3
4
5
6
7
8
9
10
11
12