bible
ra
🌐 Language
English
Español
Français
Deutsch
Português
Italiano
Nederlands
Русский
中文
日本語
한국어
العربية
Türkçe
Tiếng Việt
ไทย
Indonesia
All Languages
Home
/
Yoruba
/
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
/
Zechariah 9
Zechariah 9
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
← Chapter 8
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 10 →
1
Ọ̀rọ̀ OLÚWA kọjú ìjà sí Hádírákì, Dámásíkù ni yóò sì jẹ́ ibi ìṣinmi rẹ̀; nítorí ojú OLÚWA ń bẹ lára ènìyàn, àti lára gbogbo ẹ̀yà Ísírẹ́lì.
2
Àti Hámátì pẹ̀lú yóò ṣe ààlà rẹ̀ Tírè àti Sídónì bí o tilẹ̀ ṣe ọlọgbọ́n gidigidi.
3
Tírè sì mọ odi líle fún ara rẹ̀, ó sì kó fàdákà jọ bí èkuru, àti wúrà dáradára bí àfọ̀ ẹ̀rẹ̀ ìgboro.
4
Ṣùgbọ́n, OLÚWA yóò kó gbogbo ohun ìní rẹ̀ lọ, yóò sì pa agbára rẹ̀ run ní ojú òkun, a ó sì fi iná jó o run.
5
Ásíkélónì yóò rí í, yóò sì bẹ̀rù; Gásà pẹ̀lú yóò rí í, yóò sì káànú gidigidi, àti Ékírónì: nítorí tí ìrètí rẹ̀ yóò sákì í. Gásà yóò pàdánu ọba rẹ̀, Ásíkélónì yóò sì di ahoro.
6
Ọmọ àlè yóò sì gbé inú Ásídódì, Èmi yóò sì ge ìgbéraga àwọn Fílístínì kúrò.
7
Èmi yóò sì mu ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ kúrò ni ẹnu rẹ̀, àti àwọn ohun èèwọ̀ kúrò láàrin eyín rẹ̀: ṣùgbọ́n àwọn tó sẹ́kù yóò jẹ́ tí Ọlọ́run wa, wọn yóò sì jẹ baálẹ̀ ní Júdà, àti Ékírónì ni yóò rí bí Jébúṣì.
8
Èmi yóò sì dó yí ilẹ̀ mi ká nítorí ogun àwọn tí wọ́n ń wá ohun tí wọn yóò bàjẹ́ kiri, kò sí aninilára tí yóò là wọ́n já mọ́: nítorí ni ìṣinṣin yìí ni mo fi ojú ṣọ́ wọn.
9
Ẹ kún fún ayọ̀, ẹ̀yin ọmọbìnrin Ṣíónì Ẹ hó ìhó ayọ̀, ẹ̀yin ọmọbìnrin Jérúsálẹ́mù: Ẹ wo ọba yín ń bọ̀ wá ṣọ́dọ̀ yín: òdodo ni òun, ó sì ní ìgbàlà; ó ní ìrẹ̀lẹ̀, ó sì ń gun kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, àní ọmọ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́.
10
Èmi ó sì gbé kẹ̀kẹ́ kúrò ni Éfúráímù, àti ẹṣin ogun kúrò ni Jérúsálẹ́mù, a ó sì ṣẹ́ ọrun ogun. Òun yóò sì kéde àlàáfíà sí àwọn aláìkọlà. Ìjọba rẹ̀ yóò sì gbilẹ̀ láti òkun dé òkun, àti láti odò títí de òpin ayé.
11
Ní tìrẹ, nítorí ẹ̀jẹ̀ májẹ̀mu mi pẹ̀lú rẹ, Èmi ó dá àwọn ìgbèkùn rẹ̀ sílẹ̀ kúrò nínú ọ̀gbun.
12
Ẹ padà sínú odi agbára yín, ẹ̀yin òǹdè ìrètí: àní lónìí yìí èmi sọ pé, èmi o san án fún ọ ni ìlọ́poméjì.
13
Èmi ó fa Júdà le bí mo ṣe fa ọrun mi le, mo sì fi Éfúráímù kún un, Èmi yóò gbé àwọn ọmọ rẹ ọkùnrin dìde, ìwọ Ṣíónì, sí àwọn ọmọ rẹ̀ ọkùnrin, ìwọ Gíríkì, mo ṣe ọ́ bí idà alágbára.
14
OLÚWA yóò sì fí arahàn ní orí wọn Ọ̀kọ̀ rẹ̀ yóò tàn bí mọ̀nàmọ́ná. OLÚWA ọ̀gá-ògo yóò sì fọn ìpè, Òun yóò sì lọ nínú atẹ́gùn ìjì gúṣù.
15
OLÚWA àwọn ọmọ-ogun yóò dáàbò bò wọ́n; wọn ó sì jẹ ni run, wọn ó sì tẹ òkúta kànnà-kànnà mọ́lẹ̀; wọn ó sì mu ẹ̀jẹ̀ wọn bí wáìnì, wọn ó sì kún bí ọpọ́n, wọn ó sì rin ṣinṣin bí àwọn igun pẹpẹ.
16
OLÚWA Ọlọ́run wọn yóò sì gbà wọ́n là ni ọjọ́ náà bí agbo ènìyàn rẹ̀: nítorí wọn ó dàbí àwọn òkúta adé, tí a gbé sókè bí àmì lórí ilẹ̀ rẹ̀.
17
Nítorí oore rẹ̀ tí tóbi tó, ẹwà rẹ̀ ṣi tí pọ̀! Ọkà yóò mú ọ̀dọ́mọkùnrin dárayá, ati ọtí-wáìnì tuntun yóò mú àwọn ọ̀dọ́mọbìnrin ṣe bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú.
← Chapter 8
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 10 →
All chapters:
1
2
3
4
5
6
7
8
9
10
11
12
13
14