bible
ra
🌐 Language
English
Español
Français
Deutsch
Português
Italiano
Nederlands
Русский
中文
日本語
한국어
العربية
Türkçe
Tiếng Việt
ไทย
Indonesia
All Languages
Home
/
Yoruba
/
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
/
Romans 3
Romans 3
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
← Chapter 2
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 4 →
1
Ǹjẹ́ àǹfààní wo ní Júù ní? Tàbí kín ni èrè ilà kíkọ?
2
Púpọ̀ lọ́nà gbogbo; pàtàkì jùlọ ni pé àwọn ni a fi ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lé lọ́wọ́.
3
Ǹjẹ́ kí ha ni bí àwọn kan jẹ́ aláìgbàgbọ́? Àìgbàgbọ́ wọn yóò ha sọ òtítọ́ Ọlọ́run di asán bí?
4
Kí a má rí i: kí Ọlọ́run jẹ́ olóòtọ́, àti olúkúlùkù ènìyàn jẹ́ èké; gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ pé: “Kí a lè dá ọ láre nínú ọ̀rọ̀ rẹ, ṣùgbọ́n kí ìwọ lè borí nígbà tí ìwọ bá wá sí ìdájọ́.”
5
Ṣùgbọ́n bí àìṣòdodo wa bá fi òdodo Ọlọ́run hàn, kín ni àwa ó wí? Ọlọ́run ha jẹ́ àìsòdodo bí? Nígbà tí ó bá ń fi ìbínú rẹ̀ hàn (Mo fi ṣe àkàwé bí ènìyàn).
6
Kí a má rí i: bí bẹ́ẹ̀ bá ni, Ọlọ́run yóò ha ṣe lè dájọ́ aráyé?
7
Nítorí bí òtítọ́ Ọlọ́run bá di púpọ̀ sí ìyìn rẹ̀ nítorí èké mi, èéṣe tí a fi ń dá mi lẹ́jọ́ bí ẹlẹ́sẹ̀?
8
Èéṣe tí a kò fi ṣe búburú kí rere lè jáde wá? Bí àwọn kan tí ń fi ẹnu àtẹ́ sọ wí pé a ń sọ bẹ́ẹ̀; ti àwọn kan sì ń tẹnumọ́ ọn pé a sọ; àwọn ẹni tí ìdálẹ́bí wọn tọ́.
9
Ǹjẹ́ kí ha ni? Àwa ha sàn wọn bí? Kò rí bẹ́ẹ̀ rárá: nítorí a fi hàn ṣáájú pé àti àwọn Júù àti àwọn Gíríkì, gbogbo wọn ni ó wà lábẹ́ ẹ̀ṣẹ̀;
10
Gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ pé: “Kò sí ẹni tí í ṣe olódodo, kò sí ẹnìkan
11
Kò sí ẹni tí òye yé, kò sí ẹni tí ó ń wá Ọlọ́run.
12
Gbogbo wọn ni ó ti yapa, wọ́n jùmọ̀ di aláìlérè; kò sí ẹni tí ń ṣe rere, kò tilẹ̀ sí ẹnìkan.”
13
“Ibojì tí ó ṣí sílẹ̀ ní Ọ̀fun wọn: ahọ́n wọn di aláìlérè; kò sí ẹni ìtànjẹ.” “Oró paramọ́lẹ̀ ń bẹ lábẹ́ ètè wọn.”
14
“Ẹnu ẹni tí ó kún fún èpè àti fún oró kíkorò.”
15
“Ẹsẹ̀ wọn yára láti ta ẹ̀jẹ̀ sílẹ̀:
16
Ìparun àti ìpọ́njú wà lọ́nà wọn.
17
Ọ̀nà àlàáfíà ni wọn kò sì mọ̀:”
18
“Ìbẹ̀rù Ọlọ́run kò sí níwájú wọn.”
19
Àwa sì mọ̀ pé ohunkóhun tí òfin bá wí, ó ń wí fún àwọn tí ó wà lábẹ́ òfin: kí gbogbo ẹnu bá à lè dákẹ́ àti kí a lè mú gbogbo aráyé wá sábẹ́ ìdájọ́ Ọlọ́run.
20
Nítorí pé nípa iṣẹ́ òfin, a kì yóò dá ẹnikẹ́ni láre níwájú rẹ̀: nítorí nípa òfin ni ìmọ̀ ẹ̀ṣẹ̀ ti wá.
21
Ṣùgbọ́n nisinsinyìí, a ti fi òdodo Ọlọ́run hàn láìsí òfin, tí a ti ń jẹ́rí sí nípa òfin àti nípa àwọn wòlíì;
22
Àní òdodo Ọlọ́run nípa ìgbàgbọ́ nínú Jésù Kírísítì, sí gbogbo ènìyàn àti gbogbo àwọn tí ó gbàgbọ́: nítorí tí kò sí ìyàtọ̀:
23
Gbogbo ènìyàn ni ó sá ti ṣẹ̀, tí wọ́n sì kùnà ògo Ọlọ́run:
24
Àwọn ẹni tí a ń dáláre lọ́fẹ̀ẹ́ nípa oore-ọ̀fẹ́ rẹ̀, nípa ìdáǹdè tí ó wà nínú Kírísítì Jésù:
25
Ẹni tí Ọlọ́run ti gbé kalẹ̀ láti jẹ́ ètùtù nípa ìgbàgbọ́ nínú ẹ̀jẹ̀ rẹ̀, láti fi òdodo rẹ̀ hàn nítorí ìdáríjì àwọn ẹ̀ṣẹ̀ tí ó ti kọjá, nínú ìpamọ́ra Ọlọ́run:
26
Láti fi òdodo rẹ̀ hàn ní ìgbà ìsinsìnyìí: kí ó lè jẹ́ olódodo àti olùdáre ẹni tí ó gba Jésù gbọ́.
27
Ọ̀nà ìṣògo dà? A ti mú un kúrò. Nípa òfin wo? Nípa iṣẹ́? Bẹ́ẹ̀ kọ́: Ṣùgbọ́n nípa òfin ìgbàgbọ́.
28
Nítorí náà a parí rẹ̀ sí pé nípa ìgbàgbọ́ ni a ń dá ènìyàn láre láìsí iṣẹ́ òfin.
29
Ọlọ́run àwọn Júù nìkan ha ni bí? Kì í ha ṣe ti àwọn aláìkọlà pẹ̀lú? Bẹ́ẹ̀ ni, ti àwọn aláìkọlà pẹ̀lú:
30
Bí ó ti jẹ́ pé Ọlọ́run kan ni, tí yóò dá àwọn akọlà láre nípa Ìgbàgbọ́ àti àwọn aláìkọlà nítorí ìgbàgbọ́ wọn.
31
Àwa ha ń sọ òfin dasán nípa ìgbàgbọ́ bí? Kí a má rí i: ṣùgbọ́n a ń fi òfin múlẹ̀.
← Chapter 2
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 4 →
All chapters:
1
2
3
4
5
6
7
8
9
10
11
12
13
14
15
16