bible
ra
🌐 Language
English
Español
Français
Deutsch
Português
Italiano
Nederlands
Русский
中文
日本語
한국어
العربية
Türkçe
Tiếng Việt
ไทย
Indonesia
All Languages
Home
/
Yoruba
/
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
/
Numbers 21
Numbers 21
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
← Chapter 20
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 32
Chapter 33
Chapter 34
Chapter 35
Chapter 36
Chapter 22 →
1
Nígbà tí ọba Árádì ará Kénánì, tí ń gbé ní Gúúsù gbọ́ wí pé Ísírẹ́lì ń bọ̀ wá ní ojú ọ̀nà Átarímù, ó bá Ísírẹ́lì jà ó sì fi agbára mú díẹ̀ lára wọn.
2
Nígbà náà ni Ísírẹ́lì jẹ́jẹ̀ẹ́ fún OLÚWA pé: “Bí o bá lè fi àwọn ènìyàn yìí lé wa lọ́wọ́, gbogbo ìlú wọn ni a ó pa run.”
3
OLÚWA gbọ́ ẹ̀bẹ̀ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ó sì fi àwọn ará Kénánì lé wọn lọ́wọ́. Wọ́n pa wọ́n run pátapáta; torí náà ni a ṣe ń pe ibẹ̀ ní Hómà.
4
Wọ́n rin ìrìnàjò láti òkè Hórì lọ sí ọ̀nà tó lọ sí Òkun Pupa, láti kọjá yípo Édómù. Ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn bínú ní ojú ọ̀nà;
5
wọ́n sì sọ̀rọ̀ lòdì sí OLÚWA àti Mósè, wọ́n wí pé, “Èéṣe tí ìwọ fi mú wa jáde láti Éjíbítì kí a ba le wá kú sí ihà yìí? Kò sí oúnjẹ! Kò sì sí omi! Àwa sì kóríra oúnjẹ tí kò dára yìí!”
6
Nígbà náà ni OLÚWA rán ejò olóró sí àárin wọn; wọ́n gé àwọn ènìyàn jẹ, ọ̀pọ̀ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sì kú.
7
Àwọn ènìyàn sì wá sí ọ̀dọ̀ Mósè wọn wí pé, “A ti dá ẹ̀ṣẹ̀ nígbà tí a sọ̀rọ̀ òdì sí OLÚWA àti sí ìwọ pẹ̀lú. Gba àdúrà pé kí OLÚWA mú ejò náà kúrò lọ́dọ̀ wa.” Nígbà náà ni Mósè gbàdúrà fún àwọn ènìyàn.
8
OLÚWA sọ fún Mósè pé, “Rọ ejò, a ó sì gbé e kọ́ sókè lórí igi, ẹni tí ejò bá ti gé jẹ lè wò ó yóò sì yè.”
9
Nígbà náà ni Mósè sì rọ ejò onírin ó sì gbé e kọ́ sórí igi, Bí ejò bá sì bu ẹnikẹ́ni jẹ bí ó bá ti wò ó yóò sì yè.
10
Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tẹ̀ṣíwájú wọ́n sì péjọ sí Óbótì.
11
Wọ́n gbéra ní Óbótì wọ́n sì pa ibùdó sí Iye-àbárímù, ní ihà tí ó kọjú sí Móábù ní ìdojúkọ ìlà oòrùn.
12
Láti ibẹ̀ ni wọ́n ti gbéra wọ́n sì pa ibùdó ní àfonífojì Sérédì.
13
Wọ́n gbéra kúrò níbẹ̀ wọ́n sì pa ibùdó sí ẹ̀bá ọ̀nà Ánónì, tí ó wà ní Ìfà-gùn ihà tó kángun sí ibi tí ilẹ̀ àwọn ọmọ Ámórì wa. Ánónì jẹ́ ààlà fún ilẹ̀ Móábù, láàrin Móábù àti Ámórì.
14
Ìdí nì yìí tí ìwé ogun OLÚWA ṣe wí pé: “…Wáhébù ní Súpà, òkun pupa àti ní odò Ánónì
15
àti ní isà odò tí ó darí sí ibùjókòó Árí tí ó sì fara ti ìpìnlẹ̀ Móábù.”
16
Láti ibẹ̀ ni wọ́n ti bẹ̀rẹ̀ rìn dé Béérì, èyí ni kànga tí OLÚWA sọ fún Mósè, “Kó àwọn ènìyàn jọ èmi ó sì fún wọn ní omi.”
17
Nígbà náà ni Ísírẹ́lì kọ orin yìí pé: “Sun jáde, ìwọ kànga! Ẹ máa kọrin nípa rẹ̀,
18
Nípa kanga tí àwọn ọmọ aládé gbẹ́, nítorí àwọn ọlọ́lá ènìyàn ni ó gbẹ́ẹ: tí àwọn ọlọ́lá àwọn ènìyàn sì fi ọ̀pá aládé àti ọ̀pá oyè wọn gbẹ́.” Nígbà náà wọ́n kúrò láti ihà lọ sí Mátanà,
19
láti Mátanà lọ sí Náhálíẹ́lì, láti Náhálíẹ́lì lọ sí Bámótì,
20
àti láti Bámótì lọ sí àfonífojì ní Móábù níbi tí òkè Písígà, tí ó wà ní òkè ilé omi ti kọjú sí ihà.
