bible
ra
🌐 Language
English
Español
Français
Deutsch
Português
Italiano
Nederlands
Русский
中文
日本語
한국어
العربية
Türkçe
Tiếng Việt
ไทย
Indonesia
All Languages
Home
/
Yoruba
/
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
/
Numbers 24
Numbers 24
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
← Chapter 23
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 32
Chapter 33
Chapter 34
Chapter 35
Chapter 36
Chapter 25 →
1
Nísinsìnyìí nígbà tí Bálámù rí i wí pé ó tẹ́ Ọlọ́run lọ́rùn láti bùkún àwọn Ísírẹ́lì, kò lo ọ̀nà ìṣoṣó gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣe tẹ́lẹ̀, ṣùgbọ́n ó yí ojú rẹ̀ sí apá ihà.
2
Nígbà tí Bálámù wo ìta ó sì rí Ísírẹ́lì tí wọ́n pàgọ́ gẹ́gẹ́ bí ẹ̀yà wọn, Ẹ̀mí Ọlọ́run sì bà sórí rẹ̀
3
ó sì bẹ̀rẹ̀ òwe rẹ̀: “Ó wí pé Bálámù ọmọ Béórì, òwe ẹni tí ojú rẹ̀ mọ́lẹ̀,
4
Òwe ẹni tí ó gbọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, ẹni tí ó ríran láti ọ̀dọ̀ Olódùmarè, ẹni tí ó dojúbolẹ̀, tí ojú rẹ̀ sì là:
5
“Àgọ́ rẹ ti dára tó, ìwọ Jákọ́bù, àti ibùgbé rẹ, ìwọ Ísírẹ́lì!
6
“Gẹ́gẹ́ bí àfonífojì tí ó tàn jáde, gẹ́gẹ́ bí ọgbà tí ó wà ní ẹ̀bá odò ńlá, gẹ́gẹ́ bí igi aloe tí OLÚWA gbìn, gẹ́gẹ́ bí igi òpépé tí ó wà lẹ́bá odò.
7
Omi yóò sàn láti inú garawa: èso wọn yóò ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ omi. “Ọba wọn yóò ga ju Ágágì lọ; ìjọba wọn yóò di gbígbéga.
8
“Ọlọ́run mú wọn jáde láti Éjíbítì wá; wọ́n ní agbára gẹ́gẹ́ bí i ti kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́. Wọ́n jẹ orílẹ̀ èdè run, wọ́n fọ́ egungun wọn sí wẹ́wẹ́; wọ́n fi idà wọn gún wọn.
9
Ó tẹríba ó sì dùbúlẹ̀ bí kìnnìún, bí abo kìnnìún: ta ni ó gbọdọ̀ jí wọn? “Ìbùkún ni fún ẹni tí ó bùkún fún ọ, kí ìfibú jẹ́ ti ẹni tí ó fi ọ́ bú!”
10
Nígbà náà ni ìbínú Bálákì sì dé sí Bálámù. Ó sì fi ọwọ́ lu ọwọ́ ó wí pé, “Mo pè ọ́ láti bú àwọn ọ̀ta mi ṣùgbọ́n o tún bùkún fún wọn nígbà mẹ́ta yìí.
11
Nísinsìnyìí kúrò lọ́dọ̀ mi kíákíá kí o sì máa relé! Mo sọ wí pé màá sọ ọ́ di ẹni ńlá, ṣùgbọ́n OLÚWA kò jẹ́ kí o gba èrè yìí.”
12
Bálámù dá Bálákì lóhùn, “Ǹjẹ́ èmi kò sọ fún àwọn ìránṣẹ́ tí o rán sí mi wí pé,
13
‘Kó dà bí Bálákì bá fún mi ní ààfin rẹ̀ tí ó kún fún fàdákà àti wúrà, n kò le ṣe ohunkóhun lọ́wọ́ ara mi, yálà búburú tàbí rere, láti kọjá òfin OLÚWA: ohun tí OLÚWA bá wí ni èmi ó sọ’?
14
Nísinsin yìí mò ń padà lọ sí ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn mi, ṣùgbọ́n jẹ́ kí èmi kí ó kìlọ̀ fún ọ nítorí nǹkan tí àwọn ènìyàn wọ̀nyí yóò ṣe sí àwọn ènìyàn rẹ ní ọjọ́ iwájú.”
15
Nígbà náà ni ó bẹ̀rẹ̀ òwe: “Òwe Bálámù ọmọ Béórì, òwe ẹnì tí ojú rẹ̀ ríran kedere,
16
òwe ẹni kan tí etí rẹ̀ ń gbọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, tí ó ní ọgbọ́n láti ọ̀dọ̀ Ẹni gíga jùlọ, tí ó ríran láti ọ̀dọ̀ Olódùmarè, ẹni tí ó dọ̀bálẹ̀, tí ojú rẹ̀ sì sí:
17
“Mo rí i, ṣùgbọ́n kì í ṣe ìsinsin yìí, Mo kíyèsi, ṣùgbọ́n kò súnmọ́. Ìràwọ̀ kan yóò jáde láti ọ̀dọ̀ Jákọ́bù; yóò yọ jáde láti Ísírẹ́lì. Yóò tẹ̀ fọ́ orí Móábù, yóò sì fọ́ agbárí gbogbo ọmọ Ṣéétì.
18
Wọn yóò borí Édómù; yóò ṣẹ́gun Ṣéérì ọ̀ta rẹ̀, ṣùgbọ́n Ísírẹ́lì yóò dàgbà nínú agbára.
19
Olórí yóò jáde láti Jákọ́bù yóò sì pa àwọn tó ṣẹ́kù nínú ìlú náà run.”
20
Nígbà náà ni Bálámù rí Ámálékì ó sì bẹ̀rẹ̀ òwe: “Ámálékì ni àkọ́kọ́ nínú àwọn orílẹ̀ èdè, ṣùgbọ́n yóò dahoro níkẹyìn.”
21
Nígbà náà ní ó rí ará Kénitì ó sì bẹ̀rẹ̀ òwe: “Ibùgbé rẹ ní ààbò, ìtẹ́ rẹ ni a tò sínú àpáta;
22
ṣíbẹ̀ ẹ̀yin ará Kenítì ni yóò di píparun nígbà tí Áṣúrì bá mú yín ní ìgbékùn.”
23
Nígbà náà ni ó bẹ̀rẹ̀ òwe rẹ̀: “Áì, ta ni ó lè yè nigbà tí Ọlọ́run bá ṣe èyí?
24
Ọkọ̀ yóò wá láti ibùdó kọ̀ Kítímù; wọn yóò ṣẹ́gun Áṣù àti Ébérì, ṣùgbọ́n àwọn náà yóò di píparun.”
25
Nígbà náà ni Bálámù dìde ó sì padà sí ilé rẹ̀, Bálákì sì lọ ní ọ̀nà tirẹ̀.
← Chapter 23
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 32
Chapter 33
Chapter 34
Chapter 35
Chapter 36
Chapter 25 →
All chapters:
1
2
3
4
5
6
7
8
9
10
11
12
13
14
15
16
17
18
19
20
21
22
23
24
25
26
27
28
29
30
31
32
33
34
35
36