bible
ra
🌐 Language
English
Español
Français
Deutsch
Português
Italiano
Nederlands
Русский
中文
日本語
한국어
العربية
Türkçe
Tiếng Việt
ไทย
Indonesia
All Languages
Home
/
Yoruba
/
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
/
Romans 13
Romans 13
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
← Chapter 12
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 14 →
1
Kí olúkúlùkù ọkàn kí ó foríbalẹ̀ fún àwọn aláṣẹ tí ó wà ní ipò gíga. Nítorí kò sí àṣẹ kan, bí kò ṣe láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá; àwọn aláṣẹ tí ó sì wà, láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run li a ti lànà rẹ̀ wá.
2
Nítorí ẹni tí ó bá tàpá sí àṣẹ, ó tàpá sí ìlànà Ọlọ́run; àwọn ẹni tí ó ba sì ń tàpá, yóò gba ẹ̀bi fún ara wọn.
3
Nítorí pé adájọ́ kò wá láti dẹ́rù ba àwọn ẹni tí ń se rere. Ṣùgbọ́n àwọn tó ń ṣe búburú yóò máa bẹ̀rù rẹ̀ nígbà gbogbo. Nítorí ìdí èyí, pa òfin mọ́ ìwọ kò sì ní gbé nínú ìbẹ̀rù.
4
Nítorí ìránṣẹ́ Ọlọ́run ni láti ṣe ọ́ ní rere. Ṣùgbọ́n bí ó bá ṣé nǹkan búburú, máa bẹ̀rù, nítorí kò ru idà náà lásán. Nítorí ìránṣẹ́ Ọlọ́run nííse, ìránṣẹ́ ìbínú sí ara àwọn ẹni tí ń ṣe búburú.
5
Nítorí náà, ó ṣe pàtàkì láti tẹríba fún àwọn alásẹ, kì í ṣe nítorí ìjìyà tó lé wáyé nìkan, ṣùgbọ́n nítorí ẹ̀rí-ọkàn pẹ̀lú.
6
San owó orí rẹ pẹ̀lú nítorí ìdí méjì pàtàkì tí a ti sọ wọ̀nyí. Nítorí pé ó se dandan kí a san owó oṣù fún àwọn òṣìṣẹ́ ìjọba. Èyí yóò mú kí wọn tẹ̀ṣíwájú nínú iṣẹ́ Ọlọ́run náà. Wọn yóò sì máa tọ́jú yín.
7
Ẹ san ohun tí ó tọ́ fún ẹni gbogbo: owó-orí fún ẹni tí owó-orí tọ́ sí: owó-bodè fún ẹni tí owó-bodè tọ́ sí: ẹ̀rù fún ẹni tí ẹ̀rù ń ṣe tirẹ̀; ọlá fún ẹni tí ọlá ń ṣe tirẹ̀
8
Ẹ má ṣe jẹ ẹnikẹ́ní nígbésè, yàtọ̀ fún gbésè ìfẹ́ láti fẹ́ ọmọ ẹnìkejì ẹni, nítorí ẹni tí ó bá fẹ́ ọmọnìkejì rẹ̀, ó kó òfin já.
9
Àwọn òfin, “Ìwọ kò gbọdọ̀ ṣe panságà,” “Ìwọ kò gbọdọ̀ pànìyàn,” “Ìwọ kò gbọdọ̀ jalè,” “Ìwọ kò gbọdọ̀ jẹ́rìí èké,” bí òfin mìíràn bá sì wà, ni a papọ̀ sọ̀kan nínú òfin kan yìí: “Fẹ́ ọmọnìkejì rẹ gẹ́gẹ́ bí ara rẹ̀.”
10
Ìfẹ́ kì í ṣe ohun búburú sí ọmọnìkejì rẹ̀: nítorí náà ìfẹ́ ni àkójá òfin.
11
Àti èyí, bí ẹ ti mọ àkókò pé, ó ti tó wákàtí nísinsìnyí fún yín láti jí lójú orun: nítorí nísinsìn yìí ni ìgbàlà wa súnmọ́ etílé ju ìgbà tí àwa ti gbàgbọ́ lọ.
12
Òru bù kọjá tan, ilẹ̀ sì fẹ́rẹ mọ́: nítorí náà ẹ jẹ́ kí a bọ́ ara iṣẹ́ òkùnkùn sílẹ̀, kí a sì gbé ìhámọ́ra ìmọ́lẹ̀ wọ̀.
13
Jẹ́ kí a má rin ìrìn títọ́, bí ní ọ̀sán; kì í ṣe ní ìréde òru àti ní ìmọ̀tipara, kì í ṣe ni ìwà èérí àti wọ̀bìà, kì íṣe ní ìjà àti ìlara.
14
Ṣùgbọ́n ẹ gbé Jésù Kírísítì Olúwa wọ̀, kí ẹ má sì pèsè fún ara, láti ma mú ìfẹ́kúfẹ rẹ̀ ṣẹ.
← Chapter 12
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 14 →
All chapters:
1
2
3
4
5
6
7
8
9
10
11
12
13
14
15
16
Recommended Reading
Commentary
Romans Commentaries
→
Devotional
Romans Devotional Guide
→
Get This Bible
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní) Study Bible
→