21
Ísírẹ́lì rán oníṣẹ́ láti sọ fún Síhónì ọba àwọn ará Ámórì wí pé:
22
“Jẹ́ kí a kọjá ní orílẹ̀ èdè rẹ. A kò ní kọjá sí inú oko pápá tàbí ọgbà tàbí mu omi láti inú kànga. A máa gba òpópónà náà ti ọba títí tí a ó fi la ilẹ̀ rẹ kọjá.”
23
Ṣùgbọ́n Síhónì kò ní jẹ́ kí àwọn Ísírẹ́lì kọjá ní ilẹ̀ wọn. Ó pe àwọn ọmọ ogun rẹ̀ jọ wọ́n sì wọ́de ogun lọ sí ihà nítorí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì. Nígbà tí ó dé Jánásì, ó bá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì jà.
24
Àmọ́ Ísírẹ́lì ṣẹ́gun, wọn fi ojú idà pa wọ́n, wọ́n sì gba ilẹ̀ láti ọwọ́ Ánónì lọ dé Jábókù, títí tí ó fi dé ilẹ̀ àwọn ará Ámónì, nítorí pé ààlà wọn jẹ́ olódi.
25
Ísírẹ́lì sì gba gbogbo ìlú Ámórì wọ́n sì ń gbé ibẹ̀ pẹ̀lú Hésíbónì, àti gbogbo ibùgbé ìlú tó yí i ká.
26
Hésíbónì ni ìlú Ṣíhónì ọba àwọn ará Ámórì, ẹni tí ó bá ọba ti tẹ́lẹ̀ jà tí ó sì gba gbogbo ilẹ̀ rẹ̀ ní ọwọ́ rẹ̀ títí dé Ánónì.
27
Ìdí nì yí tí akọrin sọ wí pé: “Wá sí Hésíbónì kí ẹ jẹ́ kí a tún un kọ́; jẹ́ kí ìlú Ṣíhónì padà bọ̀ sípò.
28
“Iná jáde láti Hésíbónì, ọ̀wọ́ iná láti Ṣíhónì. Ó jó Árì àti Móábù run, àti ìlú àwọn olùgbé ibi gíga Ánónì.
29
Ègbé ní fún ọ, ìwọ Móábù! Ẹ ti parun, ẹ̀yin ènìyàn Kémósì! Ó ti fi ọmọ rẹ̀ ọkùnrin sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìṣẹ̀san àti ọmọ rẹ̀ obìnrin gẹ́gẹ bí ìgbékùn fún Ṣíhónì ọba àwọn Ámórì.
30
“Ṣùgbọ́n ati bì wọ́n ṣubú; A ti pa wọ́n run títí dé Díbónì. A sì ti run wọ́n títí dé Nófà, tí ó sì fí dé Médébà.”
31
Nígbà náà ni àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sì ń gbé ní ilẹ̀ Ámórì.
32
Lẹ́yìn ìgbà tí Mósè rán wọn lọ sí Jésírélì, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sì gba àwọn agbégbé tó yí wọn ká wọ́n sì lé àwọn Ámórì tó wà níbẹ̀ jáde.
33
Nígbà náà wọ́n pẹ̀yìn dà wọ́n sì gòkè lọ sí Básánì, Ógì ọba ti Básánì àti gbogbo àwọn ọmọ ogun tí ó wọ́de ogun jáde lati pàdé wọn ní ojú ogun ní Édírélì.
34
OLÚWA sọ fún Mósè pé, “Má ṣe bẹ̀rù rẹ̀, nítorí tí mó tí fi í lé ọ lọ́wọ́, pẹ̀lú àwọn ọmọ ogun rẹ̀ pẹ̀lú ilẹ̀ rẹ̀. Ṣe fún un gẹ́gẹ́ bí o ti ṣe sí Ṣíhónì ọba Ámórì ẹni tí ó ń jọba ní Hésíbónì.”
35
Wọ́n sì pa á, pẹ̀lú àwọn ọmọ rẹ̀ àti gbogbo àwọn ọmọ ogun rẹ̀, wọn kò fi ẹnìkankan sílẹ̀. Wọ́n sì gba ìní ilẹ̀ rẹ̀.
← Chapter 20
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 32
Chapter 33
Chapter 34
Chapter 35
Chapter 36
Chapter 22 →
All chapters:
1
2
3
4
5
6
7
8
9
10
11
12
13
14
15
16
17
18
19
20
21
22
23
24
25
26
27
28
29
30
31
32
33
34
35
36