bible
ra
🌐 Language
English
Español
Français
Deutsch
Português
Italiano
Nederlands
Русский
中文
日本語
한국어
العربية
Türkçe
Tiếng Việt
ไทย
Indonesia
All Languages
Home
/
Yoruba
/
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
/
Romans 4
Romans 4
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
← Chapter 3
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 5 →
1
Ǹjẹ́ kín ni àwa ó ha wí nípa Ábúráhámù, baba wa sàwárí nípa èyí? Májẹ̀mu láéláé jẹ́rìí si i wí pé, a gba Ábúráhámù là nípa ìgbàgbọ́.
2
Nítorí bí a bá dá Ábúráhámù láre nípa iṣẹ́, ó ní ohun ìṣògo; ṣùgbọ́n kì í ṣe níwájú Ọlọ́run.
3
Ìwé mímọ́ ha ti wí? “Ábúráhámù gba Ọlọ́run gbọ́, a sì kà á sí òdodo fún un.”
4
Ǹjẹ́ fún ẹni tí ó ṣiṣẹ́, a kò ka èrè náà sí oore ọ̀fẹ́ bí kò ṣe sí ẹ̀tọ́ rẹ̀.
5
Ṣùgbọ́n fún ẹni tí kò ṣiṣẹ́, tí ó sì ń gba ẹni tí ó ń dá ènìyàn búburú láre gbọ́, a ka ìgbàgbọ́ rẹ̀ sí òdodo.
6
Gẹ́gẹ́ bí Dáfídì pẹ̀lú ti pe olúwa rẹ̀ náà ní ẹni ìbùkún, ẹni tí Ọlọ́run ka òdodo fún láìsí ti iṣẹ́.
7
Wí pé, “Ìbùkún ni fún àwọn ẹni tí a dárí ìrékọjá wọn jì, tí a sì bo ẹ̀ṣẹ̀ wọn mọ́lẹ̀.
8
Ìbùkún ni fún ọkùnrin náà ẹni tí Olúwa kò ka ẹ̀ṣẹ̀ sí lọ́rùn.”
9
Ìbùkún yìí ha jẹ́ ti àwọn akọlà nìkan, tàbí ti àwọn aláìkọlà pẹ̀lú? Nítorí tí a wí pé, a ka ìgbàgbọ́ fún Ábúráhámù sí òdodo.
10
Báwo ni a ṣe kà á sí i? Nígbà tí ó wà ní ìkọlà tàbí ní àìkọlà? Kì í ṣe ni ìkọlà, ṣùgbọ́n ní àìkọlà ni.
11
Ó sì gbé àmì ìkọlà, èdìdì òdodo ìgbàgbọ́ tí ó ní nígbà tí ó wà ní àìkọlà kí ó lè ṣe baba gbogbo àwọn tí ó gbàgbọ́, bí a kò tilẹ̀ kọ wọ́n ní ilà kí a lè ka òdodo sí wọn pẹ̀lú.
12
Àti baba àwọn tí ìkọlà tí kì í ṣe pé a kàn kọlà fún ṣá, ṣùgbọ́n ti wọn ń tẹ̀lé àpẹẹrẹ ìgbàgbọ́ tí baba wa Ábúráhámù ní, kí a tó kọ ọ́ nílà.
13
Ìlérí fún Ábúráhámù àti fún irú ọmọ rẹ̀, pé, wọn ó jogún ayé, kì í ṣe nípa òfin bí kò ṣe nípa òdodo ti ìgbàgbọ́.
14
Nítorí bí àwọn tí ń ṣe ti òfin bá ṣe ajogún, ìgbàgbọ́ di asán, ìlérí sì di aláìlágbára:
15
Nítorí òfin ń ṣiṣẹ́ ìbínú: Ṣùgbọ́n ní ibi tí òfin kò bá sí, ìrúfin kò sí níbẹ̀.
16
Nítorí náà ni ó ṣe gbé e karí ìgbàgbọ́, kí ìlérí náà bá a lè sinmi lé oore-òfẹ́, kí a sì lè mú un dá gbogbo irú ọmọ lójú, kì í ṣe fún àwọn tí ń pa òfin mọ́ nìkan, ṣùgbọ́n bí kò ṣe pẹ̀lú fún àwọn ti ó pín nínú ìgbàgbọ́ Ábúráhámù, ẹni tí í se baba gbogbo wa pátapáta,
17
Gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ pé, “Mo ti fi ọ́ se baba orílẹ̀ èdè púpọ̀.” Níwájú Ọlọ́run ẹni tí òun gbàgbọ́, ẹni tí ó sọ òkú di ààyè, tí ó sì pè àwọn ohun tí kò sí bí ẹni pé wọ́n wà;
18
Nígbà tí ìrètí kò sí mọ́, Ábúráhámù gbàgbọ́ nínú ìrètí bẹ́ẹ̀ ni ó sì di baba orílẹ̀ èdè púpọ̀, gẹ́gẹ́ bí èyi tí a wí fún un pé, “Báyìí ni irú ọmọ rẹ̀ yóò rí.”
19
Ẹni tí kò rẹ̀wẹ̀sì nínú ìgbàgbọ́, nígbà tí ó ro ti ara òun tìkarárẹ̀ tí ó ti kú tan, nítorí tí ó tó bí ẹni ìwọ̀n ọgọ́rún-ún ọdún, àti nígbà tí ó ro ti yíyàgàn inú Sárà:
20
Kò fi àìgbàgbọ́ ṣiyèméjì nípa ìlérí Ọlọ́run; ṣùgbọ́n ó lágbára sí i nínú ìgbàgbọ́ bí ó ti fi ògo fún Ọlọ́run;
21
Pẹ̀lú ìdánilójú kíkún pé, Ọlọ́run lè ṣe ohun tí ó ti ṣe ìlérí rẹ̀.
22
Nítorí náà ni a sì ṣe kà á sí òdodo fún un.
23
Ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ náà, “A kà á sí òdodo fún un,” ni a kọ kì í ṣe kìkì nítorí tirẹ̀ nìkan.
24
Ṣùgbọ́n nítorí tiwa pẹ̀lú. A ó sì kà á sí fún wa, bí àwa bá gba ẹni tí ó gbé Jésù Olúwa wa dìde kúrò nínú òkú gbọ́.
25
Ẹni tí a pa fún ẹ̀ṣẹ̀ wa, tí a sì jí dìde nítorí ìdáláre wa.
← Chapter 3
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 5 →
All chapters:
1
2
3
4
5
6
7
8
9
10
11
12
13
14
15
16