bible
ra
🌐 Language
English
Español
Français
Deutsch
Português
Italiano
Nederlands
Русский
中文
日本語
한국어
العربية
Türkçe
Tiếng Việt
ไทย
Indonesia
All Languages
Home
/
Yoruba
/
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
/
Numbers 25
Numbers 25
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
← Chapter 24
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 32
Chapter 33
Chapter 34
Chapter 35
Chapter 36
Chapter 26 →
1
Nígbà tí àwọn Ísírẹ́lì dúró ní Ṣítímù, àwọn ènìyàn sì bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe àgbèrè pẹ̀lú àwọn ọmọbìnrin Móábù,
2
tí ó pè wọ́n sí bi ẹbọ òrìṣà wọn. Àwọn ènìyàn náà jẹun wọ́n sì foríbalẹ̀ níwájú òrìṣà wọn.
3
Báyìí ni Ísírẹ́lì ṣe darapọ̀ mọ́ wọn tí wọ́n sì jọ ń sin Báálì ti Péórì. Ìbínú OLÚWA sì ru sí wọn.
4
OLÚWA sọ fún Mósè pé; “Mú gbogbo àwọn olórí àwọn ènìyàn wọ̀nyí, pa wọ́n kí o sì fi wọ́n kọ́ sórí igi ní gbangba nínú oòrùn níwájú OLÚWA, kí ìbínú OLÚWA lè kúrò ní ọ̀dọ̀ Ísírẹ́lì.”
5
Mósè sọ fún àwọn onídàájọ́ Ísírẹ́lì, “Ẹnìkọ̀ọ̀kan yín gbọdọ̀ pa arákùnrin rẹ̀ èyí tí ó darapọ̀ ní fífi orí balẹ̀ fún Báálì ti Peori.”
6
Nítòótọ́ ọ̀kan lára àwọn ọmọkùnrin Ísírẹ́lì sì mú obìnrin Mídíánì wá ṣíwájú ojú Mósè àti gbogbo ìpéjọ ti Ísírẹ́lì wọ́n sì ń sunkún ní àbáwọlé Àgọ́ Ìpàdé.
7
Nígbà tí Fínéhásì, ọmọ Élíásárì, ọmọ Árónì, àlùfáà, rí èyí, ó fi ìpéjọ sílẹ̀, pẹ̀lú ọ̀kọ̀ ní ọwọ́ rẹ̀.
8
Ó sì tẹ̀lé arákùnrin Ísírẹ́lì yìí lọ sínú àgọ́. Ó sì fi ọ̀kọ̀ gún àwọn méjèèjì ní àgúnyọ láti ara ọkùnrin Ísírẹ́lì àti sí ara obìnrin náà. Nígbà náà ni àjàkálẹ̀-àrùn lórí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sì dúró;
9
ṣùgbọ́n gbogbo àwọn tí ó kú nínú àjàkálẹ̀-àrùn náà jẹ́ ẹgbàá méjìlá. (24,000)
10
OLÚWA sì tún sọ fún Mósè pé,
11
“Fínéhásì ọmọ Élíásárì ọmọ Árónì, àlùfáà, ti yí ìbinú mi padà kúrò lọ́dọ̀ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì: nítorí tí ó ní ìtara bí èmi náà ti ní ìtara fún iyì mi láàrin wọn, kí ó lè jẹ́ pé èmi ló pa wọ́n run nínú ìtara mi sí wọn.
12
Nítorí náà sọ fún un pé èmi ṣe májẹ̀mú àlàáfíà mi pẹ̀lú rẹ̀.
13
Òun àti irú ọmọ rẹ̀ yóò ní májẹ̀mú láéláé fún iṣẹ́ àlùfáà, nítorí pé ó ní ìtara fún Ọlọ́run rẹ̀ láti fi yẹ́ Ọlọ́run sí, ó sì ṣe ètùtù fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì.”
14
Orúkọ ọmọ Ísírẹ́lì tí a pa pẹ̀lú obìnrin Mídíánì náà ni Símírì, ọmọ Ṣálù, olórí ilé kan nínú àwọn ọmọ Símónì.
15
Orúkọ ọmọbìnrin Mídíánì náà tí a pa ni Kósíbì ọmọbìnrin Súrù, tí ṣe olóyè àwọn ẹ̀yà kan nínú ìdílé kan ní Mídíanì.
16
OLÚWA sì tún sọ fún Mósè pé,
17
“Ka àwọn ará Mídíánì sí ọ̀ta, kí o sì pa wọ́n,
18
nítorí pé wọ́n ṣe sí yín gẹ́gẹ́ bí ọ̀ta nígbà tí wọ́n tàn yín nípa ìṣẹ̀lẹ̀ Péórì, àti arábìnrin wọn Kósíbì ọmọbìnrin ìjòyè Mídíánì kan, obìnrin tí a pa nígbà tí àjàkálẹ̀-àrùn ṣẹlẹ̀ nítorí Péórì.
← Chapter 24
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 32
Chapter 33
Chapter 34
Chapter 35
Chapter 36
Chapter 26 →
All chapters:
1
2
3
4
5
6
7
8
9
10
11
12
13
14
15
16
17
18
19
20
21
22
23
24
25
26
27
28
29
30
31
32
33
34
35
36