bible
ra
🌐 Language
English
Español
Français
Deutsch
Português
Italiano
Nederlands
Русский
中文
日本語
한국어
العربية
Türkçe
Tiếng Việt
ไทย
Indonesia
All Languages
Home
/
Yoruba
/
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
/
Romans 16
Romans 16
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
← Chapter 15
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
1
Mo fi Fébè arábìnrin wa le yin lọ́wọ́, ẹni tí ó jẹ́ díaókọ́nì nínú ìjọ tí ó wà ní Kéńkíríà.
2
Mo rọ̀ yín kí ẹ gbà á ní orúkọ Olúwa, bí ó ti yẹ fún àwọn ẹ̀nìyàn mímọ́, kí ẹ̀yin kí ó sì ràn án lọ́wọ́ ní gbogbo ọ̀nà, nítorí pé òun jẹ́ olùìrànlọ́wọ́ fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn àti fún èmi náà pẹ̀lú.
3
Ẹ kí Pìrìsílà àti Àkúílà, àwọn tí ó ti jẹ́ alábásiṣẹ́pọ̀ mi nínú Kírísítì Jésù.
4
Àwọn tí wọ́n ti fi ẹ̀mí wọn wéwu nítorí mi. Kì í se èmi nìkan àti gbogbo àwọn ìjọ àwọn aláìkọlà ní ń dúpẹ́ lọ́wọ́ wọn.
5
Kí ẹ sì kí ìjọ tí ń pé jọ fún pọ̀ ní ilé wọn. Ẹ kí Épénétù ọ̀rẹ́ mi ọ̀wọ́n, òun ni ẹni àkọ́kọ́ tí ó di Kírísítẹ́nì ní orílẹ̀ èdè Ésìà.
6
Ẹ kí Màríà, ẹni tí ó ṣe iṣẹ́ takuntakun fún yin.
7
Ẹ kí Áńdíróníkúsì àti Júníásì, àwọn ìbátan mi tí wọ́n wà ní ẹ̀wọ̀n pẹ̀lú mi. Àwọn wọ̀nyí ní ìtayọ láàrin àwọn àpósítélì, wọ́n sì ti wà nínú Kírísítì sáájú mi.
8
Ẹ kí Áńpílíátúsì, ẹni tí ó jẹ́ olùfẹ́ mi nínú Olúwa.
9
Ẹ kí Úbánúsì, alábásisẹ́ pọ̀ wa nínú Kírísítì àti olùfẹ́ mi ọ̀wọ́n Sítákì.
10
Ẹ kí Ápẹ́lẹ́sì, ẹni tí a mọ̀ dájú nínú Kírísítì. Ẹ kí gbogbo àwọn ará nílé Árísítóbúlúsì.
11
Ẹ kí Héródíónì, ìbátan mi. Ẹ kí gbogbo àwọn ará nílé Nákísísù tí wọ́n wá nínú Olúwa.
12
Ẹ kí Tírífẹ́nà àti Tírífósà, àwọn obìrin tí wọ́n se iṣẹ́ takuntakun nínú Olúwa. Ẹ kí Pásísì ọ̀rẹ́ mi ọ̀wọ́n, obìnrin mìíràn tí ó se iṣẹ́ takuntakun nínú Olúwa.
13
Ẹ kí Rúfọ́ọ̀sì, ẹni tí a yàn nínú Olúwa, àti ìyá rẹ̀ àti ẹni tí ó ti jẹ́ ìyá fún èmi náà pẹ̀pú.
14
Ẹ kí Ásínkírítúsì, Fílégónì, Hérímésì, Pátíróbà, Hérímásì àti àwọn arákùnrin tí ó wà pẹ̀lú wọn.
15
Ẹ kí Fílólóhù, àti Júlíà, Néréù, àti arábìnrin rẹ̀, àti Ólíḿpà, àti gbogbo àwọn ènìyàn mímọ́ tí ó wà pẹ̀lú wọn.
16
Ẹ fi ìfẹnukonu mímọ́ kí ara yín. Gbogbo ìjọ kírísitì kí yín.
17
Èmí rọ̀ yín, ara, kí ẹ máa sọ àwọn tí ń fa ìyapa, àti àwọn tí ń mú ohun ìkọ̀sẹ̀ wá sí ọ̀nà yín, èyí tí ó lòdì sí ẹ̀kọ́ tí ẹ̀yin kọ́. Ẹ yà kúrò ní ọ̀dọ̀ wọn.
18
Nítorí irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ kò sin Kírísítì Olúwa wa, bí kò se ikùn ara wọn. Nípa ọ̀rọ̀ geere àti ọ̀rọ̀ dídùndídùn ni wọ́n fi ń yí àwọn aláìmọ̀kan ní ọkàn padà.
19
Nítorí ìgbọ́ràn yín tàn kálẹ̀ dé ibi gbogbo., nítorí náà mo ní ayọ̀ lórí yín; ṣùgbọ́n èmi fẹ́ kí ẹ jẹ́ ọlọgbọ́n sí ohun tí ó ṣe rere, kí ẹ sì ṣe òpè sí ohun tí í ṣe búburú.
20
Ọlọ́run àlàáfíà yóò sì tẹ Sátanì mọ́lẹ̀ ní àtẹ́lẹsẹ̀ yín ní lọ́ọ́lọ́ọ́ yìí. Oore ọ̀fẹ́ Jésù Kírísítì Olúwa wa kí ó wà pẹ̀lú yín.
21
Tìmótíù alábáṣiṣẹ́ mi, àti Lúkíúsì, àti Jásónì, àti Sósípátérù, àwọn ìbátan mi, kí yín.
22
Èmi Térítíù tí ń kọ Èpísítélì yí, kí yín nínú Olúwa.
23
Gáíúsì, ẹni tí èmi àti gbogbo ìjọ gbádùn ìtọ́jú wa tí ó se náà fi ìkíni ránsẹ́. Érásítù, ẹni tí ó jẹ́ alábojútó isẹ́ ìlú, àti arákùnrin wa Kúárítù fi ìkíni wọn ránsẹ́.
24
Ǹjẹ́ kí oore-ọ̀fẹ́ Jésù Kírísítì Olúwa wa, kí ó wà pẹ̀lú gbogbo yín. Àmín.
25
Ǹjẹ́ fún ẹni tí ó ní agbára láti fi ẹṣẹ̀ yín múlẹ̀ nípa ìyìn rere mi àti ìpolongo Jésù Kírísítì, gẹ́gẹ́ bí ìsípayá ohun ìjìnlẹ̀ tí a ti pamọ́ láti ìgbà ayérayé,
26
ṣùgbọ́n, nísinsinyí, a ti fihàn, a sì ti sọ ọ́ di mímọ̀ nípa àkọsílẹ̀ àwọn wòlíì, àti gẹ́gẹ́ bí àṣẹ tí Ọlọ́run ayérayé pa, kí gbogbo orílẹ̀-èdè le ní ìgbàgbọ́, kí wọn sì le se ìgbọ́ràn sí i pẹ̀lú;
27
kí ògo wà fún Ọlọ́run, Ẹnì kan ṣoṣo tí ọgbọ́n í se tirẹ̀ nípa Jésù Kírísítì! Àmín.
← Chapter 15
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
All chapters:
1
2
3
4
5
6
7
8
9
10
11
12
13
14
15
16