bible
ra
🌐 Language
English
Español
Français
Deutsch
Português
Italiano
Nederlands
Русский
中文
日本語
한국어
العربية
Türkçe
Tiếng Việt
ไทย
Indonesia
All Languages
Home
/
Yoruba
/
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
/
Zechariah 12
Zechariah 12
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
← Chapter 11
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 13 →
1
Ọ̀rọ̀-ìmọ̀ ọ̀rọ̀ OLÚWA fún Íṣírẹ́lì, ni OLÚWA wí, ẹni tí ó na àwọn ọ̀run, tí ó sì fi ìpìlẹ̀ ayé ṣọlẹ̀, tí ó sì da ẹ̀mi ènìyàn tí ń bẹ ni inú rẹ̀:
2
“Kíyèsí í, èmi yóò ṣọ Jérúsálẹ́mù dí àgọ́ ìwárìrì sí gbogbo ènìyàn yíká, nígbà tí wọn yóò dó ti Júdà àti Jérúsálẹ́mù.
3
Ní ọjọ́ náà, nígbà tí gbogbo orilẹ̀-èdè ayé bá parapọ̀ sí i, ni èmi yóò sọ Jérúsálẹ́mù di ẹrù òkúta fún gbogbo ènìyàn: gbogbo àwọn tí ó bá sì fi dẹ́rù pa ara wọn ni a ó ge sí wẹ́wẹ́,
4
ní ọjọ́ náà,” ni OLÚWA wí, “Ni èmi yóò fí ìdágìrì lu gbogbo ẹṣin, àti fi òmùgọ̀ kọlu ẹni tí ń gun un; èmi yóò sì sí ojú mi sí ilé Júdà, èmi yóò sì bu ìfọ́jú lu gbogbo ẹṣin tí orílẹ̀-èdè.
5
Àti àwọn baálẹ̀ Júdà yóò sì wí ni ọkàn wọn pé, ‘Àwọn ara Jérúsálẹ́mù ni agbára mi nípa OLÚWA Ọlọ́run wọn.’
6
“Ní ọjọ́ náà, ni èmi yóò se àwọn baálẹ̀ Júdà bí ààrò iná kan láàrin igi, àti bi ẹfúùfù iná láàrin ìtí; wọn yóò sì jẹ gbogbo àwọn ènìyàn run yíká lápá ọ̀tún àti lápá òsì: a ó sì tún máa gbé inú Jérúsálẹ́mù ní ipò rẹ̀.
7
“OLÚWA pẹ̀lú yóò kọ́ tètè gba àgọ́ Júdà là ná, kí ògo ilé Dáfídì àti ògo àwọn ara Jérúsálẹ́mù má ba gbé ara wọn ga sí Júdà.
8
Ní ọjọ́ náà ni OLÚWA yóò dáàbò bò àwọn tí ń gbé Jérúsálẹ́mù; ẹni tí ó bá sì ṣe àìlera nínú wọn ní ọjọ́ náà, yóò dàbí Dáfídì; ilé Dáfídì yóò sì dàbí Ọlọ́run, bí ańgẹ́lì OLÚWA níwájú wọn.
9
Yóò sì ṣe ni ọjọ́ náà, èmi yóò wá láti pa gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè run tí ó wá kọjú ìjà sí Jérúsálẹ́mù.”
10
“Èmi ó sì tu ẹ̀mí oore-ọ̀fẹ́ àti ẹ̀bẹ̀ ṣórí ilé Dáfídì àti sórí Jérúsálẹ́mù: wọn ó sì máa wo ẹni tí wọn tí gún ni ọ̀kọ̀, wọn ó sì máa sọ̀fọ̀ rẹ̀, bí ẹnìkan ti ń sọ̀fọ̀ fún ọmọ rẹ̀ kan ṣoṣo àti gẹ́gẹ́ bí ènìyàn tí wọn yóò sì wà ni ìbànújẹ́, bí ẹni tí ń banújẹ́ fún àkọ́bí rẹ̀.
11
Ní ọjọ́ náà ni ẹkún, ńláńlá yóò wà ni Jérúsálẹ́mù, gẹ́gẹ́ bí ọ̀fọ̀ Hádádì Rímónì ni àfonífojì Mégídónì.
12
Ilẹ̀ náà yóò ṣọ̀fọ̀, ìdílé, ìdílé, lọ́tọ̀ọ̀tọ̀; ìdílé Dáfídì lọ́tọ̀; àti àwọn aya wọn lọ́tọ̀; ìdílé Nátanì lọ́tọ̀, àti àwọn aya wọn lọ́tọ́.
13
Ìdílé Léfì lọ́tọ̀, àti àwọn aya wọn lọ́tọ̀; ìdílé Ṣimei lọ́tọ̀, àti àwọn aya wọn lọ́tọ̀.
14
Gbogbo àwọn ìdílé tí o kù, ìdílé, ìdílé, lọ́tọ̀ọ̀tọ̀, àti àwọn aya wọn lọ́tọ̀.
← Chapter 11
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 13 →
All chapters:
1
2
3
4
5
6
7
8
9
10
11
12
13
14