bible
ra
🌐 Language
English
Español
Français
Deutsch
Português
Italiano
Nederlands
Русский
中文
日本語
한국어
العربية
Türkçe
Tiếng Việt
ไทย
Indonesia
All Languages
Home
/
Yoruba
/
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
/
Zechariah 10
Zechariah 10
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
← Chapter 9
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 11 →
1
Ẹ bèèrè òjò nígbà àrọ̀kúrò ni ọwọ́ OLÚWA; OLÚWA tí o dá mọ̀nàmọ́ná, tí ó sì fi ọ̀pọ̀ òjò fún ènìyàn, fún olúkúlúkù koríko ní pápá.
2
Nítorí àwọn òrìṣà tí sọ̀rọ̀ asán, àwọn aláfọ̀ṣẹ sì tí rí èké, wọn sì tí rọ àlá èké; wọ́n ń tu ni nínú láṣán, nítorí náà àwọn ènìyàn náà ṣáko lọ bí àgùntàn, a ṣẹ wọn níṣẹ̀ẹ́, nítorí Olùṣọ́àgùntàn kò sí.
3
“Ìbínú mi ru sí àwọn darandaran, èmi o sì jẹ àwọn olórí níyà nítorí OLÚWA àwọn ọmọ-ogun ti bẹ agbo rẹ̀, ilé Júdà wò, yóò ṣi fi wọn ṣe ẹṣin rẹ̀ dáradára ní ogun.
4
Láti ọ̀dọ̀ rẹ̀ ni òkúta igun ilé ti jáde wá, láti ọ̀dọ̀ rẹ ni igi-èèkàn àgọ́ tí wá, láti ọ̀dọ̀ rẹ ni ọrún ogun tí wá, láti ọ̀dọ̀ rẹ ni àwọn akóniṣiṣẹ́ gbogbo tí wá.
5
Gbogbo wọn yóò sì dàbí ọkùnrin alágbára ni ogun tí ń tẹ àwọn ọ̀tá wọn mọ́lẹ̀ ní ìgboro, wọn ó sì jagun, nítorí OLÚWA wà pẹ̀lú wọn, wọn ó sì dààmú àwọn tí ń gun ẹṣin.”
6
“Èmi o sì mú ilé Júdà ní agbára, èmi o sì gba ilé Jósẹ́fù là, èmi ó sì tún mú wọn padà nítorí mo tí ṣàánú fún wọn, ó sì dàbí ẹni pé èmi kò ì tìí ta wọ́n nù; nítorí èmi ni OLÚWA Ọlọ́run wọn, èmi o sì gbọ́ ti wọn
7
Éfúráímù yóò sì ṣe bí alágbára, ọkàn wọn yóò sì yọ̀ bi ẹni pé nípa ọtí-wáìnì: àní àwọn ọmọ wọn yóò rí í, wọn o sì yọ̀, inú wọn ó sì dùn nínú OLÚWA.
8
Èmi ó kọ sí wọn, èmi ó sì ṣà wọ́n jọ; nítorí èmi tí rà wọ́n padà; wọn ó sì pọ̀ sí i gẹ́gẹ́ bí wọ́n tí ń pọ̀ sí í rí.
9
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé mo tú wọn kákiri orílẹ̀-èdè: ṣíbẹ̀ wọn ó sì rántí mi ni ilẹ̀ jínjìn; wọn ó sì gbé pẹ̀lú àwọn ọmọ wọn, wọn ó sì tún padà.
10
Èmi ó sì tún mú wọn padà kúrò ni ilẹ̀ Éjíbítì pẹ̀lú, èmi ó sì ṣà wọn jọ kúrò ni ilẹ̀ Áṣíríà: èmi ó sì mú wọn wá sí ilẹ̀ Gílíádì àti Lébánónì; a a kì yóò sì rí àyè fún wọn bí ó ti yẹ.
11
Wọn yóò sì la òkun wàhálà já, yóò sì lu rírú omi nínú òkun, gbogbo ibú odò ni yóò sì gbẹ, a ó sì rẹ ìgbéraga Áṣíríà ṣílẹ̀, ọ̀pá aládé Éjíbítì yóò sí lọ kúrò.
12
Èmi ó sì mú wọn ní agbára nínú OLÚWA; wọn ó sì rìn sókè rìn sódò ni orúkọ rẹ̀,” ni OLÚWA wí.
← Chapter 9
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 11 →
All chapters:
1
2
3
4
5
6
7
8
9
10
11
12
13
14