bible
ra
🌐 Language
English
Español
Français
Deutsch
Português
Italiano
Nederlands
Русский
中文
日本語
한국어
العربية
Türkçe
Tiếng Việt
ไทย
Indonesia
All Languages
Home
/
Yoruba
/
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
/
Numbers 12
Numbers 12
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
← Chapter 11
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 32
Chapter 33
Chapter 34
Chapter 35
Chapter 36
Chapter 13 →
1
Míríámù àti Árónì sọ̀rọ̀ òdì sí Mósè nítorí pé ó fẹ́ obìnrin ará Etiópíà.
2
Wọ́n sì wí pé, “Nípa Mósè nìkan ni OLÚWA ti sọ̀rọ̀ bí, kò ha ti ipa wa sọ̀rọ̀ bí?” OLÚWA sì gbọ́ èyí.
3
(Mósè sì jẹ́ ọlọ́kàn tútù ènìyàn ju gbogbo ènìyàn tó wà lórí ilẹ̀ ayé lọ).
4
Lẹ́ẹ̀kan náà ni OLÚWA sọ fún Mósè, Árónì àti Míríámù pé, “Ẹ̀yin mẹ́tẹ̀ẹ̀ta, jáde wá sínú àgọ́ ìpàdé.” Àwọn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta sì jáde síta.
5
Nígbà náà ni OLÚWA sọ̀kalẹ̀ nínú ọ̀wọ̀n ìkúùkù, ó sì dúró ní ẹnu ọ̀nà àgọ́, ó ké sí Árónì àti Míríámù. Àwọn méjèèjì sì bọ́ ṣíwájú,
6
Ó wí pé, “Ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ mi: “Bí wòlíì OLÚWA bá wà láàrin yín Èmi OLÚWA a máa fara à mi hàn án ní ojúran, Èmi a máa bá a sọ̀rọ̀ nínú àlá.
7
Ṣùgbọ́n èyí kò rí bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú Mósè ìránṣẹ́ mi: ó jẹ́ olótítọ́ nínú gbogbo ilé mi.
8
Mo sì ń bá a sọ̀rọ̀ ní ojúkojú, ọ̀rọ̀ yékéyéké tí kì í ṣe òwe, ó rí àwòrán OLÚWA Kí ló wá dé tí ẹ̀yin kò se bẹ̀rù láti sọ̀rọ̀ òdì sí Mósè ìránṣẹ́ mi?”
9
Ìbínú OLÚWA sì ru sókè sí wọn OLÚWA sì fi wọ́n sílẹ̀.
10
Nígbà tí ìkúùkù kúrò lórí àgọ́ lójijì ni Míríámù di adẹ́tẹ̀, ó funfun bí i yìnyín. Árónì sì padà wo Míríámù ó sì rí i pé ó ti di adẹ́tẹ̀,
11
Ó sì sọ fún Mósè pé, “Jọ̀wọ́ olúwa mi, má ṣe ka ẹ̀ṣẹ̀, èyí tí a fi ìwà òmùgọ̀ dá sí wa lọ́rùn.
12
Má ṣe jẹ́ kí ó dàbí òkú ọmọ tí a bí, tí ìdajì ara rẹ̀ ti rà dànù.”
13
Torí èyí Mósè sì kígbe sí OLÚWA, “OLÚWA, dákun mú un lára dá!”
14
OLÚWA sì dá Mósè lóhùn, “Bí bàbá rẹ̀ bá tutọ́ sí i lójú, ojú kò wa ní í tì í fún ọjọ́ méje? Dá a dúró sí ẹ̀yìn ibùdó fún ọjọ́ méje, lẹ́yìn èyí ki a tó ó le mú wọlé.”
15
Míríámù sì dúró sí ẹ̀yìn ibùdó fún ọjọ́ méje, àwọn ènìyàn kò sì tẹ̀ ṣíwájú nínú ìrìnàjò wọn títí tí Míríámù fi wọ inú ibùdó padà.
16
Lẹ́yìn èyí, àwọn ènìyàn kúrò ní Hásérótì, wọ́n sì pa ibùdó sí Aginjù Páránì.
← Chapter 11
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 32
Chapter 33
Chapter 34
Chapter 35
Chapter 36
Chapter 13 →
All chapters:
1
2
3
4
5
6
7
8
9
10
11
12
13
14
15
16
17
18
19
20
21
22
23
24
25
26
27
28
29
30
31
32
33
34
35
36