bible
ra
🌐 Language
English
Español
Français
Deutsch
Português
Italiano
Nederlands
Русский
中文
日本語
한국어
العربية
Türkçe
Tiếng Việt
ไทย
Indonesia
All Languages
Home
/
Yoruba
/
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
/
Zechariah 11
Zechariah 11
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
← Chapter 10
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 12 →
1
Ṣí àwọn ìlẹ̀kùn rẹ sílẹ̀, ìwọ Lébánónì, kí iná bá lè jẹ igi Kédárì rẹ run,
2
Pohùnréré-ẹkún, igi fírì; nítorí igi Kédárì ṣubú, nítorí tí a ba àwọn igi tí o lógo jẹ́: ṣunkún kíkorò ẹ̀yin igi óákù tí Básánì, nítorí gé igbó àjàrà lulẹ̀.
3
Gbọ́ ohun igbe àwọn olùṣọ́-àgùntàn; ògo wọn bàjẹ́; gbọ́ ohùn bíbú àwọn ọmọ kìnnìún nítorí ògo Jódánì bàjẹ́.
4
Báyìí ni OLÚWA Ọlọ́run mi wí: “Bọ́ ọ̀wọ́-ẹran àbọ́pa.
5
Tí àwọn olúwa wọn ń pa wọ́n, tí wọn kò sì ka ara wọn sí pé wọn jẹ̀bi: àti àwọn tí ń tà wọ́n wí pé, ‘Ìbùkún ni fún OLÚWA, nítorí tí mo dí ọlọ́rọ̀!’ Àwọn olùṣọ́ àgùntàn wọn kò sì ṣàánú wọn.
6
Nítorí èmi kì yóò ṣàánú fún àwọn ara ilẹ̀ náà mọ́,” ni OLÚWA wí, “Ṣí kíyèsí í, èmi yóò fi olúkúlúkù ènìyàn lé aládùúgbò rẹ̀ lọ́wọ́, àti lé ọwọ́ ọba rẹ̀, wọn yóò sì fọ́ ilẹ̀ náà, èmi kì yóò sì gbà wọ́n lọ́wọ́ wọn.”
7
Èmi yóò sì bọ́ ẹran àbọ́pa, àní ẹ̀yin òtòsì nínú ọ̀wọ́ ẹran. Mo sì mu ọ̀pá méjì ṣọ́dọ̀; mo pè ọ̀kan ni Oore-ọ̀fẹ́, mo pè èkejì ni Àmùrè; mo sì bọ́ ọ̀wọ́-ẹran náa.
8
Olùṣọ àgùntàn mẹ́ta ni mo sì gé kúrò ní oṣù kan; Ọkàn mi sì kòrìíra wọn, ọkàn wọn pẹ̀lú sì kóríra mi.
9
Mo sì wí pé, “Èmi kì yóò bọ́ yin: èyí ti ń ku lọ, jẹ́ kí òkú o kú; èyí tí a o ba sì gé kúrò, jẹ́ kí a gé e kúrò; ki olúkúlùkù nínú àwọn ìyókù jẹ́ ẹran-ara ẹnìkejì rẹ̀.”
10
Mo sì mu ọ̀pá mi, ti a ń pè ní Oore-ọ̀fẹ́, mo ṣẹ́ ẹ méjì, ki èmi bá lè da májẹ̀mu mi tí mo tí bá gbogbo àwọn ènìyàn náà dá.
11
Ó sì dá ni ọjọ́ náà, bẹ́ẹ̀ ni àwọn òtòsì nínú ọ̀wọ́-ẹran náà ti o dúró tì mí mọ̀ pé, ọ̀rọ̀ OLÚWA ni.
12
Mo sì wí fún wọn pé, “Bí ó bá dára ní ojú yin, ẹ fún mi ni owó-ọ̀yà mi; bí bẹ́ẹ̀ kọ́, ẹ mú un lọ́wọ́.” Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n wọn ọgbọ̀n owó fàdákà fún iye owó-ọ̀yà mi.
13
OLÚWA sì wí fún mi pé, “Ṣọ ọ sí àpótí ìsúra!” Iye dáradára náà, tí wọn yọ owó mi sí. Mo sì mu ọgbọ̀n owo fàdákà náà, mo sì sọ wọ́n sí àpótí ìsúra ní ilé OLÚWA.
14
Mo sì ṣẹ́ ọ̀pá mi kejì, àní Àmùrè, sí méjì, kí èmi lè ya ìbátan tí ó wà láàrin Júdà àti láàrin Íṣírẹ́lì.
15
OLÚWA sì wí fún mi pé, “Tún mú ohun-èlò Olùṣọ́-àgùntàn búburú kan ṣọ́dọ̀ rẹ̀.
16
Nítorí Èmi o gbé olùṣọ́-àgùntàn kan dídé ni ilẹ̀ náà, tí kí yóò bẹ àwọn tí ó ṣègbé wò, ti kì yóò sì wá èyí tí ó yapa; tí kì yóò ṣe ìtọ́jú èyí tí a pa lára tàbí kí ó bọ́ àwọn tí ara wọn dá pépé: Ṣùgbọ́n òun yóò jẹ ẹran èyi tí ó ni ọ̀rá, yóò sì fa èékánna wọn ya pẹ́rẹpẹ̀rẹ.
17
“Ègbé ni fún olùṣọ́-àgùntàn aṣán náà, tí ó fi ọ̀wọ́-ẹran sílẹ́! Idà yóò ge apá rẹ̀ àti ojú ọ̀tún rẹ̀: apá rẹ̀ yóò gbẹ pátapáta, ojú ọ̀tún rẹ̀ yóò sì fọ́ pátapáta!”
← Chapter 10
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 12 →
All chapters:
1
2
3
4
5
6
7
8
9
10
11
12
13
14